Bí Wọ́n Ṣe Ń Mọ̀nà Lórí Agbami Òkun
ÀWỌN erékùṣù ńlá àtàwọn erékùṣù kéékèèké tó lé ní ẹgbẹ̀fà [1,200] ló para pọ̀ jẹ́ Marshall Islands. Ọ̀pọ̀ lára àwọn erékùṣù wọ̀nyí ló jẹ́ pé kò ju nǹkan bíi mítà mẹ́fà tí wọ́n fi yọ sókè lórí òkun. Láìjẹ́ pé èèyàn bá lọ sáàárín agbami òkun dáadáa, èèyàn kì í rí wọn. Síbẹ̀, àwọn ará Marshall tí wọ́n máa ń fi ọkọ̀ wọn rìnrìn àjò lójú agbami òkun nígbà àtijọ́ máa ń mọ̀nà láti erékùṣù kékeré kan lọ sí òmíràn lórí Òkun Pàsífíìkì. Àgbègbè yẹn sì fẹ̀ tó mílíọ̀nù méjì kìlómítà níbùú àti lóròó. Báwo ni wọ́n ṣe ń mọ̀nà? Àwòrán atọ́ka kan tí wọ́n fi igi wẹ́wẹ́ ṣe ni wọ́n máa ń lò. Àwòrán náà kò díjú, ó sì wúlò gan-an.
Nítorí pé àwọn ará erékùṣù Marshall tí wọ́n máa ń rìnrìn àjò lójú agbami òkun mọ iṣẹ́ náà gan-an, bí erékùṣù kan bá tiẹ̀ wà ní nǹkan bí ọgbọ̀n [30] kìlómítà sí wọn, wọ́n á mọ̀. Ohun tó máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ ni bí ìgbì òkun bá ṣe rí. Wọ́n gbọ́dọ̀ mọ oríṣiríṣi ọ̀nà tí ìgbì òkun ń gbà yí padà. Àwòrán atọ́ka tí wọ́n fi igi wẹ́wẹ́ ṣe ló sì máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ̀ ọ́n. Báwo ni àwòrán atọ́ka náà ṣe rí? Bí ìwọ náà ṣe rí i nínú àwòrán tó wà níbí yìí, ẹ̀ka igi àgbọn tí wọ́n là sí wẹ́wẹ́ ni wọ́n máa ń so pa pọ̀ tí wọ́n á fi ṣe iṣẹ́ ọnà tó dúró fáwọn ìgbì òkun náà. Wọ́n máa ń so àwọn ìkarawun kéékèèké tí wọ́n máa ń rí létí òkun mọ́ àwọn ibì kan lára àwọn igi wẹ́wẹ́ náà, ìwọ̀nyí sì dúró fún bí erékùṣù kọ̀ọ̀kan ti jìnnà síra wọn tó.
Ọ̀pọ̀ ọdún ni lílo àwòrán atọ́ka tí wọ́n fi igi wẹ́wẹ́ ṣe yìí fi jẹ́ àṣírí, kìkì àwọn mélòó kan ni wọ́n sì fi àṣírí náà hàn. Báwo ni ọ̀dọ́ awakọ̀ òkun ṣe máa ń mọ béèyàn ṣe lè lo àwòrán atọ́ka yìí? Ńṣe ni wọ́n máa kọ́ ọ táá sì máa fi dánra wò déédéé. Awakọ̀ òkun tó ti mọ àwòrán atọ́ka náà lò dáadáa ló máa kọ́ ọmọ ẹ̀kọ́ṣẹ́ náà. Ó lè jẹ́ nípa mímú un rìnrìn àjò lọ sí àwọn erékùṣù tó wà nítòsí. Bí ọmọ ẹ̀kọ́ṣẹ́ náà ti ń lóye oríṣiríṣi ọ̀nà tí ìgbì òkun ń gbà yí padà, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn rẹ̀ á máa balẹ̀ láti lo àwòrán atọ́ka rẹ̀ dáadáa. Nígbà tó bá wá yá, òun fúnra rẹ̀ á lè dá rìnrìn àjò lójú agbami òkun.
Lọ́nà kan náà, Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè ṣamọ̀nà wa nínú ìrìn àjò ìgbésí ayé wa. Lákọ̀ọ́kọ́, ẹnì kan á ràn wá lọ́wọ́ láti mọ àwọn ohun tó yẹ kéèyàn kọ́kọ́ mọ̀ nínú Ìwé Mímọ́. Lẹ́yìn náà, bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìṣó tá a sì ń fi àwọn ìlànà rẹ̀ sílò, àá lè gbára lé ohun tó bá sọ. Jèhófà sọ fún Jóṣúà, aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé kó bàa lè “kíyè sára láti máa ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí a kọ sínú rẹ̀.” Ó sọ fún Jóṣúà pé, “Nígbà náà ni ìwọ yóò mú kí ọ̀nà rẹ yọrí sí rere, nígbà náà ni ìwọ yóò sì hùwà ọgbọ́n.” (Jóṣúà 1:8) Dájúdájú, Bíbélì lè fi ọ̀nà tó dájú tó sì máa yọrí sí rere hàn wá nígbèésí ayé wa.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]
© Greg Vaughn