ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 4/15 ojú ìwé 32
  • Ìfẹ́ Ọkàn Adryana

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìfẹ́ Ọkàn Adryana
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 4/15 ojú ìwé 32

Ìfẹ́ Ọkàn Adryana

ỌMỌ ọdún mẹ́fà ni Adryana. Ó ń gbé nílùú Tulsa, ní ìpínlẹ̀ Oklahoma, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ohun kan wà tí ọkàn ọmọdébìnrin yìí ń fẹ́. Nǹkan ọ̀hún jọ èyí tí onísáàmù náà Dáfídì fẹ́, tó fi kọrin pé: “Ohun kan ni mo béèrè lọ́wọ́ Jèhófà—ìyẹn ni èmi yóò máa wá, kí n lè máa gbé inú ilé Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé mi, kí n lè máa rí adùn Jèhófà kí n sì lè máa fi ẹ̀mí ìmọrírì wo tẹ́ńpìlì rẹ̀.”—Sáàmù 27:4.

Nígbà tí Adryana wà lọ́mọ oṣù mẹ́fà péré, àwọn dókítà rí i pé ó ní oríṣi àrùn jẹjẹrẹ kan, èyí tó mú káwọn ibì kan lára iṣan tó ń bá ọpọlọ rẹ̀ ṣiṣẹ́ wú. Àìsàn gbẹ̀mígbẹ̀mí làìsàn yìí, ó sì ti mú kí ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì rọ. Àìmọye ìgbà làwọn dókítà ti ṣe iṣẹ́ abẹ fún un, wọ́n tún fún un láwọn oògùn alágbára kan fún odindi ọdún kan.

Bàbá Adryana kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ Ẹlẹ́rìí ni Adryana àti ìyá rẹ̀. Lọ́jọ́ kan, bàbá rẹ̀ lọ sílé iṣẹ́ àjọ afẹ́dàáfẹ́re kan láti bá a tọrọ ohun kan. Ó ní kí wọ́n bá òun ṣètò láti gbé e lọ síbi ìgbafẹ́ kan tó gbajúmọ̀, tó ní oríṣiríṣi nǹkan ìṣeré. Kí àwọn tó wà nílé iṣẹ́ àjọ náà tó gbà láti gbé Adryana lọ, wọ́n kọ́kọ́ fọ̀rọ̀ wá Adryana lẹ́nu wò. Adryana dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn fún gbígbà tí wọ́n gbà láti gbé òun lọ síbi ìgbafẹ́ kan, àmọ́ ó sọ fún wọn pé inú òun á dùn tó bá jẹ́ pé Bẹ́tẹ́lì ni wọ́n mú òun lọ, ìyẹn orílé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú New York. Nígbà tí Adryana gbọ́ ibi tó wu bàbá òun pé kí wọ́n gbé òun lọ, ó gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ kí wọ́n lè mú òun lọ sí Bẹ́tẹ́lì. Àwọn tó wà nílé iṣẹ́ àjọ náà rò pé Bẹ́tẹ́lì kì í ṣe ibi tí ọmọdé lè lọ tó máa gbádùn rẹ̀, àmọ́ nígbà tí wọ́n rí i pé bàbá Adryana ò ta ko ohun tí ọmọ rẹ̀ fẹ́, wọ́n gbà láti mú un lọ síbẹ̀.

Màmá Adryana, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ bá wọn lọ. Ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn tí Adryana máa lọ sí Bẹ́tẹ́lì nílùú New York. Ó sọ pé: “Jèhófà gbọ́ àdúrà mi. Mo mọ̀ pé Jèhófà á jẹ́ ká gbádùn Bẹ́tẹ́lì gan-an. Mo rí bí wọ́n ṣe ń tẹ àwọn ìwé ńlá, ìwé ìròyìn àti Bíbélì. Lílọ tí mo lọ síbẹ̀ pé mi ju lílọ síbi ìṣeré lọ.”

Adryana “rí adùn Jèhófà” lóòótọ́, inú rẹ̀ sì dùn láti rí bí nǹkan ṣe ń lọ sí ní orílé iṣẹ́ àwọn èèyàn Jèhófà lóde òní. Ó mọrírì rẹ̀ gan-an ni. Á dára tí ìwọ náà bá lè wá wo Bẹ́tẹ́lì. Yàtọ̀ sí orílé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, a tún ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ jákèjádò ayé.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́