Wíwàásù àti Kíkọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Nílẹ̀ Áfíríkà
ILẸ̀: 57
IYE ÈÈYÀN: 878,000,158
IYE ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ: 1,171,674
IYE ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ: 2,382,709
JÈHÓFÀ nawọ́ ẹ̀bùn iyebíye sí gbogbo èèyàn níbi gbogbo, ẹ̀bùn náà sì ni ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run. Àwa tá a ti tẹ́wọ́ gba ẹ̀bùn yìí, tá a sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà láǹfààní láti wàásù nípa rẹ̀ fún àwọn èèyàn. Bá a ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, à ń láyọ̀ pé à ń ṣe ohun tí Ẹni tó fún wa lẹ́bùn náà fẹ́ ká ṣe, a sì tún láyọ̀ pé à ń ṣe ohun tó ṣàǹfààní fún àwọn tó bá gba ẹ̀bùn náà. Kò sí àní-àní pé, ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run àtàwọn aládùúgbò wa ló jẹ́ ká máa wàásù. (Mátíù. 22:37-40) Nínú àwọn ìpínrọ̀ tó tẹ̀ lé e yìí, kà nípa bí àwọn èèyàn Jèhófà ṣe fi ìfẹ́ yìí hàn nínú bí wọ́n ṣe ń fi ìtara wàásù kárí ayé.
Benin Ó ti tó ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27] tí Claude àti Marie-Claire ìyàwó rẹ̀ ti ń fìtara ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Ní February, Marie-Claire yọ̀ ṣubú, ó sì fi ẹsẹ̀ kán. Lọ́sẹ̀ méjì lẹ́yìn náà, Claude náà ṣubú nígbà tó ń ṣiṣẹ́ nílé míṣọ́nnárì tí wọ́n ń gbé, lòun náà bá kán lẹ́sẹ̀. Àwọn méjèèjì ni wọ́n fi nǹkan dì lẹ́sẹ̀, ẹsẹ̀ ọ̀tún Marie-Claire ló kán, Claude sì kán lẹ́sẹ̀ òsì. Claude fi ọ̀rọ̀ náà ṣàwàdà pé, “Gbogbo ìgbà la máa ń fẹ́ ṣe nǹkan kan náà!”
Claude ṣì lè rìn díẹ̀, àmọ́ Marie-Claire kò lè jáde nílé fún ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣètò pé kí àwọn mẹ́rin lára àwọn méjìlá tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ máa wá sílé míṣọ́nnárì tí wọ́n ń gbé, kó sì máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, kò láǹfààní láti lọ́wọ́ nínú àwọn apá iṣẹ́ ìsìn yòókù. Nítorí náà, ó pinnu láti jókòó sídìí tábìlì kan tó kó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó pọ̀ sí níta ilé tí wọ́n ń gbé, ó sì ń wàásù fún àwọn tó ń kọjá lọ. Ní oṣù March, wákàtí mẹ́rìnlélọ́gọ́rin [83] ló lò nídìí tábìlì náà. Ǹjẹ́ Jèhófà bù kún ìdánúṣe rẹ̀ yìí? Lóṣù yẹn, ìwé ńlá mẹ́rìnlá [14], ìwé pẹlẹbẹ àádọ́ta lé nírínwó ó lé méjì [452], ọ̀ọ́dúnrún dín mẹ́wàá [290] ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! àti ìwé àṣàrò kúkúrú tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ló fún àwọn èèyàn.
Etiópíà Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Arega, tó ń gbé ní abúlé kan tó wà ní àdádó fẹ́ láti fi bébà ṣe yàrá rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwé ìròyìn ni àwọn kan ń lò ní orílẹ̀-èdè rẹ̀ láti fi ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀, òun fẹ́ láti lo bébà aláràbarà. Lọ́jọ́ kan, ó rí ọkùnrin kan nínú ọjà tó ń fún àwọn èèyàn ní ìwé pẹlẹbẹ Gbádùn Iwalaaye Lori Ilẹ Ayé Titilae! Arega gba ọ̀kan lára ìwé náà, kò sì kà á, àmọ́ ó yọ ọ́ sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, ó sì lẹ̀ ẹ́ mọ́ ògiri ilé rẹ̀. Ní ọdún méjì lẹ́yìn náà, ó ṣàkíyèsí gbólóhùn kan nínú bébà tó fi ṣe yàrá rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ tó kà pé: “Jésù jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run.” Ọ̀rọ̀ yìí yàtọ̀ sí àdììtú Mẹ́talọ́kan tí wọ́n fi kọ́ ọ. Èyí mú kí Arega fẹ́ láti mọ̀ sí i, ló bá rin ìrìn wákàtí mẹ́sàn-án lọ sí abúlé tó sún mọ́ abúlé rẹ̀ jù lọ láti wá àwọn èèyàn tó sọ pé Ọlọ́run ní Ọmọ kan. Kò rí wọn nígbà tó kọ́kọ́ lọ, ó pa dà wálé, èyí sì dùn ún gan-an. Lẹ́yìn náà, ó tún lọ, àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, wọ́n júwe ilé arákùnrin tó fún un ní ìwé pẹlẹbẹ náà. Ohun míì tún dán ìpinnu tí Arega ṣe wò torí pé nígbà tó dé ilé arákùnrin náà, ó ní láti dúró fún ọ̀pọ̀ wákàtí kí arákùnrin náà tó dé. Àbájáde ìjíròrò wọn ni pé, ó bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ Arega lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Láwọn oṣù tó tẹ̀ lé e, Arega lọ sí ìlú náà léraléra láti lọ gba ìmọ̀ Ọlọ́run. Nígbà tó bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ ní abúlé rẹ̀ nípa ohun tó ti kọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn ta kò ó, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò sì fẹ́ gbọ́rọ̀ rẹ̀. Àmọ́ kò rẹ̀wẹ̀sì, àwọn míì sì nífẹ̀ẹ́ sí ohun tó ń sọ. Nígbà tí iye àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ Bíbélì pé mẹ́tàlá, wọ́n rán Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì síbẹ̀, àwọn wọ̀nyí sì jẹ́ àkànṣe òjíṣẹ́ tí wọ́n ń fi ọ̀pọ̀ àkókó wàásù. Kò sì pẹ́ tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ogójì [40] èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn tó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó iye yìí náà ló ń wá sí ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn mẹ́jọ ló ń fìtara kéde Ìjọba Ọlọ́run ní àgbègbè yẹn ní báyìí. Àwòrán tó wà lára ilé Arega tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di arákùnrin wa kì í kàn ṣe àwòrán aláràbarà lásán.
