Ṣó Dáa Kí Òbí Sọ Tẹlifíṣọ̀n Di Abọ́mọṣeré?
NÍGBÀ míì, ó lè dà bí ohun tó dára gan-an láti fi àwọn ọmọ rẹ kéékèèké sídìí tẹlifíṣọ̀n kí wọ́n máa wò ó nígbà tí ìwọ òbí ń bá iṣẹ́ rẹ lọ. Àmọ́, àkóbá wo lèyí lè ṣe fáwọn ọmọ rẹ?
Ìwé ìròyìn The New York Times sọ pé: “Ohun táwọn ìkókó bá rí lórí tẹlifíṣọ̀n lè nípa lórí wọn.” Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe láìpẹ́ yìí, wọ́n fi fíìmù kan han àwọn ọmọ ọlọ́dún kan fún ìṣẹ́jú mélòó kan lórí tẹlifíṣọ̀n. Nínú fíìmù náà, obìnrin òṣèré kan fi onírúurú ìṣarasíhùwà hàn sí ohun ìṣeré ọmọdé kan. Ìwé ìròyìn náà sọ pé: “Nígbà tí obìnrin òṣèré náà bá ṣe bíi pé ẹ̀rù ba òun bó ṣe rí ohun ìṣeré náà, àwọn ọmọ náà sábà máa ń yẹra fún ohun ìṣeré ọ̀hún, ó sì máa ń mú kí àyà wọn já, tàbí kí wọ́n dijú mọ́rí, tàbí kí wọ́n figbe ta. Àmọ́ nígbà tí obìnrin òṣèré náà bá fi hàn pé inú òun dùn bó ṣe rí ohun ìṣeré náà, àwọn ọmọ náà fẹ́ láti máa fi í ṣeré.”
Láìsí àní-àní, tẹlifíṣọ̀n lè ṣàkóbá fáwọn ọmọ ọwọ́. Ohun tó lè sọ àwọn ọmọdé dà ńkọ́? Dókítà Naoki Kataoka tó jẹ́ onímọ̀ nípa ìtọ́jú àìsàn àwọn ọmọdé ní Yunifásítì Ìṣègùn ti Kawasaki nílùú Kurashiki, lórílẹ̀-èdè Japan, ṣàkíyèsí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọdé tó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n kàn máa ń dákẹ́ ṣáá, tí wọn kì í rẹ́rìn ín. Ohun tó fà á ni pé wọ́n ti wo tẹlifíṣọ̀n tàbí fídíò láwòjù. Fídíò wíwò tiẹ̀ ṣàkóbá fún ọmọkùnrin ọmọ ọdún méjì kan débi pé kò mọ bí wọ́n ṣe ń béèyàn sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ tó sì mọ̀ ò tó nǹkan. Látìgbà tó ti wà lọ́mọ ọdún kan ló ti ń fojoojúmọ́ wo fídíò látàárọ̀ ṣúlẹ̀. Dókítà kan wá gba ìyá rẹ̀ nímọ̀ràn pé kó má ṣe jẹ́ kọ́mọ náà máa wo fídíò mọ́, pé ńṣe ni kó máa bá a ṣeré. Ìyá rẹ̀ tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ dókítà yìí, látìgbà náà wá sì lọmọ náà ti ń mọ ọ̀rọ̀ọ́ sọ dáadáa. Bẹ́ẹ̀ ni, ó yẹ káwọn òbí máa ní ìfararora pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn.
Jèhófà Ọlọ́run tí í ṣe Olùdásílẹ̀ ètò ìdílé tẹnu mọ́ ọ̀nà tó dára jù lọ táwọn òbí lè gbà ní ìfararora pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn ló ti sọ fáwọn èèyàn rẹ̀ pé: “Kí ìwọ sì fi ìtẹnumọ́ [gbin ọ̀rọ̀ Ọlọ́run] sínú ọmọ rẹ, kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa wọn nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí o bá ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.” (Diutarónómì 6:7) Tẹlifíṣọ̀n ò lè tọ́ ọmọ, àwọn òbí fúnra wọn ló lè tọ́ wọn lọ́nà tó dára jù lọ nípa ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá ń bá wọn sọ àti àpẹẹrẹ tí wọ́n bá fi lélẹ̀ “ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí [wọn] yóò tọ̀.”—Òwe 22:6.