Àkókò Lílekoko La Wà Yìí
BÍBÉLÌ sọ tẹ́lẹ̀ pé aráyé yóò bọ́ sí “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò.” Ó pe àkókò náà ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” (2 Tímótì 3:1-5; 2 Pétérù 3:3-7) Jésù Kristi náà sọ̀rọ̀ nípa àkókò yìí nígbà tó ń dáhùn ìbéèrè kan táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bí i nípa “ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mátíù 24:3) Ṣé ọjọ́ ìkẹyìn yẹn la wà yìí? Kó o lè fúnra rẹ mọ̀ bóyá ọjọ́ ìkẹyìn ni tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, fi àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì wé ohun táwọn ìròyìn ẹnu àìpẹ́ yìí, tó wà nísàlẹ̀ yìí, sọ.
Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì: ogun jákèjádò ayé—Lúùkù 21:10; Ìṣípayá 6:4.
Ohun tí ìròyìn àìpẹ́ yìí sọ: “Àwọn tí ogun pa láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún sí ìsinsìnyí nìkan, ju ìlọ́po mẹ́ta iye àwọn tógun ti ń pa látìgbà ìbí Kristi títí di ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn.”—Àjọ Tó Ń Rí sí Àwọn Ohun Tó Ń Lọ Lágbàáyé.
Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì: àìtó oúnjẹ àti àjàkálẹ̀ àrùn—Lúùkù 21:11; Ìṣípayá 6:5-8.
Ohun tí ìròyìn àìpẹ́ yìí sọ: Lọ́dún 2004, nǹkan bí ẹgbẹ̀rin ó lé mẹ́tàlélọ́gọ́ta [863] mílíọ́nù èèyàn ni kò róúnjẹ jẹ bó ṣe yẹ lágbàáyé. Iye yìí fi mílíọ́nù méje ju ti ọdún 2003 lọ.—Àjọ Tó Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Oúnjẹ àti Iṣẹ́ Àgbẹ̀ fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè.
Iye èèyàn tó tó bílíọ̀nù kan ló ń gbé nínú ilé jákujàku; àwọn tó dín díẹ̀ ní bílíọ̀nù mẹ́ta ni kò ní ohun tá a lè pè ní ilé ìgbọ̀nsẹ̀ àti ibi ìdàdọ̀tí sí; àwọn èèyàn tó sì lé ní bílíọ̀nù kan ni kì í rí omi tó dára mu.—Àjọ Tó Ń Rí sí Àwọn Ohun Tó Ń Lọ Lágbàáyé.
Ọgọ́rùn-ún márùn-ún [500] mílíọ́nù èèyàn ni àìsàn ibà ń yọ lẹ́nu; ogójì [40] mílíọ́nù ni àrùn éèdì ń bá fínra; ọgọ́rin ọ̀kẹ́ ni ikọ́ ẹ̀gbẹ sì pa lọ́dún 2005.—Àjọ Ìlera Àgbáyé.
Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì: báwọn èèyàn ṣe ń run ilẹ̀ ayé—Ìṣípayá 11:18.
Ohun tí ìròyìn àìpẹ́ yìí sọ: “Ìlò àpà táráyé ń lo ayé yìí ti ṣàkóbá débi pé onírúurú ẹ̀dá alààyè lè kú àkúrun láìpẹ́.” “Èyí tó fẹ́rẹ̀ẹ́ pọ̀ jú nínú ọ̀nà tí ojú ọjọ́, ohun ọ̀gbìn, ẹranko, ẹyẹ àtàwọn ohun alààyè míì gbà ń ṣiṣẹ́ pọ̀ táyé fi ṣeé gbé ni kò lọ déédéé mọ́.”—Millennium Ecosystem Assessment.
“Àwọn àfẹ́fẹ́ olóró tó ń bàyíká jẹ́, táráyé ń tú dà sínú àtẹ́gùn ti ba ojú ọjọ́ jẹ́ lọ́nà tó burú jáì, èyí tó lè kó ayé wa sínú ewu ńláǹlà.”—Àjọ NASA, àti ilé ìwé gíga Goddard Institute for Space Studies.
Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì: a ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé—Mátíù 24:14; Ìṣípayá 14:6, 7.
Ohun tí ìròyìn àìpẹ́ yìí sọ: Lọ́dún 2007, iye àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́fà, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án àti mẹ́tàdínlọ́gọ́ta, ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ àti mẹ́rìnléláàádọ́ta [6,957,854] fi àrópọ̀ wákàtí tó lé ní bílíọ̀nù kan àti àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́rin wàásù ní igba ó lé mẹ́rìndínlógójì [236] ilẹ̀ lágbàáyé.—Ìwé ọdọọdún 2008 Yearbook of Jehovah’s Witnesses.
Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ níṣàájù, Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìròyìn burúkú máa gbayé kan, ìrètí ṣì máa wà pé ayé ń bọ̀ wá dáa. Jésù sọ̀rọ̀ nípa “ìhìn rere” Ìjọba Ọlọ́run. Kí ni Ìjọba Ọlọ́run yẹn? Báwo ni Ìjọba yẹn ṣe mú kí aráyé nírètí pé ayé ṣì ń bọ̀ wá dáa? Ipa wo sì ni Ìjọba Ọlọ́run máa ní lórí rẹ?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn nǹkan tá à ń rí nínú ayé lónìí máa ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