ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w08 8/1 ojú ìwé 27-30
  • Bíbélì Máa Ń Sọni Dèèyàn Rere

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bíbélì Máa Ń Sọni Dèèyàn Rere
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Bíbélì Máa Ń Sọni Dèèyàn Rere
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Bíbélì Máa Ń Sọni Dèèyàn Rere
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • “Mò Ń Fi Ẹ̀mí Ara Mi Tàfàlà”
    Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
w08 8/1 ojú ìwé 27-30

Bíbélì Máa Ń Sọni Dèèyàn Rere

Kí ló lè mú kí ọ̀kan lára àwọn ọmọọ̀ta kan tí wọ́n ń pe ẹgbẹ́ wọn ní Àwọn Ọmọ Èṣù, (Junior Satans) lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò yí padà di olóòótọ́ èèyàn tó kọjú mọ́ṣẹ́ rẹ̀? Kí nìdí tí obìnrin oníṣòwò ọmọ ilẹ̀ Japan kan tó rí tajé ṣe fi jáwọ́ nínú fifi gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ lépa ọrọ̀, báwo sì ni àyípadà tó ṣe yìí ṣe rí lára rẹ̀? Kí lohun tó lè mú kí ọmọ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà kan tó ń ta ohun ìjà olóró jáwọ́ nínú òwò tí kò bófin mu àmọ́ tó ń mówó wọlé yìí? Gbọ́ ohun táwọn èèyàn náà sọ.

ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ

ORÚKỌ: ADRIAN PEREZ

ỌJỌ́ ORÍ: ỌGBỌ̀N ỌDÚN

ORÍLẸ̀-ÈDÈ: MẸ́SÍKÒ

IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: ỌMỌỌ̀TA

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Nígbà tí mo wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́tàlá, ìdílé wa kó lọ sí àgbègbè Ecatepec de Morelos ní Mẹ́síkò. Ní àkókò yẹn, ìwà ìpáǹle àwọn ọ̀dọ́, ìwà bàsèjẹ́ àti lílo oògùn olóró gbòde kan ní àgbègbè náà. Kò sì pẹ́ témi náà fi di ọ̀mùtí, bàsèjẹ́ àti oníṣekúṣe.

Nígbà tó yá, a padà sí ìlú San Vicente tí wọ́n ti bí mi. Àmọ́ oògùn olóró ti gbòde kan níbẹ̀ náà. Ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń rí òkú àwọn ọ̀dọ́ lójú pópó. Mo wá wọ ẹgbẹ́ àwọn ọmọọ̀ta kan tí wọ́n ń pè ní Àwọn Ọmọ Èṣù. A máa ń jalè, a sì máa ń lo oògùn olóró, irú bíi fífa òórùn èròjà ti wọ́n fi ń po ọ̀dà, ìyẹn thinner, àti èròjà tí wọ́n fi ń lẹ igi pọ̀ ìyẹn glue, ságbárí. Lọ́pọ̀ ìgbà, mi kì í mọ bí mo ṣe délé, ìgbà míì sì wà tó jẹ́ pé ẹ̀gbẹ́ títì ni màá kàn sùn gbalaja sí láìmọ̀kan. Àwọn kan lára àwọn ọ̀rẹ́ mi sì ti dèrò ẹ̀wọ̀n torí olè jíjá àti ìpànìyàn.

