“Kí Nìdí Tá A Fi Wà Láàyè?”
NÍGBÀ kan rí, ọ̀gbẹ́ni Elie Wiesel tó gba ẹ̀bùn Nobel, tó sì wà lára àwọn tó yè bọ́ nígbà ìjọba Násì tí wọ́n ti pa àwọn èèyàn rẹpẹtẹ, sọ pé ìbéèrè kan wà tó jẹ́ “ìbéèrè pàtàkì jù lọ tó yẹ kí ọmọ èèyàn ronú lé lórí.” Ìbéèrè wo nìyẹn? Òun ni, “Kí nìdí tá a fi wà láàyè?”
Ǹjẹ́ o ti ronú lórí ìbéèrè yẹn rí? Ọ̀pọ̀ èèyàn ti ronú lórí ẹ̀ gan-an, àmọ́ wọn ò lè dáhùn rẹ̀. Òpìtàn kan tó ń jẹ́ Arnold Toynbee, tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, gbìyànjú láti dáhùn ìbéèrè yìí. Ó sọ pé: “Ìdí tọ́mọ èèyàn fi wà láàyè ni láti máa yin Ọlọ́run lógo kó sì máa jẹ̀gbádùn iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọ́run títí ayé.”
Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́ta sẹ́yìn lẹnì kan ti sọ ìdáhùn ìbéèrè yẹn kan náà. Sólómọ́nì ọlọgbọ́n Ọba táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa pé ó fara balẹ̀ ṣàkíyèsí ìgbésí ayé ẹ̀dá gan-an ló sọ ọ́. Ó ní: “Òpin ọ̀ràn náà, lẹ́yìn gbígbọ́ gbogbo rẹ̀, ni pé: Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Nítorí èyí ni gbogbo iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ti ènìyàn.”—Oníwàásù 12:13.
Jésù Kristi Ọmọ Ọlọ́run fi hàn pé òótọ́ ni ohun tó jẹ́ ìlànà pàtàkì yìí. Nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé, gbogbo ipá rẹ̀ ló sà láti ṣe ohun tó máa fi yin Baba rẹ̀ ọ̀run lógo. Sísìn tí Jésù ń sin Ẹlẹ́dàá rẹ̀ mú káyé rẹ̀ dùn gan-an. Ó fún un lókun, àní débi tó fi sọ pé: “Oúnjẹ mi ni kí n ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi.”—Jòhánù 4:34.
Kí wá nìdí tá a fi wà láàyè? Tá a bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, àwa náà yóò lè gbé ìgbé ayé rere, ayé wa yóò sì dùn bíi ti Jésù, Sólómọ́nì àti ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Ọlọ́run míì tó ṣèfẹ́ Ọlọ́run. Ṣé wàá fẹ́ mọ̀ sí i nípa bó o ṣe lè máa sin Ọlọ́run “ní ẹ̀mí àti òtítọ́”? (Jòhánù 4:24) Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nítòsí rẹ̀ yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè rí ìdáhùn ìbéèrè náà, “Kí nìdí tá a fi wà láàyè?”