Ṣé Wíwọ Ẹ̀wù Onírun Ló Ń jẹ́ Kéèyàn Sún Mọ́ Ọlọ́run?
ỌBA LOUIS KẸSÀN-ÁN ti ilẹ̀ Faransé wọ ẹ̀wù onírun. Nígbà tí Alàgbà Thomas More wà ní ọ̀dọ́, tó ń kọ́ iṣẹ́ amòfin, oṣù bíi mélòó kan ni ẹ̀wù onírun tó wọ̀ fi ràn án lọ́wọ́, tí kì í jẹ́ kó sùn fún wákàtí mọ́kàndínlógún sí ogún wákàtí lójoojúmọ́. Àní, èyí tó pọ̀ jù lọ nínú ìgbésí ayé More ló fi wọ ẹ̀wù onírun. Kódà, ó ya àwọn èèyàn lẹ́nu láti rí aṣọ onírun lábẹ́ aṣọ Thomas Becket, tó jẹ́ bíṣọ́ọ̀bù àgbà ti ìlú Canterbury, nígbà tí wọ́n pa á nínú ṣọ́ọ̀ṣì ńlá kan ní Canterburỵ. Kí làwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn tí ìtàn sọ nípa wọn yìí fi jọra? Gbogbo wọn ló wọ ẹ̀wù onírun láti jẹ ara wọn níyà kí wọ́n lè yàgò fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara.
Ẹ̀wù onírun yìí jẹ́ ẹ̀wù kan tó máa ń ṣe háráhárá tí wọ́n máa ń fi irun ewúrẹ́ ṣe tí wọ́n sì máa ń wọ̀ bí àwọ̀tẹ́lẹ̀. Ńṣe ló máa ń yún àwọn tó bá wọ̀ ọ́ lára, tó sì máa ń jẹ́ kára ni wọ́n gan-an. Ẹ̀wù onírun yìí tún máa ń ní iná lára gan-an. A gbọ́ pé Thomas Becket wọ ẹ̀wù onírun tiẹ̀ pẹ̀lú ṣòkòtò àwọ̀tẹ́lẹ̀ tí wọ́n fi irun ewúrẹ́ ṣe, ó wọ̀ ọ́ títí “iná fi bo ẹ̀wù náà.” Lẹ́yìn ọ̀rúndún kẹrìndínlógún làwọn kan wá ń fi wáyà tó láwọn irin ṣóńṣó tíntìntín lára rọ́pò irun ewúrẹ́. Wọ́n á fi wáyà náà hun ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n á sì jẹ́ kí àwọn irin ṣóńṣó tíntìntín náà máa kàn wọ́n lára. Wáyà tí wọ́n wá ń fi hun ẹ̀wù yìí ló ń jẹ́ kí ara ni èèyàn jù.
Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwé atúmọ̀ èdè kan sọ, ìdí táwọn èèyàn fi máa ń wọ ẹ̀wù onírun táwọn kan sì máa ń fìyà jẹ ara wọn láwọn ọ̀nà mìíràn ni, “láti kápá àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ dẹni tó ń gbé ìgbésí ayé wọn lọ́nà tó máa túbọ̀ múnú Ọlọ́run dùn.” Kì í ṣe àwọn tó ń ṣẹ́ ara wọn níṣẹ̀ẹ́ nítorí ìsìn nìkan ló wọ ẹ̀wù náà o, àwọn gbáàtúù èèyàn wọ̀ ọ́, bẹ́ẹ̀ náà làwọn lóókọlóókọ nínú iṣẹ́ ìjọba wọ̀ ọ́ pẹ̀lú. Àní, àwọn onísìn kan lóde òní ṣì máa ń wọ ẹ̀wù onírun.
Ṣé wíwọ aṣọ onírun tàbí kéèyàn máa fi àwọn nǹkan kan du ara rẹ̀ ló ń múni sún mọ́ Ọlọ́run? Rárá o, sísún mọ́ Ọlọ́run kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Kódà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé “ìfìyàjẹ ara” ẹni kò dára. (Kólósè 2:23)a Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó túmọ̀ sí pé èèyàn ń fi ọkàn sin Ọlọ́run ní ti gidi ni pé kéèyàn máa wá ìmọ̀ Ọlọ́run nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ taápọntaápọn kó sì máa fi ìmọ̀ náà sílò nínú ìgbésí ayé rẹ̀.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tó o bá túbọ̀ fẹ́ mọ̀ sí i, wo Jí! October 8, 1997, lábẹ́ àkòrí náà, “Ojú Ìwòye Bíbélì: Ìṣẹ́ra-Ẹni-Níṣẹ̀ẹ́ Ha Ni Ọ̀nà Àtilọ́gbọ́n Bí?”
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]
Ọba Louis kẹsàn-án, lókè: Látinú ìwé Great Men and Famous Women; Thomas Becket, láàárín: Látinú ìwé Ridpath’s History of the World (Ìdìpọ̀ Kẹrin). Thomas More, nísàlẹ̀: Látinú ìwé Heroes of the Reformation, 1904