Pẹ̀lú gbogbo ìwàkíwà mi yìí, mo ṣì gba Ọlọ́run gbọ́. Kí n lè dín bí ẹ̀rí ọkàn ṣe ń dà mí láàmú kù, mo máa ń kópa nínú ààtò ìsìn táwọn Kátólíìkì máa ń ṣe nígbà àjíǹde, irú bí eré tí wọ́n máa ń ṣe nípa bí wọ́n ṣe pa Jésù. Àmọ́ tá a bá ṣe tán, ńṣe ni gbogbo wa, títí kan ọkùnrin tó ṣe Kristi, máa ń mutí yó láti fi ṣe àjọyọ̀ ipa tá a kó.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PADÀ: Nígbà tó kù díẹ̀ kí n pé ọmọ ogún ọdún, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mo wá mọ̀ pé ìgbésí ayé tí kò nítumọ̀ ni mò ń gbé àti pé tí mo bá ń bá a lọ bẹ́ẹ̀, nǹkan kò ní dáa fún mi. Ohun tó mú mi ronú bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Gálátíà 6:8 pé: “Ẹni tí ń fúnrúgbìn pẹ̀lú níní ẹran ara rẹ̀ lọ́kàn yóò ká ìdíbàjẹ́ láti inú ẹran ara rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ń fúnrúgbìn pẹ̀lú níní ẹ̀mí lọ́kàn yóò ká ìyè àìnípẹ̀kun láti inú ẹ̀mí.” Ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́ yìí jẹ́ kí n mọ̀ pé, tí mo bá fẹ́ kí nǹkan dáa fún mi, àfi kí n máa ṣe ohun táá jẹ́ kí ọjọ́ ọ̀la mi lè dáa.

Bí mo ṣe ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi lọ, mo wá mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run alààyè tó nífẹ̀ẹ́ mi àti pé ó ṣe tán láti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ti dá jì mí. Mo tún wá kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi pé Ọlọ́run máa ń gbọ́ àdúrà.

Kì í ṣe pé ó rọrùn fún mi láti yí ìgbé ayé mi padà o. Ó ṣòro fún mi láti fi ẹgbẹ́ ọmọọ̀ta tí mo wà sílẹ̀. Àwọn àdúgbò kan tiẹ̀ wà tí mi ò lè gbà kọjá torí àwọn ẹgbẹ́ ọmọọ̀ta ibẹ̀, bó tílẹ̀ jẹ́ pé mi ò sí nínú ẹ̀gbẹ́ ọmọọ̀ta mọ́. Ìgbà míì sì wà tó jẹ́ pé ṣe ni mo máa ń fara pa mọ́ fáwọn ọ̀rẹ́ mi àtijọ́, torí wọ́n máa ń fẹ́ wá mi kàn láti fipá mú mi lọ máa hu àwọn ìwà burúkú tí mo ti fi sílẹ̀.

Ṣùgbọ́n nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo rí i pé ìwà àwọn tó wà níbẹ̀ yàtọ̀, ìjọ wọn tuni lára, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́. Bí ìgbàgbọ́ àwọn èèyàn náà ṣe jẹ́ ojúlówó àti bí wọ́n ṣe ń fi ohun tí wọ́n ń kọ́ni ṣèwà hù wú mi lórí gan-an. Ká sòótọ́, èyí yàtọ̀ gan-an sóhun tó ti mọ́ mi lára.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO RÍ: Ó ti di ọdún mẹ́wàá báyìí tí mo ti ṣe ìrìbọmi tí mo sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mo ń gbìyànjú gan-an láti fi ohun tí Bíbélì kọ́ni ṣèwà hù. Èyí ti wá jẹ́ kí àwọn ẹbí mi máa bọ̀wọ̀ fún mi. Wọ́n ti wá mọ̀ mí sí òṣìṣẹ́ kára, kódà mo tún máa ń fún wọn lówó. Màmá mi náà bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, òun náà sì ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà báyìí. Bàbá mi náà ti ń yí ọ̀nà tó gbà ń gbé ìgbé ayé rẹ̀ padà báyìí. Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ẹbí mi ni kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ nígbà tí wọ́n rí bí mo ṣe yí ọ̀nà tí mo gbà ń gbé ìgbésí ayé mi padà, àwọn náà gbà pé Bíbélì lè sọni dèèyàn rere.

ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ

ORÚKỌ: YAYOI NAGATANI

ỌJỌ́ ORÍ: ÀÁDỌ́TA ỌDÚN

ORÍLẸ̀-ÈDÈ: JAPAN

IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: OBÌNRIN ONÍṢÒWÒ TÓ RÍ TAJÉ ṢE

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Ìlú kékeré kan tára àwọn èèyàn ibẹ̀ yá mọ́ni ni mo gbé dàgbà. Bàbá mi ní ilé ìtajà ńlá kan sí ìlú yẹn, ó sì gba òṣìṣẹ́ mẹ́wàá síbẹ̀. Ẹ̀gbẹ́ ilé wa ni ilé ìtajà náà wà, torí náà mi kì í dá wà tọ́wọ́ àwọn òbí mi bá tiẹ̀ dí.

