ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w11 8/1 ojú ìwé 27
  • Ǹjẹ́ Ọlọ́run Ní Ibì Kan Tó Ń Gbé?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Ọlọ́run Ní Ibì Kan Tó Ń Gbé?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Ibi Gbogbo Ni Ọlọ́run Wà?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ṣé Ibi Gbogbo Ni Ọlọ́run wà?
    Jí!—2005
  • Ǹjẹ́ Ibì Kan Wà Tí Ọlọ́run Ń Gbé?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ṣé Ibi Gbogbo Ni Ọlọ́run Wà?
    Jí!—2011
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
w11 8/1 ojú ìwé 27

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .

Ǹjẹ́ Ọlọ́run Ní Ibì Kan Tó Ń Gbé?

▪ Onírúurú ìsìn ló ń sọ pé ibi gbogbo ni Ọlọ́run wà. Bí àpẹẹrẹ, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, New Catholic Encyclopedia sọ pé, Ọlọ́run “máa ń wà ní ibi gbogbo, ó sì máa ń wà nínú ohun gbogbo.” Bákan náà, ọ̀gbẹ́ni John Wesley, tó jẹ́ olùdásílẹ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì Mẹ́tọ́díìsì, kọ ìwé kan tó pe àkòrí rẹ̀ ní, “On the Omnipresence of God,” nínú ìwé náà, ó sọ pé, “kò sí ibi náà tí Ọlọ́run kò sí, ì báà jẹ́ inú òfuurufú tàbí inú ìṣẹ̀dá èyíkéyìí.”

Kí ni Bíbélì kọ́ni? Ṣé Ọlọ́run wà níbi gbogbo, ìyẹn ní ọ̀run, ní ayé àti nínú èèyàn pàápàá?

Ohun tí Bíbélì sọ nípa Ọlọ́run ni pé, ó ní ibi pàtó kan tó ń gbé, ìyẹn ọ̀run. Àkọsílẹ̀ àdúrà kan tí Ọba Sólómọ́nì gbà sí Ọlọ́run wà nínú Bíbélì, ó ní: “Kí ìwọ alára fetí sílẹ̀ láti ọ̀run, ibi àfìdímúlẹ̀ tí o ń gbé.” (1 Àwọn Ọba 8:43) Nígbà tí Jésù Kristi ń kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bí wọ́n ṣe máa gbàdúrà, ó ní kí wọ́n máa gbàdúrà sí “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run.” (Mátíù 6:9) Lẹ́yìn tí Kristi jíǹde, Bíbélì sọ pé ó wọlé lọ “sí ọ̀run, nísinsìnyí láti fara hàn níwájú Ọlọ́run.”—Hébérù 9:24.

Àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ ká mọ̀ ní kedere pé, ọ̀run nìkan ni Jèhófà Ọlọ́run ń gbé kì í ṣe ibi gbogbo. “Àwọn ọ̀run” tí à ń sọ níbí yìí kì í ṣe àwọn ọ̀run tí a lè fojú rí. Àwọn ọ̀run tí a lè fojú rí yìí kò lè gba Ẹlẹ́dàá ayé òun ọ̀run. (1 Àwọn Ọba 8:27) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé “Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí.” (Jòhánù 4:24) Inú ọ̀run tí a kò lè fojú rí ni Ọlọ́run ń gbé.—1 Kọ́ríńtì 15:44.

Àmọ́ ohun tí Bíbélì sọ tó jọ pé Ọlọ́run wà ní ibi gbogbo ńkọ́? Bí àpẹẹrẹ, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Sáàmù 139:7-10, Dáfídì sọ nípa Ọlọ́run pé: “Ibo ni mo lè lọ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀mí rẹ, ibo sì ni mo lè fẹsẹ̀ fẹ lọ kúrò ní ojú rẹ? Bí mo bá gòkè re ọ̀run, ibẹ̀ ni ìwọ yóò wà; bí mo bá sì ga àga ìrọ̀gbọ̀kú mi ní Ṣìọ́ọ̀lù, wò ó! ìwọ yóò wà níbẹ̀. Bí mo bá mú ìyẹ́ apá tí ó jẹ́ ti ọ̀yẹ̀, kí n lè máa gbé nínú òkun jíjìnnàréré jù lọ, ibẹ̀, pẹ̀lú, ni ọwọ́ rẹ yóò ti ṣamọ̀nà mi.” Ṣé ohun táwọn ẹsẹ yìí ń sọ ni pé, Ọlọ́run ń gbé ní gbogbo ibi tí wọ́n sọ yẹn?

Ẹ kíyè sí ohun tí Dáfídì kọ́kọ́ béèrè pé: “Ibo ni mo lè lọ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀mí rẹ?”a Nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́, Ọlọ́run lè rí gbogbo nǹkan, ó sì lè lo agbára rẹ̀ níbikíbi, láìjẹ́ pé òun fúnra rẹ̀ lọ síbẹ̀ tàbí kí ó gbé ibẹ̀. Àpẹẹrẹ kan rèé tó fi hàn pé ó ṣeé ṣe: Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ó ti ṣeé ṣe fún àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì láti ṣàyẹ̀wò erùpẹ̀ pílánẹ́ẹ̀tì kan tó ń jẹ́ Mars, àìmọye mílíọ̀nù kìlómítà ni pílánẹ́ẹ̀tì yìí fi jìn sí ayé wa. Báwo ni wọ́n ṣe ṣe é? Kì í ṣe pé wọ́n lọ síbẹ̀ fúnra wọn, ohun tí wọ́n ṣe ni pé, wọ́n fi ẹ̀rọ kan ránṣẹ́ sí Mars, àwọn àwòrán àtàwọn ìsọfúnni míì tí ẹ̀rọ yìí fi ránṣẹ́ sí ayé ni wọ́n fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò.

Bákan náà, Jèhófà Ọlọ́run kò ní láti wà ní ibi gbogbo kó tó mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé àti lọ́run. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Kò sì sí ìṣẹ̀dá tí kò hàn kedere sí ojú rẹ̀.” (Hébérù 4:13) Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ̀mí mímọ́ tàbí ipá ìṣiṣẹ́ Jèhófà tó lágbára gan-an, lè dé ibikíbi, ó ń jẹ́ kí Ọlọ́run rí ohun gbogbo, ó sì ń jẹ́ kó ṣe ohun tó ní lọ́kàn láti ọ̀run tó jẹ́ ‘ibùgbé rẹ̀ mímọ́.’—Diutarónómì 26:15.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n túmọ̀ sí “ẹ̀mí” níbí yìí jẹ́ ipá ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run, ìyẹn agbára tí Ọlọ́run ń lò láti fi ṣe àwọn nǹkan tó fẹ́.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 27]

IAC/RGO/David Malin Images

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́