Bíbélì Máa Ń yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà
BÁWO ni ọmọbìnrin kan tí ìyà jẹ nígbà èwe rẹ̀ ṣe wá dẹni tí ayé rẹ̀ dára? Kí ló mú kí oníjàgídíjàgan kan tó ṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba di ajíhìnrere? Ka àpilẹ̀kọ yìí kó o lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí.
“Ohun tó jẹ mí lógún ni bí mo ṣe máa rí ìfọ̀kànbalẹ̀ àti àwọn tó máa fẹ́ràn mi.”—INNA LEZHNINA
ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1981
ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: RỌ́ṢÍÀ
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: ÌYÀ JẸ MÍ NÍGBÀ ÈWE MI
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Odi ni mí látìgbà tí wọ́n ti bí mi, odi náà sì làwọn òbí mi. Ìyà ò jẹ mí títí mo fi di ọmọ ọdún mẹ́fà. Àmọ́ lẹ́yìn ìgbà yẹn, àwọn obí mi kọ ara wọn sílẹ̀. Mo ṣì kéré nígbà yẹn o, ṣùgbọ́n mo mọ ohun tó túmọ̀ sí pé àwọn òbí kọ ara wọn sílẹ̀, ó sì dùn mí gan-an. Lẹ́yìn tí wọ́n kọra sílẹ̀, bàbá mi àti ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin dúró sí ìlú Troitsk, ìyá mi sì kó lọ sí ìlú Chelyabinsk ó sì mú mi dání. Nígbà tó yá, ó fẹ́ ọkọ míì. Àmọ́, ọ̀mùtí paraku lọkùnrin náà, ó sì máa ń na èmi àti màmá mi.
Lọ́dún 1993, ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin kú sómi, mo fẹ́ràn ẹ̀gbọ́n mi yìí gan-an. Ìbànújẹ́ ńlá ni ikú rẹ̀ jẹ́ fún ìdílé wa. Ni màmá mi bá bẹ̀rẹ̀ sí í mutí láti fi pàrònú rẹ́, lòun náà bá tún ń fìyà jẹ mí bí ọkọ rẹ̀ ṣe ń ṣe. Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í wá bí màá ṣe bọ́ nínú ìyà yìí nìyẹn. Ohun tó jẹ mí lógún ni bí mo ṣe máa rí ìfọ̀kànbalẹ̀ àti àwọn tó máa fẹ́ràn mi. Mo wá ń lọ láti ṣọ́ọ̀ṣì kan sí òmíràn bóyá máa lè rí ìtùnú àmọ́ mi ò rí ìtùnú kankan.
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá, ọmọbìnrin kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá a jọ wà ní kíláàsì máa ń sọ ìtàn inú Bíbélì fún mi. Mo máa ń gbádùn ìtàn tí Bíbélì sọ nípa àwọn èèyàn bíi Nóà àti Jóòbù tí wọ́n sin Ọlọ́run láìka gbogbo ìṣòro wọn sí. Láìpẹ́, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mo sì ń lọ sí ìpàdé wọn.
Ẹ̀kọ́ Bíbélì tí mo ń kọ́ jẹ́ kí n mọ ọ̀pọ̀ òtítọ́ tó wúni lórí. Inú mi dùn gan-an nígbà tí mo mọ̀ pé Ọlọ́run ní orúkọ. (Sáàmù 83:18) Ó tún jọ mí lójú gan-an pé Bíbélì sọ bí nǹkan ṣe máa rí ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ó sì ń rí bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. (2 Tímótì 3:1-5) Ohun ayọ̀ gbáà ló jẹ́ fún mi nígbà tí mo gbọ́ pé àwọn òkú yóò jíǹde. Ìyẹn ni pé màá tún pa dà rí ẹ̀gbọ́n mi tó ti kú! Inú mi á mà dùn o!—Jòhánù 5:28, 29.
Ṣùgbọ́n, kì í ṣe inú gbogbo èèyàn ló dùn sí ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó ń fún mi láyọ̀ yìí. Màmá mi àti ọkọ rẹ̀ kórìíra àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gidigidi. Wọ́n wá ń fúngun mọ́ mi pé kí n dáwọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi dúró. Àmọ́ mo fẹ́ràn ẹ̀kọ́ tí mo ń kọ́ gan-an, mi ò sì fẹ́ jáwọ́ nínú rẹ̀.