Èmi ni mo dàgbà jù nínú àwọn ọmọbìnrin mẹ́ta táwọn òbí mi bí, láti kékeré sì làwọn òbí mi ti ń kọ́ mi kí n lè dẹni tí yóò máa bójú tó òwò ìdílé wa. Mi ò dàgbà púpọ̀ tí mo fi lọ́kọ. Nígbà tó yá, ọkọ mi fi iṣẹ́ tó ń ṣe nílé ìfowópamọ́ sílẹ̀, a sì jọ ń bójú tó òwò ìdílé wa. Kò sì pẹ́ tá a fi bí àwọn ọmọ wa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Màmá mi ń bá wa bójú tó àwọn ọmọ náà pẹ̀lú iṣẹ́ ilé tó ń ṣe, tí èmi yóò sì wà ní ilé ìtajà látàárọ̀ ṣúlẹ̀. Àmọ́ ṣá o, ìdílé wa ṣì máa ń ráyè ṣeré pa pọ̀.

Nígbà tó yá, ọrọ̀ ajé àgbègbè yẹn dẹnu kọlẹ̀, ni òwò tiwa náà kò bá lọ déédéé mọ́. A wá pinnu láti ṣí ilé ìtajà kan tí a ó ti máa ta àwọn ohun èlò tí wọ́n fi ń tún ilé ṣe sítòsí ojú ọ̀nà márosẹ̀ kan. Nígbà tó ku ọ̀la ká ṣe ayẹyẹ ìfilọ́lẹ̀ kíkọ́ ilé ìtajà náà, ni àrùn burúkú kan ṣàdédé kọ lu bàbá mi tó jẹ́ ọ̀gá àgbà ilé iṣẹ́ wa. Àrùn náà kò jẹ́ kí bàbá mi lè sọ̀rọ̀ rárá, bí gbogbo ètò ìkọ́lé náà ṣe já lé mi léjìká nìyẹn. Àmọ́ ọkọ mi ṣì ń bójú tó ilé ìtajà wa ti tẹ́lẹ̀. Bó ṣe di pé gbogbo ìgbà lọwọ́ wa máa ń dí nìyẹn.

Ọjà ń yá gan-an ní ilé ìtajà wa tuntun yìí. Inú mi máa ń dùn fún àṣeyọrí tí mo ṣe, torí náà ọ̀pọ̀ ìgbà ni n kì í sùn torí iṣẹ́. Lóòótọ́ mo fẹ́ràn àwọn ọmọ mi, àmọ́ iṣẹ́ mi ló gbà mí lọ́kàn jù. Mi kì í fi bẹ́ẹ̀ ráyè bá ọkọ mi sọ̀rọ̀, tá a bá sì ń sọ̀rọ̀, ńṣe la máa ń jiyàn. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í jáde lálaalẹ́ láti lọ mutí pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi àtàwọn oníbàárà mi láti lè fi pàrònú rẹ́. Gbogbo ohun tí mo wá ń ṣe kò ju kí n ṣiṣẹ́, kí n mutí, kí n sì lọ sùn. Lóòótọ́ mo rí tajé ṣe, àmọ́ mi ò láyọ̀ mọ́, mi ò sì mọ ohun tó fà á.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PADÀ: Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo rí ẹsẹ Bíbélì mẹ́ta pàtàkì tó nípa gidi lórí mi. Mo sunkún nígbà tí mo mọ ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ tó wà nínú Mátíù 5:3 tó sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn, níwọ̀n bí ìjọba ọ̀run ti jẹ́ tiwọn.” Ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ kí n mọ̀dí tí mi ò fi láyọ̀ bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo lówó tí mo sì tún gbayì láwùjọ. Mo wá rí i pé mímọ àwọn ohun tó jẹ́ ojúṣe mi nínú ìjọsìn Ọlọ́run àti ṣíṣe wọ́n ló lè jẹ́ kí n ní ojúlówó ayọ̀.

