Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .
Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fẹ́ fún aráyé ní ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun?
▪ Bíbélì sọ pé Ọlọ́run fún àwa èèyàn ní àǹfààní láti ní “ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 6:40) Àmọ́, kí nìdí tó fi fẹ́ fún wa ní ìyè àìnípẹ̀kun? Ṣé ó kàn wù ú láti ṣe ohun tó bá ìdájọ́ òdodo mu ni?
Lára ohun tí ìdájọ́ òdodo túmọ̀ sí ni pé kéèyàn máa hùwà sí àwọn èèyàn bó ti tọ́ àti bó ṣe yẹ. Ṣé àwa èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ sí ìwàláàyè? Rárá o. Bíbélì sọ pé: “Nítorí kò sí olódodo kankan ní ilẹ̀ ayé tí ń ṣe rere tí kì í dẹ́ṣẹ̀.” (Oníwàásù 7:20) Ìjìyà wà fún ẹ̀ṣẹ̀. Ọlọ́run kìlọ̀ fún Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́ pé kíkú ló máa kú lọ́jọ́ tó bá dẹ́ṣẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:17) Nígbà tó yà, Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ̀wé pé: “Owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú.” (Róòmù 6:23) Tó bá jẹ́ pé ikú ló tọ́ sí gbogbo àtọmọdọ́mọ Ádámù, kí nìdí tí Ọlọ́run fi fẹ́ fún wọn ní àǹfààní láti ní ìyè tí kò nípẹ̀kun?
“Ẹ̀bùn ọ̀fẹ́” ni ìyè àìnípẹ̀kun. Ìfẹ́ àti inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run tó ga lọ́lá tó sì tún gbòòrò ló fi hàn sí wa lọ́nà yìí. Bíbélì sọ pé: “Gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run, a sì ń polongo wọn ní olódodo gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ nípasẹ̀ ìtúsílẹ̀ nípa ìràpadà tí Kristi Jésù san.”—Róòmù 3:23, 24.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo wa ni ikú tọ́ sí, síbẹ̀, Ọlọ́run yàn láti fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ní ìyè àìnípẹ̀kun. Ṣó dáa bẹ́ẹ̀? Bíbélì sọ pé: “Kí wá ni àwa yóò wí? Àìṣèdájọ́ òdodo ha wà pẹ̀lú Ọlọ́run bí? Kí èyíinì má ṣe rí bẹ́ẹ̀ láé! Nítorí ó sọ fún Mósè pé: ‘Èmi yóò ṣe àánú fún ẹnì yòówù tí èmi yóò ṣe àánú fún, èmi yóò sì fi ìyọ́nú hàn sí ẹnì yòówù tí èmi yóò fi ìyọ́nú hàn sí.’ . . . Ta wá ni ọ́ ní ti gidi, tí o fi ń ṣú Ọlọ́run lóhùn?”—Róòmù 9:14-20.
Ní àwọn apá ibì kan láyé, ọ̀kan lára àwọn aláṣẹ gíga nínú ìjọba tàbí adájọ́ kan lè dárí ji ọ̀daràn kan tó ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀. Bí ọ̀daràn náà bá fi gbogbo ọkàn fara mọ́ ìjìyà tí wọ́n fún un tó sì yí èrò àti ìwà rẹ̀ pa dà, adájọ́ tàbí ààrẹ lè yàn láti dárí jì í nípa dídín àkókò tó máa lò lẹ́wọ̀n kù tàbí kó dá a sílẹ̀ pátápátá. Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí gbáà ni wọ́n fi hàn sírú ọ̀daràn bẹ́ẹ̀.
Bákan náà, Jèhófà lè yàn pé òun kò ní fìyà ẹ̀ṣẹ̀ jẹ gbogbo àwọn tó bá dẹ́ṣẹ̀. Kàkà kó fìyà jẹ wọ́n, ìfẹ́ tó ní lè mú kó fún gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tí wọ́n sì ń ṣe àwọn ohun tó bá ìlànà rẹ̀ mu ní ìyè àìnípẹ̀kun. Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.”—Ìṣe 10:34, 35.
Ọ̀nà tó ga jù lọ tí Jèhófà gbà fìfẹ́ hàn sí wa ni rírán tó rán Ọmọ rẹ̀ wá sáyé láti wá jìyà kó sì kú nítorí wa. Jésù sọ nípa Bàbá rẹ̀ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 3:16.
Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba gbogbo àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tí wọ́n sì ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀, láìka ibi tí wọ́n ti wá sí. Torí náà, inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun jẹ́, ó sì ń fi hàn pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa lọ́nà tó ga jù lọ.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 29]
Ìyè àìnípẹ̀kun jẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ó sì fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa lọ́nà tó ga jù lọ