“Ǹjẹ́ O Mọ Orúkọ Ọlọ́run?”
NÍGBÀ tí obìnrin kan tó ń gbé lápá gúúsù ìwọ̀ oòrùn ní àárín gbùngbùn Éṣíà rí ìbéèrè yẹn, ó fẹ́ láti mọ̀ nípa rẹ̀. Ìbéèrè náà wà lára èèpo ẹ̀yìn ìwé ìròyìn wa tó ṣìkejì Ilé Ìṣọ́, ìyẹn ìwé ìròyìn Jí!, ti January 22, 2004, lédè rẹ̀. Obìnrin náà kọ̀wé sáwọn tó tẹ ìwé ìròyìn yìí pé: “Látìgbà tí mo ti ka àlàyé nípa ìbéèrè yẹn ni mo ti nífẹ̀ẹ́ sáwọn ìwé ìròyìn yín, kíkà tí mo sì ń ká àwọn ìwé ìròyìn náà ti jẹ́ kí n ka ìwà ọmọlúwàbí sí nǹkan pàtàkì. Bákan náà, ó ti mú kí n ní èrò tó dára nípa ìgbésí ayé, pé ọ̀la ń bọ̀ wá dára. Mo máa ń bá gbogbo èèyàn sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run wa àti ìbàlẹ̀ ọkàn tí ohun tí mo mọ̀ yìí máa ń mú kéèyàn ní.”
Ní ọ̀pọ̀ ibi, kódà “títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé,” làwọn èèyàn ti ń mọ orúkọ náà, Jèhófà, tó jẹ́ orúkọ Ọlọ́run. (Ìṣe 1:8) Bí àpẹẹrẹ, Yehowa, ìyẹn orúkọ Ọlọ́run lédè Turkmen, wọ́pọ̀ nínú Bíbélì tí wọ́n túmọ̀ sí èdè yẹn. Sáàmù 8:1 sọ pé: “Jèhófà Olúwa wa, orúkọ rẹ mà kún fún ọlá ńlá ní gbogbo ilẹ̀ ayé o!”
Kí obìnrin tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí lè mọ̀ sí i nípa Jèhófà Ọlọ́run, ó ní ká fún òun ní ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé méjìlélọ́gbọ̀n kan tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae. Ìwọ náà lè gba ìwé yìí lọ́wọ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.