Àkókò yẹn ni ọrọ̀ ajé ilẹ̀ Japan bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sílẹ̀, ohun tó sì ń ṣẹlẹ̀ sáwọn ẹgbẹ́ mi wá jẹ́ kí n rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ inú 1 Tímótì 6:9 tó sọ pé: “Àwọn tí ó pinnu láti di ọlọ́rọ̀ máa ń ṣubú sínú ìdẹwò àti ìdẹkùn àti ọ̀pọ̀ ìfẹ́-ọkàn tí í ṣe ti òpònú, tí ó sì ń ṣeni lọ́ṣẹ́, èyí tí ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé.” Mo tún wá rí i pé ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Mátíù 6:24 kan èmi fúnra mi, níbi tó ti sọ pé, “ẹ kò lè sìnrú fún Ọlọ́run àti fún Ọrọ̀.” Ni mo bá pinnu láti ṣe àwọn àtúnṣe kan nígbèésí ayé mi.

Mo rí i pé mo ti pa àwọn òbí mi, ọkọ mi àtàwọn ọmọ mi tì. Kedere ni mo tún rí i pé mo ti dẹni tó láwọn ìwà tó kù díẹ̀ káàtó. Bí àpẹẹrẹ, mo di agbéraga, n kì í ní sùúrù fáwọn èèyàn mọ́, inú kì í sì í pẹ́ bí mi. Níbẹ̀rẹ̀, ṣe ni mo máa ń rò pé kò lè ṣeé ṣe fún mi láti yí padà di Kristẹni. Àmọ́, mo nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ mi gan-an, mo sì rí i pé bí mo ṣe ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nínú àjọṣe mi pẹ̀lú ìdílé mi ni àárín èmi àtàwọn ọmọ mi túbọ̀ ń dán mọ́rán sí i. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í lo àkókò tó pọ̀ pẹ̀lú wọn, mo sì ń mú wọn dání lọ sáwọn ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO RÍ: Ní báyìí tí mo ti mọ ìdí tá a fi wà ní ayé, tí mo dẹni tó ń sin Ọlọ́run, tí mo sì ń gbé irú ìgbésí ayé tó fẹ́, mo ti wá ní ojúlówó ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn. Mi ò tún jẹ́ kí iṣẹ́ dí mi lọ́wọ́ mọ́ débi tí mi ò fi ní ráyè gbọ́ ti ìdílé mi, ìyẹn sì ti jẹ́ kí n tún dẹni iyì padà.

Rírí tí màmá mi rí i pé ìwà mi ti yí padà sí rere bí mo ṣe ń fàwọn ìlànà Bíbélì sílò mú kóun náà kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà báyìí. Inú mi sì dùn pé bàbá mi àti ọkọ mi kò ta ko ìpinnu wa. Èmi àtàwọn ọmọ mi ti tún wá mọwọ́ ara wa gan-an, ìdílé wa sì láyọ̀.

ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ

ORÚKỌ: MIKHAIL ZUYEV

ỌJỌ́ ORÍ: ỌDÚN MỌ́KÀNLÉLÁÀÁDỌ́TA

ORÍLẸ̀-ÈDÈ: RỌ́ṢÍÀ

IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: ONÍṢÒWÒ OHUN ÌJÀ TÍ KÒ BÓFIN MU

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Ọmọ ìlú Krasnogorsk ni mí. Ewéko tútù yọ̀yọ̀ ló sì yí ìlú wa ká. Omi odò tí wọ́n ń pè ní Moscow River ṣàn gba apá gúúsù ìlú wa kọjá. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé igbó ló wà ní gbogbo apá ìwọ̀ oòrùn àti ìlà oòrùn ìlú náà.

