Ǹjẹ́ o Mọ̀ Pé Ọlọ́run Ń wò Ọ́?
ṢÉ JÈHÓFÀ tó jẹ́ Àgbà Olùṣẹ̀dá, lágbára láti rí nǹkan? Bẹ́ẹ̀ ni, ó lágbára láti rí i! Bíbélì sọ bọ́rọ̀ ṣe jẹ́ gan-an, ó ní: “Ẹni tí ó ṣẹ̀dá ojú, ṣé kò lè rí ni?” (Sáàmù 94:9) Agbára tí Jèhófà ní láti rí nǹkan ju ti àwa ẹdá èèyàn lọ fíìfíì. Kì í kàn ṣe pé ó ń wo ìrísí wa nìkan, àmọ́ òun tún ni “olùṣàyẹ̀wò àwọn ọkàn-àyà,” ó sì lágbára láti “díwọ̀n àwọn ọkàn-àyà.” (Òwe 17:3; 21:2) Àní sẹ́, Jèhófà lágbára láti mọ ohun tá à ń rò, ohun tó ń sún wa ṣe nǹkan àti ohun tí ọkàn wa ń fẹ́.
Jèhófà mọ àwọn ìṣòro tá a lè bá pàdé, ó sì máa ń dáhùn àwọn ẹ̀bẹ̀ wa. Ọ̀kan lára àwọn tó kọ sáàmù sọ pé: “Ojú Jèhófà ń bẹ lọ́dọ̀ àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́. Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; Ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.” (Sáàmù 34:15, 18) Ó mà tù wá nínú o, láti mọ̀ pé Jèhófà mọ àwọn ohun tó ń bá wa fínra, ó sì máa ń gbọ́ àwọn àdúrà tá a bá gbà látọkàn wá!
Kò sí ohunkóhun tá à ń ṣe tí Jèhófà Ọlọ́run ò mọ̀ títí kan èyí tá a ṣe níkọ̀kọ̀. Àní sẹ́, “ohun gbogbo wà ní ìhòòhò àti ní ṣíṣísílẹ̀ gbayawu fún ojú ẹni tí a óò jíhìn fún.” (Hébérù 4:13) Nítorí náà, bóyá a ṣe ohun tó tọ́ tàbí ohun tí kò tọ́, Ọlọ́run rí gbogbo ẹ̀ pátá. (Òwe 15:3) Bí àpẹẹrẹ, Jẹ́nẹ́sísì 6:8, 9 sọ pé “Nóà rí ojú rere ní ojú Jèhófà” ó sì “bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn.” Láìsí àní-àní, Nóà rí ojú rere Jèhófà, ó sì tún rí ìbùkún gbà, ìdí rẹ̀ sì ni pé ó ṣègbọràn, ó sì gbé ìgbésí ayé rẹ̀ lọ́nà tó bá ìlànà òdodo Ọlọ́run mú. (Jẹ́nẹ́sísì 6:22) Àwọn èèyàn ayé ìgbà Nóà ní tiwọn yàtọ̀ pátápátá, ọ̀daràn ni wọ́n, oníwà ìbàjẹ́ sì tún ni wọ́n. Kì í kúkú ṣe pé Ọlọ́run ò rí gbogbo ìwà ìbàjẹ́ yìí. Ọlọ́run “rí i pé ìwà búburú ènìyàn pọ̀ yanturu ní ilẹ̀ ayé, gbogbo ìtẹ̀sí ìrònú ọkàn-àyà rẹ̀ sì jẹ́ kìkì búburú ní gbogbo ìgbà.” Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Jèhófà pa àwọn èèyàn búburú yẹn run, ó sì pa Nóà àti ìdílé rẹ̀ mọ́ láàyè.—Jẹ́nẹ́sísì 6:5; 7:23.
Ṣe Jèhófà máa fojú rere wo ìwọ náà? Àní, ojú Jèhófà “ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.” (2 Kíróníkà 16:9) Láìpẹ́ Jèhófà yóò tún pa àwọn ẹni ibi run kúrò lórí ilẹ̀ ayé, yóò sì dá àwọn ọlọ́kàn-tútù sí.—Sáàmù 37:10, 11.