ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w10 4/1 ojú ìwé 4
  • Ipa Rere Tí Ẹ̀kọ́ Jésù Kristi Ní Lórí Àwọn Èèyàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ipa Rere Tí Ẹ̀kọ́ Jésù Kristi Ní Lórí Àwọn Èèyàn
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Tẹ̀ Lé Ọ̀rọ̀ Jésù Nínú Ìwà àti Ìṣe Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • “Ènìyàn Mìíràn Kò Tíì Sọ̀rọ̀ Báyìí Rí”
    “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn”
  • Ǹjẹ́ O Máa Ń Tẹ̀ Lé Ọ̀rọ̀ Jésù Tó O Bá Ń Gbàdúrà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ìwàásù Tí O Lókìkí Julọ Tí A Tíì Fúnni Rí
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
w10 4/1 ojú ìwé 4

Ipa Rere Tí Ẹ̀kọ́ Jésù Kristi Ní Lórí Àwọn Èèyàn

“Ẹ̀rí kan tí kò ṣeé já ní koro pé amòye tó wá láti Kápánáúmù yìí jẹ́ èèyàn ńlá ni pé àwọn èèyàn ò gbàgbé ọ̀rọ̀ rẹ̀.”a—ÒǸṢÈWÉ TÓ Ń JẸ́ GREGG EASTERBROOK.

Ọ̀RỌ̀ lágbára. Ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n téèyàn ronú jinlẹ̀ kó tó sọ lè wọni lọ́kàn, ó lè fúnni ní ìrètí, ó sì lè mú kéèyàn yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà. Kò tíì sí ẹ̀dá èèyàn kan tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ lágbára bíi ti Jésù Kristi. Nígbà tó yá, ẹnì kan tó fi etí ara rẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù, tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí Ìwàásù Lórí Òkè, sọ pé: “Wàyí o, nígbà tí Jésù parí àwọn àsọjáde wọ̀nyí, ìyọrísí rẹ̀ ni pé háà ń ṣe ogunlọ́gọ̀ sí ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀.”—Mátíù 7:28.

Lóde òní, kárí ayé ni ọ̀pọ̀ èèyàn ti mọ ọ̀rọ̀ Jésù. Jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò díẹ̀ lára àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó nítumọ̀ tó lágbára.

“Ẹ kò lè sìnrú fún Ọlọ́run àti fún Ọrọ̀.”—Mátíù 6:24.

“Nítorí náà, gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.”—Mátíù 7:12.

“Ẹ san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”—Mátíù 22:21.

“Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.

Àmọ́, Jésù ṣe ju pé kó kàn sọ̀rọ̀ téèyàn ò lè gbàgbé. Iṣẹ́ tó jẹ́ lágbára torí pé ó jẹ́ ká mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run, ó kọ́ni béèyàn ṣe lè fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe ohun rere, ó sì tún jẹ́ ká mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run ló máa fòpin sí ìyà tó ń jẹ ẹ̀dá èèyàn. Bá a ṣe ń ṣàgbéyẹ̀wò iṣẹ́ tí Jésù jẹ́ yìí ní àwọn ojú ìwé tó tẹ̀ lé e, a máa rí ìdí tí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn kò fi gbàgbé àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn èèyàn gbà pé Kápánáúmù ni ìlú ìbílẹ̀ Jésù, ní Gálílì.—Máàkù 2:1.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́