Ẹ̀kọ́ Pàtàkì fún Àwọn Ọmọdé
ILÉ Ẹ̀KỌ́ kan nílùú Mendoza, lórílẹ̀-èdè Ajẹntínà ni Gladys ti ń ṣiṣẹ́. Lọ́jọ́ kan, bó ṣe ń kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ kíláàsì kan, ó rí olùkọ́ kan tó ń ka Iwe Itan Bibeli Mi a fáwọn ọmọ tó wà ní kíláàsì kẹrin ní ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ náà. Gladys sọ fún olùkọ́ náà pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòun, ó sì sọ pé òun lè fi hàn án bó ṣe lè jàǹfààní tó pọ̀ gan-an látinú ìwé náà. Nítorí pé ohun tí Gladys sọ fún olùkọ́ yìí dùn mọ́ olùkọ́ náà nínú, ó fẹ́ kí ìwé náà wà lára àwọn ìwé tí wọ́n a máa fi kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nílé ìwé. Àmọ́, ó ní láti gbàyè lọ́wọ́ àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ náà. Inú rẹ̀ sì dùn gan-an pé wọ́n fọwọ́ sí i.
Lẹ́yìn náà, níbi ayẹyẹ Ọjọ́ Ìwé Kíkà tó wáyé nílé ìwé náà, olùkọ́ yìí yan àkòrí kọ̀ọ̀kan fáwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ pé kí wọ́n kà á níwájú àwọn ọmọ ilé ìwé tó kù. Nítorí pé àwọn tó wà níbẹ̀ gbádùn ètò yìí gan-an, wọ́n pe olùkọ́ náà pé kó wá sórí ètò kan nílé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n kan ládùúgbò náà. Nígbà tí wọ́n sọ̀rọ̀ kan ìwà àwọn ọmọ ilé ìwé, atọ́kùn ètò náà béèrè lọ́wọ́ obìnrin náà pé: “Ọgbọ́n wo lo dá táwọn ọmọ kíláàsì rẹ ò fi ń ṣèjàngbọ̀n?” Olùkọ́ náà sọ pé òun ń lo ìwé kan tó ń jẹ́ Iwe Itan Bibeli Mi. Ó ṣàlàyé pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kò fi ẹ̀sìn kọ́ àwọn ọmọ kíláàsì òun, síbẹ̀ òun ti lo ìwé náà láti kọ́ wọn láwọn ìwà tó dáa irú bíi ìwà ọ̀wọ̀, àmúmọ́ra, ìṣọ̀kan, ìgbọràn, àti ìfẹ́. Gbogbo àwọn èèyàn ló gbà pé ẹ̀kọ́ pàtàkì lèyí jẹ́ fáwọn ọmọdé.
Ṣé wàá fẹ́ láti fi irú ẹ̀kọ́ pàtàkì yìí kọ́ àwọn ọmọ rẹ? O lè sọ fún ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé kó fún ọ ní ẹ̀dà kan Iwe Itan Bibeli Mi tó fani mọ́ra yìí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.