ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 5/15 ojú ìwé 32
  • “Olúwa, Kí Ló Dé Tó O Fi Dákẹ́ Tó Ò Ń Wòran?”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Olúwa, Kí Ló Dé Tó O Fi Dákẹ́ Tó Ò Ń Wòran?”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 5/15 ojú ìwé 32

“Olúwa, Kí Ló Dé Tó O Fi Dákẹ́ Tó Ò Ń Wòran?”

PÓÒPÙ Benedict Kẹrìndínlógún ló béèrè ìbéèrè yìí ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù karùn-ún ọdún 2006, nígbà tó ṣèbẹ̀wò sí ibì kan tó ti fìgbà kan rí jẹ́ àgọ́ ìṣẹ́níṣẹ̀ẹ́ nílùú Auschwitz lórílẹ̀-èdè Poland. Nígbà tó wà níbi tí ìjọba Násì ti pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn Júù àtàwọn míì, ó tún sọ pé: “Àwọn ìbéèrè tó máa ń wá síni lọ́kàn téèyàn bá débí yìí pọ̀ gan-an ni! Ńṣe lèèyàn á kàn máa bi ara rẹ̀ pé: Ibo ni Ọlọ́run wà nígbà táwọn èèyàn ń hu adúrú ìwà ibi yìí? Kí ló dé tó fi dákẹ́ tó ń wòran? Kí ló dé tó fi fàyè gba ìpànìyàn tó pọ̀ tó báyìí, tó sì jẹ́ kí ìwà ibi borí? . . . Àfi ká yáa máa fìrẹ̀lẹ̀ bẹ Ọlọ́run láìdáwọ́dúró pé: Wá nǹkan ṣe sọ́rọ̀ ọmọ èèyàn! Má gbàgbé pé ẹ̀dá ọwọ́ rẹ ni wá!”

Onírúurú nǹkan làwọn èèyàn ti sọ nípa ọ̀rọ̀ póòpù yìí. Àwọn kan sọ pé kò sọ àwọn nǹkan kan tó mọ̀ pé ó lè mú kí àṣírí àwọn nǹkan kan tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn tú. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ní kò mẹ́nu kan ìkórìíra tí wọ́n ní sáwọn Júù, èyí tó mú kí ìjọba Násì ṣe wọ́n ṣúkaṣùka nílùú Auschwitz. Àwọn kan sọ pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi hàn pé ńṣe ló ń dọ́gbọ́n wá àwíjàre fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ìjọ Kátólíìkì ṣẹ̀ tí Póòpù John Paul Kejì fi tọrọ ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún ìjọ náà. Akọ̀ròyìn ìjọ Kátólíìkì kan tó ń jẹ́ Filippo Gentiloni sọ pé: “Ó bọ́gbọ́n mu pé nígbà tí àwọn tó ń ṣe atótónu bá ṣalábàápàdé àdììtú ìbéèrè yìí, ‘Ibo ni Ọlọ́run wà nígbà táwọn èèyàn ń hu adúrú ìwà ibi yìí?,’ dípò kí wọ́n dáhùn, ńṣe làwọn alára máa ń béèrè ìbéèrè tó rọ àwọn èèyàn lọ́rùn láti dáhùn, pé: Ibo ni Póòpù Pius Kejìlá wà?” Ohun táwọn èèyàn náà ń tọ́ka sí ni bí Póòpù Pius Kejìlá ò ṣe sọ nǹkan kan nígbà tí ìjọba Násì ń pa àwọn èèyàn nípakúpa.

Ìpakúpa rẹpẹtẹ tó wáyé nígbà yẹn àti ìpẹ̀yàrun tó ti ń wáyé látọjọ́ pípẹ́ fi hàn pé “ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.” (Oníwàásù 8:9) Àmọ́, Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá ò kàn fọwọ́ lẹ́rán kó máa wo àwọn ohun búburú jáì tó ń ṣẹlẹ̀ o. Nínú Bíbélì, ó jẹ́ ká mọ ìdí tóun fi fàyè gba ìwà ibi. Ó tún fi dá wa lójú pé òun ò gbàgbé aráyé. Kódà, àkókò tó fi fàyè gba èèyàn láti máa ṣàkóso ara rẹ̀ yóò dópin láìpẹ́. (Jeremáyà 10:23) Ṣé wàá fẹ́ láti mọ̀ sí i nípa ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fáwa èèyàn? Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè mọ bí Bíbélì ṣe dáhùn ìbéèrè tó rú Póòpù Benedict Kẹrìndínlógún lójú.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]

Oświęcim Museum

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́