ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w10 11/1 ojú ìwé 6
  • Máa Fi Ẹ̀mí Ìmoore Hàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Fi Ẹ̀mí Ìmoore Hàn
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Fi Ìmoore Hàn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Epo Rọ̀bì—Báwo La Ṣe Ń Rí I?
    Jí!—2003
  • Jèhófà Jẹ́ Ọlọ́run Tó Mọrírì Ìsapá Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Dúpẹ́ Oore?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
w10 11/1 ojú ìwé 6

Ọ̀nà Kẹta

Máa Fi Ẹ̀mí Ìmoore Hàn

KÍ NI BÍBÉLÌ FI KỌ́NI? “Ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ohun gbogbo, ẹ máa dúpẹ́.”—1 Tẹsalóníkà 5:18.

KÍ NI ÌṢÒRO NÁÀ? Àárín àwọn agbéraga àti aláìmoore là ń gbé, ìwà wọn sì lè ràn wá. (2 Tímótì 3:1, 2) Yàtọ̀ síyẹn, a lè máa rò pé ó pọn dandan ká fi kún àwọn nǹkan rẹpẹtẹ tá a ti ń ṣe tẹ́lẹ̀. Èyí á mú ká dẹni tí ìṣòro wọ̀ lọ́rùn tàbí ẹni tó ń lépa ìfẹ́ ti ara rẹ̀ débi tí a kò fi ní mọyì ohun tá a ní tàbí ká wá di ẹni tí kì í fi ẹ̀mí ìmoore hàn fún ohun táwọn ẹlòmíì ṣe fún wa.

KÍ LO LÈ ṢE? Wá àkókò láti ṣàṣàrò lórí àwọn ohun rere tí ò ń gbádùn nísinsìnyí. Lóòótọ́, ìṣòro lè dorí rẹ kodò, àmọ́, ṣàgbéyẹ̀wò àpẹẹrẹ Dáfídì Ọba. Nígbà míì, ó máa ń ní ìbànújẹ́ ọkàn, àdánwò á sì mú ọkàn rẹ̀ pòrúurùu. Láìka gbogbo ìyẹn sí, ó gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Mo ti ṣe àṣàrò lórí gbogbo ìgbòkègbodò rẹ; tinútinú ni mo ń fi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ṣe ìdàníyàn mi.” (Sáàmù 143:3-5) Láìfi gbogbo àdánwò yìí pè, Dáfídì moore, ó sì ní ìtẹ́lọ́rùn.

Ronú nípa ohun tí àwọn èèyàn ti ṣe láti ràn ẹ́ lọ́wọ́, kí o sì dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn. Jésù fi àpẹẹrẹ tó tayọ lélẹ̀ nínú ọ̀ràn yìí. Bí àpẹẹrẹ, Màríà ọ̀rẹ́ Jésù da òróró sí orí àti ẹsẹ̀ Jésù, àwọn kan béèrè pé: “Èé ṣe tí ìfiṣòfò òróró onílọ́fínńdà yìí fi ṣẹlẹ̀?”a Àwọn alárìíwísí yẹn rò pé ó yẹ kí wọ́n ta òróró náà kí wọ́n sì fún àwọn tálákà ní owó rẹ̀. Jésù fèsì pé: “Ẹ jọ̀wọ́ rẹ̀ jẹ́ẹ́. Èé ṣe tí ẹ fi ń gbìyànjú láti dà á láàmú?” Lẹ́yìn náà, ó fi kún un pé: “Ó ṣe ohun tí ó lè ṣe.” (Máàkù 14:3-8; Jòhánù 12:3) Kàkà kí Jésù máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan míì tó yẹ kí Màríà ṣe àmọ́ tí kò ṣe, ńṣe ni Jésù fi ìmọrírì hàn fún ohun tí Màríà ṣe.

Lẹ́yìn ìgbà tí àwọn kan bá pàdánù ọ̀kan lára ìdílé wọn, àwọn ọ̀rẹ́ wọn tàbí àwọn àǹfààní kan tí wọ́n ní, ni wọ́n tó máa ń mọyì wọn. O ò ní kó sínú irú ìṣòro yìí tó o bá ń ronú lórí àwọn ohun rere tó ò ń gbádùn nísinsìnyí! O ò ṣe máa ronú lórí àwọn nǹkan tó yẹ kó o tìtorí wọn dúpẹ́ tàbí kó o ṣe àkọsílẹ̀ àwọn nǹkan tó yẹ kó o tìtorí wọn dúpẹ́.

Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni “gbogbo ẹ̀bùn rere” ti wá, ó yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ nígbà tá a bá ń gbàdúrà. (Jákọ́bù 1:17) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ déédéé, a óò lẹ́mìí ìmoore, a ó sì ní ìtẹ́lọ́rùn.—Fílípì 4:6, 7.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, dída òróró sórí àlejò jẹ́ àmì pé èèyàn ní ẹ̀mí aájò àlejò, dída òróró sí ẹsẹ̀ sì jẹ́ àmì pé èèyàn ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Ǹjẹ́ o máa ń mọrírì ohun táwọn ẹlòmíì ṣe fún ẹ?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́