Àtakò tí ìdílé mi ń ṣe sí mi yìí le gan-an. Àjálù míì tún dé bá mi nígbà tí àbúrò mi ọkùnrin, tó ti bá mi lọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí, tún kú sómi. Àmọ́, ṣe ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dúró tì mí gbágbáágbá. Mo rí i pé ìfọ̀kànbalẹ̀ àti ìfẹ́ tí mo ti ń wá látìgbà èwe mi wà láàárín wọn. Èyí jẹ́ kí n mọ̀ pé àwọn gan-an ló ń ṣe ìsìn tòótọ́. Lọ́dún 1996, mo ṣe ìrìbọmi, mo sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Láti ọdún mẹ́fà sẹ́yìn báyìí ni èmi àti Dmitry, ọkọ mi àtàtà, ti fẹ́ ara wa. A sì jọ ń ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ìlú St. Petersburg. Nígbà tó sì yá, àwọn òbí mi kò bínú sí mi mọ́ nítorí ẹ̀sìn mi.
Mo mà dúpẹ́ o pé mo mọ Jèhófà! Sísìn tí mo ń sìn ín ti jẹ́ kí ayé mi dáa gan-an.
“Ọ̀pọ̀ ìbéèrè ń jà gùdù lọ́kàn mi.”—RAUDEL RODRÍGUEZ RODRÍGUEZ
ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1959
ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: CUBA
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: ỌLỌ̀TẸ̀ SÍ ÌJỌBA
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Ìlú Havana ní orílẹ̀-èdè Cuba, ni wọ́n bí mi sí, àdúgbò àwọn tálákà, tí wọ́n ti máa ń ja ìjà ìgboro gan-an, ni mo sì gbé dàgbà. Nígbà tí mo wá ń dàgbà, mo fẹ́ràn ìjàkadì kan tí wọ́n ń pè ní júdò àtàwọn ìdíje míì tó jẹ mọ́ ìjà.
Mo ń ṣe dáadáa nílé ìwé, nítorí náà àwọn òbí mi ní kí n lọ kàwé sí i ní yunifásítì. Nígbà tí mo wà níbẹ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé ó yẹ kí àtúnṣe bá ètò ìṣèlú orílẹ̀-èdè wa. Ni mo bá ya ọlọ̀tẹ̀. Èmi àti ọmọ kíláàsì mi kan wá lọ bá ọlọ́pàá kan jà ká lè gba ìbọn ọwọ́ rẹ̀. Nígbà ìjà náà, ọlọ́pàá yẹn forí ṣèṣe gan-an. Èyí mú kí wọ́n ju èmi àti ọmọ kíláàsì mi yẹn sẹ́wọ̀n, wọ́n sì dájọ́ ikú fún wa, pé kí wọ́n yìnbọn pa wá. Èmi ọmọ ogún [20] ọdún péré ló dẹni tó fẹ́ kú báyìí!
Bí mo ṣe dá wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n tí wọ́n há mi mọ́, mò ń ronú nípa bí mo ṣe máa ṣe nígbà tí wọ́n bá fẹ́ yìnbọn pa mí. Mi ò fẹ́ ṣe bí ẹni tó ń bẹ̀rù rárá. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ìbéèrè ń jà gùdù lọ́kàn mi. Mo ń rò ó pé: ‘Kí nìdí tí kò fi sí ìdájọ́ òdodo láyé yìí? Ṣé téèyàn bá ti kú láyé tá a wà yìí, gbogbo ẹ̀ ti parí náà nìyẹn?’
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, wọ́n yí ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wa pa dà sí ẹ̀wọ̀n ọgbọ̀n [30] ọdún. Àkókò yẹn ni mo pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tí wọ́n jù sẹ́wọ̀n nítorí ìgbàgbọ́ wọn. Bí àwọn Ẹlẹ́rìí yẹn ṣe jẹ́ onígboyà àti ẹlẹ́mìí àlàáfíà jọ mí lójú púpọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tọ́ bí wọ́n ṣe fi wọ́n sẹ́wọ̀n, síbẹ̀ wọn kò fi ṣèbínú tàbí kí wọ́n máa kanra.
