Ó Rọrùn Láti Kà Lóòótọ́, Àmọ́ Ǹjẹ́ Ó Péye?
LÓṢÙ September, ọdún 2005, tayọ̀tayọ̀ ni Ṣọ́ọ̀ṣì Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì fi fọwọ́ sí i pé káwọn èèyàn máa lo Bíbélì kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe jáde, èyí tí wọ́n pè ní The 100-Minute Bible [ìyẹn Bíbélì kan téèyàn lè kà tán láàárín ọgọ́rùn-ún ìṣẹ́jú péré]. Wọ́n ṣe é lọ́nà táá fi ṣeé kà tán ní ọgọ́rùn-ún ìṣẹ́jú, nípa ṣíṣàkópọ̀ ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sí ojú ìwé mẹ́tàdínlógún, tí wọ́n sì ṣàkópọ̀ ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì sórí ojú ìwé mẹ́tàlélọ́gbọ̀n. Wọ́n yọ gbogbo ibi tẹ́nì kan tó ṣàyẹ̀wò Bíbélì ọ̀hún pè ní “àwọn apá tó máa ń sú èèyàn ní kíkà,” kúrò nínú rẹ̀. Lóòótọ́ ló rọrùn láti kà, àmọ́ ǹjẹ́ ó péye?
Yàtọ̀ sí Jèhófà, tí í ṣe orúkọ Ọlọ́run, tí wọ́n yọ kúrò nínú rẹ̀, ọ̀pọ̀ àṣìṣe mìíràn ni àwọn tó bá jẹ́ ojúlówó àkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa rí nínú rẹ̀. (Sáàmù 83:18) Bí àpẹẹrẹ, ìsọ̀rí àkọ́kọ́ nínú Bíbélì ọ̀hún sọ pé Ọlọ́run “dá ọ̀run àti ayé láàárín ọjọ́ mẹ́fà péré.” Àmọ́, ohun tí ìwé Jẹ́nẹ́sísì 1:1 wulẹ̀ sọ ni pé: “Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, Ọlọ́run dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” Lẹ́yìn náà ló ṣẹ̀ṣẹ̀ wá pèsè ẹkúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa bó ṣe gba Ọlọ́run ní “ọjọ́” mẹ́fà tàbí àwọn àkókò, láti ṣẹ̀dá ayé àtàwọn ohun ti ń bẹ nínú wọn. Ẹ̀yìn èyí ni ìwé Jẹ́nẹ́sísì 2:4 tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá ṣàkópọ̀ gbogbo àkókò ìṣẹ̀dà náà tó sì pè é ní “ọjọ́ tí Jèhófà Ọlọ́run ṣe ilẹ̀ ayé àti ọ̀run.”
Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ọlọ́gọ́rùn-ún ìṣẹ́jú yìí ṣe sọ, ó ní “Sátánì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run, . . . ẹni tí iṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ láti máa ta ko ìran èèyàn” gbé ìṣòro bá Jóóbù tó jẹ́ ọkùnrin olóòótọ́. Ǹjẹ́ o kíyè sí àṣìṣe tó wà níbí yìí? “Alátakò” ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà, “Sátánì.” Torí náà, dípò tá a ó fi ka Sátánì sí ìránṣẹ́ Ọlọ́run, olórí ọ̀tá Ọlọ́run tó dìídì sọ ara rẹ̀ di ẹni tó ń fẹ̀sùn kan aráyé ni Sátánì jẹ́.—Ìṣípayá 12:7-10.
Tá a bá wá yẹ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì wò nínú Bíbélì ọlọ́gọ́rùn-ún ìṣẹ́jú yìí ńkọ́? Nínú àkàwé Jésù nípa àgùntàn àti ewúrẹ́, Bíbélì yìí sọ pé Jésù ń fójú rere hàn sí “ẹnikẹ́ni, bó ti wù kẹ́ni ọ̀hún máà já mọ́ nǹkan kan tó,” nígbà tó sì jẹ́ pé ohun tí Jésù ń sọ ni pé, òun yóò bù kún àwọn tó bá ń ṣe dáadáa sáwọn “arákùnrin” òun, ìyẹn àwọn tó ń tẹ̀ lé ipa ọ̀nà ìgbésí ayé òun. (Mátíù 25:40) Bíbélì yìí ṣàkópọ̀ ìwé Ìṣípayá nígbà tó sọ pé “ìlú Róòmù, ìyẹn Bábílónì ńlá, yóò pa run yan-ányán-án.” Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ̀ pé kò sí ẹsẹ kankan nínú ojúlówó Bíbélì tó sọ pé Róòmù ni “Bábílónì Ńlá” dúró fún.—Ìṣípayá 17:15–18:24.
Àwọn tí wọ́n fẹ́ láti sin Ẹlẹ́dàá, tí wọ́n sì fẹ́ lóye àwọn ohun tó máa ṣe fún aráyé mọ̀ pé Bíbélì tó pé pérépéré làwọn nílò. A mọ̀ pé kíka Bíbélì máa gbà ju ọgọ́rùn ìṣẹ́jú lọ, ṣùgbọ́n ṣíṣe bẹ́ẹ̀ máa mú ìbùkún tí kò lẹ́gbẹ́ wá. (Jòhánù 17:3) Á dára kó o múra tán láti ka Bíbélì tó pé pérépéré kó o bàa lè jàǹfàǹní tó wà níbẹ̀.—2 Tímótì 3:16, 17.