“Ẹ Jọ̀wọ́ ẹ Bá Mi Fìfẹ́ Gba Ẹ̀bùn Yìí”
GBÓLÓHÙN tó wà lókè yìí fara hàn nínú lẹ́tà kan tí wọ́n rí gbà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Ẹni tó kọ lẹ́tà yẹn fi í ránṣẹ́ pẹ̀lú àpótí ńlá kan tí ìbọ̀sẹ̀ kúnnú ẹ̀.
Ìyá kan tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàdínláàádọ́rin tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Alla ló fi ẹ̀bùn yìí ránṣẹ́. Ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni, inú ìjọ kan tó wà ní Ìpẹ̀kun Ìlà Oòrùn Rọ́ṣíà ló wà, ó sì ti lé lọ́dún mẹ́wàá tó ti ń sin Jèhófà bọ̀, tó ń fìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Àmọ́, òjijì ni àìsàn rọpárọsẹ̀ kọ lù ú tó sì di pé apá kan ara rẹ̀ rọ. Síbẹ̀, ìfẹ́ tí Alla ní mú kó ṣohun tó jọ ti Dọ́káàsì, obìnrin kan tó jẹ́ Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní, tó ṣe ẹ̀wù fáwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́.—Ìṣe 9:36, 39.
Nínú lẹ́tà tí Alla kọ, ó sọ pé: “Mi ò lè gbé ẹsẹ̀ mi mọ́, àmọ́ mo ṣì lè lo ọwọ́ mi méjèèjì. Nítorí náà, lẹ́tà ni mo fi máa ń wàásù.” Ó fi kún un pé: “Níwọ̀n ìgbà tí mo ṣì lè lo ọwọ́ mi, mo pinnu pé màá hun ìbọ̀sẹ̀ mélòó kan tó ń mú ẹsẹ̀ móoru. Mo fẹ́ kẹ́ ẹ bá mi kó ìbọ̀sẹ̀ wọ̀nyí fáwọn arákùnrin àti arábìnrin tó ń lọ kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba láwọn ibi tí òtútù ti mú, irú bíi Siberia àti Ìpẹ̀kun Ìlà Oòrùn Rọ́ṣíà.”
Nígbà tí Jésù Kristi ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó jẹ́ ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tòótọ́, ó sọ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:35) Irú ìfẹ́ tí Alla ní yìí ló jẹ́ àmì téèyàn fi lè mọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tòótọ́.