Àwọn Ẹlẹ́rìí yẹn kọ́ mi pé ó nídìí tí Ọlọ́run fi dá àwa èèyàn. Wọ́n fi hàn mí nínú Bíbélì pé Ọlọ́run yóò sọ ayé yìí di Párádísè níbi tí kò ti ní sí ìwà ọ̀daràn àti ìwà ìrẹ́jẹ. Wọ́n tún kọ́ mi pé àwọn èèyàn rere nìkan ló máa wà nínú ayé, wọn yóò sì láǹfààní láti wà láàyè títí láé, tí gbogbo nǹkan yóò sì wà ní pípé.—Sáàmù 37:29.
Mo gbádùn àwọn ohun tí mò ń kọ́ lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí náà, àmọ́ ìwà mi ò bá tiwọn mu rárá. Mo rò pé mi ò lè ṣe kí n máà dá sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú tàbí kí n má gbẹ̀san ohun tí ẹlòmíì bá ṣe sí mi. Èyí mú kí n bẹ̀rẹ̀ sí í dá Bíbélì kà fúnra mi. Nígbà tí mo wá ka Bíbélì látòkè délẹ̀, mo rí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ló ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn Kristẹni ìjímìjí.
Ẹ̀kọ́ Bíbélì tí mo ń kọ́ jẹ́ kí n mọ̀ pé mo gbọ́dọ̀ ṣe àwọn àyípadà pàtàkì kan nígbèésí ayé mi. Bí àpẹẹrẹ, ó ti mọ́ mi lára láti máa sọ ìsọkúsọ, ó sì di dandan kí n jáwọ́ nínú rẹ̀. Mo sì tún ní láti jáwọ́ nínú sìgá mímu. Mo tún gbọ́dọ̀ yọwọ́ nínú ọ̀rọ̀ ìṣèlú. Àwọn ìyípadà yìí kò rọrùn rárá fún mi láti ṣe, àmọ́ Jèhófà ràn mí lọ́wọ́, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, mo kógo já.
Ọ̀kan lára ohun tó ṣòro jù fún mi láti borí ni bí mo ṣe máa ń tètè bínú. Àní títí di ìsinsìnyí, mo ṣì ń gbàdúrà kí n lè borí ìṣòro yìí pátápátá. Ara àwọn ẹsẹ Bíbélì tó ràn mí lọ́wọ́ gan-an ni Òwe 16:32, tó sọ pé: “Ẹni tí ó lọ́ra láti bínú sàn ju alágbára ńlá, ẹni tí ó sì ń ṣàkóso ẹ̀mí rẹ̀ sàn ju ẹni tí ó kó ìlú ńlá.”
Lọ́dún 1991, mo ṣe ìrìbọmi láti fi hàn pé mo ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Inú àgbá kan tí wọ́n pọn omi sí ni mo ti ṣèrìbọmi lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, wọ́n tú àwa kan sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, wọ́n sì kó wa lọ sí orílẹ̀-èdè Sípéènì torí pé àwọn mọ̀lẹ́bí wa wà níbẹ̀. Gbàrà tí mo dé orílẹ̀-èdè Sípéènì, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀ fi ọ̀yàyà gbà mí bíi pé a ti mọra láti ìgbà pípẹ́, wọ́n sì ràn mí lọ́wọ́ kí n lè dẹni tó ń gbé ìgbé ayé tó dára.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Ìgbé ayé aláyọ̀ ni mò ń gbé báyìí, èmi àti ìyàwó mi àti àwọn ọmọbìnrin wa méjèèjì sì jọ ń sin Ọlọ́run. Inú mi ń dùn bí mo ṣe ń lo ọ̀pọ̀ àkókò mi láti fi kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ Bíbélì. Nígbà míì, mo máa ń rántí ìgbà ọ̀dọ́ mi tí ikú rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lé mi lórí, màá sì dúpẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni mo ti jèrè láti ìgbà yẹn. Yàtọ̀ sí pé mo ṣì wà láàyè, mo tún ní ìrètí. Mo ń fojú sọ́nà fún Párádísè tí Ọlọ́run ṣèlérí, nígbà tí ìdájọ́ òdodo yóò gbilẹ̀, tí “ikú kì yóò sì sí mọ́.”—Ìṣípayá 21:3, 4.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 19]
“Inú mi dùn gan-an nígbà tí mo mọ̀ pé Ọlọ́run ní orúkọ”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Inú èmi àti ọkọ mi máa ń dùn láti fi àwọn fídíò tó wà lédè àwọn adití han àwọn odi