ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 7/15 ojú ìwé 32
  • “Látòní Yìí Lọ,Mo Gbà Pé Ọlọ́run Wà”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Látòní Yìí Lọ,Mo Gbà Pé Ọlọ́run Wà”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 7/15 ojú ìwé 32

“Látòní Yìí Lọ,Mo Gbà Pé Ọlọ́run Wà”

LỌ́JỌ́ kan, obìnrin ọmọ ilẹ̀ Ukraine kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Alexandra tó ń gbé nílùú Prague, lórílẹ̀-èdè Czech ń padà lọ sílé láti ibi iṣẹ́. Nígbà tó dé ibùdókọ̀ èrò, ó rí àpamọ́wọ́ kékeré kan nílẹ̀ táwọn tó ń kọjá ń fẹsẹ̀ gbá nílẹ̀. Ó mú àpamọ́wọ́ náà, ó sì ṣí i láti wo ohun tó wà nínú rẹ̀. Ẹnu yà á nígbà tó rí adúrú nǹkan tó wà ńbẹ̀. Ìdìpọ̀ owó ńlá kan tí bébà rẹ̀ kọ̀ọ̀kan jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún koruna, ìyẹn owó tí wọ́n ń ná lórílẹ̀-èdè Czech, ló wà nínú rẹ̀! Kò sẹ́ni tó dà bíi pé ó ń wá àpamọ́wọ́ náà nínú gbogbo àwọn tó wà nítòsí ibẹ̀. Àtijẹ-àtimu sì nira gan-an fún Alexandra nítorí pé àjèjì ló jẹ́ lórílẹ̀-èdè Czech. Kí ló máa wá ṣe báyìí?

Nígbà tí Alexandra délé, ó fi àpamọ́wọ́ náà han ọmọ rẹ̀ obìnrin tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Victoria. Òun àti Victoria yẹ àpamọ́wọ́ náà wò bóyá wọ́n á rí orúkọ àti àdírẹ́sì ẹni tó ni ín, àmọ́ wọn ò rí nǹkan tó jọ ọ́. Ṣùgbọ́n, bébà kan wà nínú àpamọ́wọ́ náà tí wọ́n kọ àwọn nọ́ńbà kan sí lára. Nọ́ńbà àkáǹtì owó ní báńkì wà lójú ewé àkọ́kọ́, onírúurú nọ́ńbà sì wà lódìkejì. Bébà kan tún wà nínú àpamọ́wọ́ náà tí wọ́n fi ṣàpèjúwe ọ̀nà téèyàn lè gbà dé báńkì kan tó wà nílùú yẹn, bébà míì sì tún wà tí wọ́n kọ “330,000 koruny” (tó jẹ́ nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá owó dọ́là) sí lára. Iye owó tó wà nínú àpamọ́wọ́ náà gan-an nìyẹn.

Alexandra lo ọ̀kan lára nọ́ńbà yẹn tó jọ nọ́ńbà tẹlifóònù láti fi pe báńkì náà lọ́pọ̀ ìgbà, àmọ́ kò wọlé. Lòun àti ọmọ rẹ̀ bá gbọ̀nà báńkì yẹn lọ láti lọ ṣàlàyé fún wọn bí ọ̀rọ̀ owó náà ṣe jẹ́. Wọ́n bi àwọn òṣìṣẹ́ báńkì bóyá wọ́n mọ ẹni tó ń lo nọ́ńbà àkáǹtì tí wọ́n rí nínú àpamọ́wọ́ náà. Àmọ́, àkọsílẹ̀ báńkì náà fi hàn pé kò sẹ́ni tó ń lo nọ́ńbà àkáǹtì yìí. Nígbà tó dọjọ́ kejì, Alexandra tún padà lọ sí báńkì náà, ó sì fi nọ́ńbà míì tó wà nínú àpamọ́wọ́ náà hàn wọ́n. Báńkì yẹn gan-an ni obìnrin tó ni nọ́ńbà àkáǹtì náà máa ń lò. Alexandra àti Victoria kàn sí obìnrin náà, ó sì sọ fún wọn pé àpamọ́wọ́ òun sọ nù lóòótọ́. Nígbà tí wọ́n pàdé, obìnrin náà dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ wọn, ó wá bi wọ́n pé: “Kí ni kí n fún yín fún owó mi tẹ́ ẹ bá mi rí yìí?”

Victoria sọ fún un pé: “A ò ní gba nǹkan kan lọ́wọ́ yín. Ká lá a fẹ́ gbé owó yẹn lọ ni, à bá ti gbé e lọ.” Victoria wá fi táátààtá tó gbọ́ nínú èdè Czech sọ fún un pé: “Ohun tó jẹ́ ká gbé owó yìí wá fún yín ni pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá. Ẹ̀rí ọkàn wa tá a ti fi Bíbélì kọ́ kò ní jẹ́ ká sọ nǹkan oníǹkan di tiwa.” (Hébérù 13:18) Tayọ̀tayọ̀ ni obìnrin náà fi sọ pé, “Látòní yìí lọ, mo gbà pé Ọlọ́run wà.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́