Ǹjẹ́ O Máa Ń Lo Àǹfààní Tó Bá Yọjú Láti Sọ̀rọ̀ Nípa Ohun Tó O Gbà Gbọ́?
“ǸJẸ́ òtítọ́ pọ́ńbélé tiẹ̀ wà?” Èyí ni àkòrí àròkọ kan tí wọ́n fi ṣe ìdíje fáwọn ọmọ ilé ìwé jákèjádò ilẹ̀ Poland. Ohun tí wọ́n sọ fáwọn ọmọ náà nípa àròkọ ọ̀hún ni pé: “A ò nílò òtítọ́ pọ́ńbélé. Kò sẹ́ni tó nílò rẹ̀. Kò tiẹ̀ sí òtítọ́ pọ́ńbélé pàápàá.” Agata, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tó wà nílé ìwé girama tó sì tún jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, pinnu láti lo àǹfààní yìí láti sọ ohun tó gbà gbọ́ fáwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀.
Nígbà tí Agata ń múra àtikọ àròkọ náà, ó kọ́kọ́ gbàdúrà sí Jèhófà pé kó tọ́ òun sọ́nà. Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í wá àwọn ìwé tó sọ̀rọ̀ lórí kókó náà. Ó rí àwọn àlàyé tó jẹ mọ́ àkòrí náà nínú Ilé-Ìṣọ́nà ti July 1, 1995. Ó ṣàyọlò ìbéèrè tí Pọ́ńtíù Pílátù béèrè lọ́wọ́ Jésù pé: “Kí ni òtítọ́?” (Jòhánù 18:38) Ó wá sọ pé ìbéèrè yẹn fi hàn pé Pílátù ò gbà pé ohun kan wà tó ń jẹ́ òtítọ́, bí ìgbà tó ń sọ pé: ‘Òtítọ́ kẹ̀? Kí ló ń jẹ́ bẹ́ẹ̀ ná? Kò tiẹ̀ sóhun tó jọ ọ́!’ Agata tún sọ pé: “Ìbéèrè Pílátù yẹn rán mi létí àkòrí ìdíje náà àti ohun tí wọ́n sọ fún wa nípa àròkọ ọ̀hún.”
Ó tún sọ̀rọ̀ lórí ohun tó dóde báyìí, ìyẹn ni ohun tó wù mí ò wù ọ́, tó túmọ̀ sí pé ohun tó tọ́ lójú ẹnì kan lè má tọ́ lójú ẹlòmíràn, àwọn méjèèjì sì lè “tọ̀nà.” Ó wá béèrè àwọn ìbéèrè bíi, “Ǹjẹ́ a rí ẹnikẹ́ni nínú wa tó máa jẹ́ wọ ọkọ̀ òfuurufú tónítọ̀hún ò bá gbà pé àwọn òfin tó ń darí afẹ́fẹ́ ṣe é gbára lé?” Ẹ̀yìn ìyẹn ló tọ́ka sí Bíbélì, ó sì sọ pé: “A lè gbára lé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nítorí pé ó sinmi lórí òtítọ́ pọ́ńbélé.” Ó wá ní òun lérò pé àwọn tó ń fi tọkàntọkàn wá òtítọ́ yóò ní sùúrù tó pọ̀ tó láti lè rí i.
Wọ́n fún Agata ní àkànṣe ìwé ẹ̀rí dípúlọ́mà kan, ó sì tún láǹfààní láti sọ̀rọ̀ níwájú gbogbo kíláàsì rẹ̀. Àwọn bíi mélòó kan lára àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ sì gbà pé kó wá máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Inú Agata dùn gan-an pé òun lo àǹfààní yìí láti sọ ohun tóun gbà gbọ́ fún ọ̀pọ̀ èèyàn. Dájúdájú, mímúratán láti sọ̀rọ̀ nípa ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn èèyàn nígbàkigbà tí àǹfààní rẹ̀ bá yọ lè so èso rere. Àǹfààní wo lo lè yọjú fún ọ láti sọ̀rọ̀ nípa ohun tó o gbà gbọ́?