Nígbà tí mo ṣì kéré, mo fẹ́ràn kí n máa kan ẹ̀ṣẹ́, kí n sì máa fi àwọn ohun ìjà ṣeré. Mo sì máa ń ṣe eré ìmárale gan-an. Mo tún máa ń ṣe ìbọn, ọta ìbọn àti ọ̀bẹ láìgbàṣẹ. Nígbà tó yá, mo kúkú wá sọ ọ́ diṣẹ́. Mo ń ṣe iṣẹ́ yìí lọ́nà tí kò mú ìfura lọ́wọ́, mo sì ń rí owó gidi nínú àwọn ohun ìjà tí mò ń tà fáwọn ọ̀daràn.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PADÀ: Láàárín ọdún 1990 sí 1994 ni mo pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ mi ò kọ́kọ́ fọkàn tán wọn. Mo ronú pé wọ́n ti máa ń béèrè ìbéèrè jù.

Lọ́jọ́ kan, ọ̀kan lára wọn ka ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Róòmù 14:12 fún mi, ohun tó sọ ni pé: “Olúkúlùkù wa ni yóò ṣe ìjíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.” Mo wá ń wò ó pé, kí lèmi máa wá sọ fún Ọlọ́run? Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ló mú kí n kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ kí n máa ṣe.

Mo sapá gan-an láti lè fi ìmọ̀ràn Bíbélì tó wà nínú Kólósè 3:5-10 sílò, èyí tó sọ pé: “Nítorí náà, ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé di òkú ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo, ìfẹ́-ọkàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, àti ojúkòkòrò, tí í ṣe ìbọ̀rìṣà. Ní tìtorí nǹkan wọnnì ni ìrunú Ọlọ́run fi ń bọ̀. . . . Ẹ mú gbogbo wọn kúrò lọ́dọ̀ yín, ìrunú, ìbínú, ìwà búburú, ọ̀rọ̀ èébú, àti ọ̀rọ̀ rírùn kúrò lẹ́nu yín. Ẹ má ṣe máa purọ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Ẹ bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn àṣà rẹ̀, ẹ sì fi àkópọ̀ ìwà tuntun wọ ara yín láṣọ.”

Ó ṣòro fún mi gan-an láti ṣe àwọn àtúnṣe tí ibẹ̀ yẹn sọ. Àwọn ọ̀daràn tó jẹ́ oníbàárà mi tẹ́lẹ̀, kò yéé gbówó wá fún mi pé kí n bá wọn ṣe ohun ìjà, táwọn èèyàn bá sì fìwọ̀sí lọ̀ mí, n kì í lè mú un mọ́ra. Síbẹ̀síbẹ̀, mo ba ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ohun ìjà olówó iyebíye tí mo ní jẹ́ pátápátá. Bí mo ṣe ń kọ́ nípa ìfẹ́ tí Ọlọ́run àti Kristi ní sí mi, èmi náà dẹni tó nífẹ̀ẹ́ wọn. Mo tẹra mọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí mò ń ṣe, mo ń lọ sípàdé ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nítòsí mi, mo sì ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn mí lọ́wọ́.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO RÍ: Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, mo dẹni tó níwà tó dáa, àmọ́ pẹ̀lú ìsapá gidi àti ìrànlọ́wọ́ àwọn Kristẹni arákùnrin mi ni o. Bí mo tún ṣe wá mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run bìkítà fún wa, títí kan àwọn tó ti kú, mú kí n túbọ̀ láyọ̀. (Ìṣe 24:15) Mo mọyì jíjẹ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ olóòótọ́ èèyàn tí kì í figbá kan bọ̀kan. Mo sì mọrírì ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn sí mi àti bí wọ́n ṣe jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run.

Níbẹ̀rẹ̀, àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ mi ṣàtakò sí mi torí ẹ̀sìn tuntun tí mo ń ṣe yìí. Àmọ́ nígbà tó yá, ohun tí wọ́n fi ń tu ara wọn nínú ni pé ó sàn kí n tara bọ ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ju pé kí n jẹ́ ọ̀kan lára àwọn jàǹdùkú lọ. Ní báyìí, inú mi ń dùn pé mi ò fi ohun ìjà títà ṣiṣẹ́ ṣe mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀ iṣẹ́ kíkọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run àlàáfíà ni mo gbájú mọ́.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Mo ń kópa nínú onírúurú ààtò ìsìn Kátólíìkì láti fi pẹ̀tù sí ẹ̀rí ọkàn mi

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Lóòótọ́ mo rí tajé ṣe àmọ́ mi ò láyọ̀ rárá

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́