Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
September 15, 2010
Ẹ̀dà Tó Wà Fún Ìkẹ́kọ̀ọ́
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ TÁ A MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍ Ọ̀SẸ̀:
October 25-31, 2010
Máa Fi Taratara Wá Ìbùkún Jèhófà
OJÚ ÌWÉ 7
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 95, 38
November 1-7, 2010
Ìṣọ̀kan La Fi Ń Dá Ìsìn Tòótọ́ Mọ̀
OJÚ ÌWÉ 12
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 20, 121
November 8-14, 2010
Ìṣọ̀kan Àwa Kristẹni Ń Fi Ògo fún Ọlọ́run
OJÚ ÌWÉ 16
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 119, 73
November 15-21, 2010
OJÚ ÌWÉ 21
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 84, 25
November 22-28, 2010
OJÚ ÌWÉ 25
ÀWỌN ORIN TÁ A Ó KỌ: 120, 98
Ohun Táwọn Àpilẹ̀kọ Tá A Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Dá Lé
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 1 OJÚ ÌWÉ 7 sí 11
Àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run nílò ìbùkún rẹ̀ ká lè máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà òdodo rẹ̀. Kí lèyí máa béèrè pé ká máa ṣe? Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí ìṣòro èyíkéyìí tó bá dojú kọ wá?
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 2 àti 3 OJÚ ÌWÉ 12 sí 20
Àwọn àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká mọrírì bó ṣe dára tó àti bó ṣe dùn tó láti máa gbé pọ̀ ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn ará wa. A máa rí ìdí tó fi jẹ́ pé Jèhófà nìkan ló lè mú kí àwọn èèyàn láti orílẹ̀-èdè gbogbo wà ní ìṣọ̀kan. Lẹ́yìn náà, a máa ṣàgbéyẹ̀wò bí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe lè gbé ìṣọ̀kan ìjọ lárugẹ ká sì máa tipa bẹ́ẹ̀ fi ògo fún Ọlọ́run.
ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 4 àti 5 OJÚ ÌWÉ 21 sí 29
Àwọn àpilẹ̀kọ méjèèjì yìí máa jẹ́ ká túbọ̀ mọ̀ nípa Kristi, Ọba wa ọ̀run, ẹni tó ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Aṣáájú wa báyìí. Ó ń kíyè sí àwọn nǹkan tó ń lọ nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wà lórí ilẹ̀ ayé lónìí.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ:
Mo Sìn Lásìkò Ìmúgbòòrò Tó Bùáyà 3
Ìwàásù Àkànṣe Lórílẹ̀-Èdè Bulgaria Kẹ́sẹ Járí 30