Gánà Nítorí bí fóònù alágbèéká ṣe pọ̀ káàkiri ilẹ̀ Áfíríkà báyìí, àwọn èèyàn ń sọ pé “àyípadà rere ti bá ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀.” Ọ̀pọ̀ ilé iṣẹ́ fóònù ló ti ṣe kóríyá fún àwọn tó ń lo fóònù nítorí wọ́n fún wọn láǹfààní láti lo fóònù lọ́fẹ̀ẹ́ láwọn àkókò kan lálẹ́. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Grace lo àǹfààní yìí. Ó ṣòro fún un láti kọ́ Monica lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, torí àwọn nǹkan máa ń mú kí ọwọ́ Monica dí. Grace ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà lọ, àní ó ṣètò láti máa lọ sí ilé Monica ní aago márùn-ún àárọ̀. Monica yí ìtòlẹ́sẹẹsẹ rẹ̀ pa dà, síbẹ̀ àyè kò yọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Nítorí náà Grace ronú pé òun á máa pè é lóru lórí fóònù lọ́fẹ̀ẹ́. Monica gbà, wọ́n sì jọ ṣètò láti máa kẹ́kọ̀ọ́ lórí fóònù láago mẹ́rin ìdájí. Inú wọn kò dùn torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń lo fóònù lákòókò yẹn, èyí sì jẹ́ kó ṣòro láti bá ara wọn sọ̀rọ̀. Nítorí náà, wọ́n ṣètò pé káwọn tètè máa jí ní aago mẹ́ta òru káwọn lè máa ṣèkẹ́kọ̀ọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ṣòro fún àwọn abiyamọ méjèèjì yìí nítorí wọ́n máa ń lọ síbi iṣẹ́. Grace sọ pé: “Mo gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún mi lágbára kí n lè nífẹ̀ẹ́ láti máa ran ẹni tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ kó lè máa nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ náà. Mo ṣètò aago inú fóònù mi láti jí mi, mo sì kọ́ ara mi láti máa jí lákòókò yẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń rẹ̀ mí gan-an, mi ò jẹ́ kí ìyẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi.” Ẹ wo bí inú rẹ̀ ti dùn tó pé òun ti sapá gan-an láti ran Monica lọ́wọ́, òun sì wà níbẹ̀ nígbà tó ṣèrìbọmi ní Àpéjọ Àgbègbè “Ẹ̀mí Ọlọ́run Ń Darí Wa” tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe lọ́dún 2008! Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, Grace tún ti lo fóònù ọ̀fẹ́ lóru láti máa fi ṣèkẹ́kọ̀ọ́ obìnrin kan tó ti bẹ̀rẹ̀ sí wá sípàdé.
Mòsáńbíìkì Ní August 2008, ẹ̀wù kan já bọ́ nínú ọkọ̀ kan tó ń kọjá, ó sì já bọ́ sítòsí ilé alámọ̀ tí opó kan tó jẹ́ tálákà ń gbé, Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni obìnrin yìí. Obìnrin yìí mú ẹ̀wù náà, àwọn nǹkan tó sì rí nínú àpò ẹ̀wù náà ni ọ̀pọ̀ ìwé ẹ̀rí, àpamọ́wọ́ kéékèèké mẹ́ta tí àwọn ohun ọ̀ṣọ́ olówó ńlá àti nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan owó dọ́là wà nínú wọn. Ó fi dandan lé e pé kí ẹnì kan tó wà lábúlé yẹn fi fóònù rẹ̀ pe àwọn nọ́ńbà tẹlifóònù tó wà nínú àwọn ìwé ẹ̀rí náà láti fi tó àwọn èèyàn náà létí pé wọ́n ti sọ nǹkan nù. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, àwọn ọkùnrin mẹ́rin gbé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wá sí abúlé náà. Obìnrin Ẹlẹ́rìí yìí gbé ẹ̀wù náà àtàwọn ohun tó wà nínú rẹ̀ láìyingin fún ẹni tó ni í níṣojú àwọn aláṣẹ abúlé náà. Ọkùnrin tó ni àwọn nǹkan náà bú sẹ́kún, ó sì sọ pé ká ní ẹlòmíì ló rí ẹrù yìí tí kì í sì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni, kì bá tí sí ìdánilójú pé òun á rí i gbà pa dà. Lóòótọ́, arábìnrin wa yìí jẹ́ tálákà, àmọ́ ohun tó ṣe yìí jẹ́rìí ní àgbègbè náà, èyí sì mú ìyìn ńlá bá orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀.