ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 9/1 ojú ìwé 32
  • Orúkọ Ọlọ́run Wà Nínú Orin Ilẹ̀ Rọ́ṣíà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Orúkọ Ọlọ́run Wà Nínú Orin Ilẹ̀ Rọ́ṣíà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 9/1 ojú ìwé 32

Orúkọ Ọlọ́run Wà Nínú Orin Ilẹ̀ Rọ́ṣíà

GBAJÚGBAJÀ ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà kan tó ń jẹ́ Modest Mussorgsky ṣe ìwé orin kan jáde lọ́dún 1877. Ìtan ohun tó ṣẹlẹ̀ láwọn ilẹ̀ tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn ni orin inú ìwé náà dá lé lórí. Nínú lẹ́tà kan tó kọ sí ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan, ó sọ pé: “Mo ti kọ̀wé nípa ìtàn Jesus Navinus [ìyẹn Jósúà] tí Bíbélì sọ, ohun tí Bíbélì sì sọ nípa ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni mo kọ, mo tiẹ̀ kọ nípa bí Jóṣúà ṣe ń jagun káàkiri ilẹ̀ Kénáànì tó sì ń ṣẹ́gun ní gbogbo ibi tó jagun dé.” Nínú àwọn ìtàn mìíràn tí Mussorgsky kọ, irú bí “Ìparun Senakéríbù,” ó lo àwọn ìtàn pàtàkì pàtàkì tó wà nínú Bíbélì àtàwọn èèyàn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn.

Ohun kan tá ò lè gbójú fò nínú ìtàn “Jósúà,” àti ìtàn “Ìparun Senakéríbù” tí Mussorgsky kọ lọ́dún 1874 ni pé ó sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run. Mussorgsky kọ orúkọ Ọlọ́run lọ́nà tí wọ́n gbà ń pè é léde Rọ́ṣíà, èyí tí lẹ́ta èdè Hébérù mẹ́rin yìí יהוה dúró fún, (tá à ń pè ní Jèhófà lédè Yorubà), ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìgbà ẹgbẹ̀rún méje tó fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù.

Nígbà náà, a lè rí i pé orin tí Mussorgsky kọ sílẹ̀ yìí fi hàn pé wọ́n ti mọ orúkọ Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì, ìyẹn Jèhófà, nílẹ̀ Rọ́ṣíà kó tó di ọdún 1900. Bó sì ṣe yẹ kó rí nìyẹn, torí Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ fún Mósè pé: “Èyí ni orúkọ mi fún àkókò tí ó lọ kánrin, èyí sì ni ìrántí mi láti ìran dé ìran.”—Ẹ́kísódù 3:15.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]

Ilé ẹ̀kọ́ St. Petersburg Conservatory rèé lọ́dún 1913 níbi tí wọ́n ti ń kẹ́kọ̀ọ́ orin. Ibẹ̀ ni wọ́n kó orin Mussorgsky tí wọ́n tẹ̀ sórí ìwé sí

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]

Bébà orin: Láti ilé ìkàwé The Scientific Music Library of the Saint-Petersburg State Conservatory tí wọ́n fi orúkọ N.A. Rimsky-Korsakov sọ; ojú ọ̀nà: Láti ilé ìkàwé National Library of Russia, St. Petersburg

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́