Ohun Kan Tó Ṣe Pàtàkì Gan-An Ju Ojú Ọjọ́ Lọ
Ó FẸ́RẸ̀Ẹ́ jẹ́ gbogbo orílẹ̀-èdè ló ní òwe nípa ojú ọjọ́. Òwe ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan sọ pé: Bójú ọ̀run bá pọ́n lálẹ́, inú awakọ̀ òkun á dùn, bójú ọ̀run bá pọ́n láàárọ̀, kí awakọ̀ òkun ṣọ́ra. Lóde òní, àwọn onímọ̀ nípa ojú ọjọ́ ti wá ṣàlàyé ìdí tí ojú ọjọ́ fi máa ń rí bí òwe yẹn ṣe sọ.
Bákan náà, nígbà ayé Jésù, àwọn èèyàn máa ń wo sánmà gan-an, wọ́n á sì sọ bójú ọjọ́ ṣe máa rí lọ́jọ́ yẹn. Jésù sọ fáwọn Júù kan pé: “Nígbà tí ó bá di ìrọ̀lẹ́, ó ti di àṣà yín láti máa sọ pé, ‘Ojú ọjọ́ yóò dára, nítorí sánmà pupa bí iná’; àti ní òwúrọ̀, ‘Ojú ọjọ́ olótùútù, tí ó kún fún òjò yóò wà lónìí, nítorí sánmà pupa bí iná, ṣùgbọ́n ó ṣú dùdù.’ Ẹ mọ̀ bí a ṣe ń túmọ̀ ìrísí sánmà, ṣùgbọ́n . . . “ Ṣùgbọ́n kí ni? Jésù wá sọ ohun kan tó wọ̀ wọ́n lára gan-an, ó ní: “Àwọn àmì àkókò ni ẹ kò lè túmọ̀.”—Mátíù 16:2, 3.
Kí ni “àwọn àmì àkókò” wọ̀nyí? Ọ̀pọ̀ àmì tó fi hàn kedere pé Jésù ni ojúlówó Mèsáyà tí Ọlọ́run rán wá ni. Àwọn ohun tó ṣe mú kó rọrùn láti dá a mọ̀ dáadáa bí ìgbà tí ojú ọ̀run bá pọ́n. Àmọ́ èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn Júù ló fojú di àwọn àmì tó fi hàn pé Mèsáyà ti dé, bẹ́ẹ̀ dídé Mèsáyà ṣe pàtàkì gan-an ju mímọ bí ojú ọjọ́ ṣe rí lọ.
Bákan náà, lóde òní, àmì kan wà tó ṣe pàtàkì gan-an tó yẹ kéèyàn lóye ju bí àwọ̀ ojú ọ̀run ṣe rí lọ. Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ayé búburú yìí yóò dópin kí ayé tó dára ju èyí lọ lè dé. Ó sọ àwọn ohun kan tó máa ṣẹlẹ̀ tí àpapọ̀ wọn á jẹ́ ká mọ ìgbà tí ìyípadà yìí bá fẹ́ wáyé. Lára wọn ni ogun tó máa kárí ayé àti ìyàn. Jésù sọ pé tá a bá ti ń rí àwọn nǹkan wọ̀nyí, á jẹ pé àkókò tí Ọlọ́run máa dá sí ọ̀ràn aráyé ti sún mọ́lé nìyẹn.—Mátíù 24:3-21.
Ǹjẹ́ o rí “àmì àwọn àkókò”?