“Nítorí Ọmọ Ọdún Mẹ́sàn-Án Kan”
NÍGBÀKÍGBÀ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá ti wá sílé obìnrin kan tó ń jẹ́ Wiesława, tó ń gbé lápá gúúsù ilẹ̀ Poland, ńṣe ló máa rọra dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn táá sì sọ fún wọn pé òun kò fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn. Àmọ́ lọ́jọ́ kan, ọmọ ọdún mẹ́sàn-án kan tó ń jẹ́ Samuel àti màmá rẹ̀ wá sílé obìnrin yìí. Lọ́tẹ̀ yìí, Wiesława pinnu láti gbọ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n fẹ́ bá a sọ látinú Bíbélì, ó sì gba ìwé ìròyìn kan tó sọ nípa Párádísè tó máa wà lórí ilẹ̀ ayé.
Nítorí pé àkókò àtiṣe Ìrántí Ikú Jésù Kristi ti ń sún mọ́ nígbà yẹn, ó wu Samuel láti pe Wiesława wá síbi àkànṣe ìpàdé yìí. Nípa bẹ́ẹ̀, òun àti màmá rẹ̀ padà lọ sọ́dọ̀ Wiesława, wọ́n sì mú ìwé ìkésíni kan dání. Bí Wiesława ṣe rí ọmọdékùnrin yìí tó múra dáadáa, ló bá sọ pé kí wọ́n dúró ná, òun ń bọ̀, ó sì wọlé lọ múra dáadáa. Nígbà tó padà dé, ó tẹ́tí sí Samuel ó sì gba ìwé ìkésíni náà, ó wá béèrè pé: “Ṣé èmi nìkan ni kí n wá, àbí kí ọkọ mi náà wá pẹ̀lú?” Lẹ́yìn náà ló tún wá sọ pé: “Bí ọkọ mi ò tiẹ̀ wá, èmi á wá. Nítorí tiẹ̀ ni màá sì ṣe wá, Samuel.” Obìnrin yìí wá gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ, inú Samuel sì dùn gan-an.
Nígbà tí àsọyé Ìrántí náà ń lọ lọ́wọ́, Samuel jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ Wiesława ó sì ń fi àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ẹni tó ń sọ àsọyé ń jíròrò hàn án. Èyí wú u lórí gan-an. Ó gbádùn ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ó sì mọrírì bí ẹni tó sọ àsọyé náà ṣe ṣàlàyé àwọn kókó pàtàkì lọ́nà tó rọrùn gan-an. Bákan náà, bí àwọn ará ìjọ ṣe kí i dáadáa tí wọ́n sì fìfẹ́ hàn sí i múnú rẹ̀ dùn gan-an. Látìgbà náà, Wiesława ti wá túbọ̀ mọrírì àwọn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn Ọlọ́run, ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà déédéé. Ó sọ láìpẹ́ yìí pé: “Ó tì mí lójú gan-an pé mi ò kì í tẹ́tí sí i yín tẹ́lẹ̀ nígbà tẹ́ ẹ bá wá sílé mi. Mo sì ní láti jẹ́wọ́ fún un yín pé nítorí ọmọ ọdún mẹ́sàn-án kan ni mo ṣe tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ yín, ìyẹn Samuel.”
Bíi ti Samuel tó ń gbé nílẹ̀ Poland, ọ̀pọ̀ àwọn èwe tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu wọn àti ìwà wọn tó dára yin Ọlọ́run. Bó bá jẹ́ pé ọmọ kékeré ni ọ́, ìwọ náà lè ran àwọn èèyàn tó fẹ́ mọ òtítọ́ lọ́wọ́ láti dẹni tó mọyì àwọn ìlànà Ọlọ́run tó ń ṣeni láǹfààní.