Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Kí Nìdí Tí Àwọn Kristẹni Fi Ń Ṣe Ìrìbọmi?
Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìbéèrè tó o ti lè máa béèrè, a sì tún sọ ibi tó o ti lè rí ìdáhùn wọn kà nínú Bíbélì rẹ. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti bá ẹ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìdáhùn náà.
1. Kí ni ìrìbọmi tí àwọn Kristẹni ń ṣe túmọ̀ sí?
Ìrìbọmi jẹ́ ọ̀nà kan téèyàn gbà ń sọ fún Ọlọ́run pé òun fẹ́ di ọ̀rẹ́ rẹ̀. Torí náà ìgbà tí Kristẹni kan bá dàgbà tó láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run tó sì yé e, tó sì wá di ọmọ ẹ̀yìn Jésù ló yẹ kó ṣe ìrìbọmi, kì í ṣe ìgbà tó bá wà ní ìkókó. (Ìṣe 8:12; 1 Pétérù 3:21) Ìgbà tí a bá kẹ́kọ̀ọ́, tá a mọ àwọn ohun tí Jésù pa láṣẹ pé ká máa ṣe tí a sì ń ṣe wọ́n la tó di ọmọ ẹ̀yìn Jésù.—Ka Mátíù 28:19, 20.
Nígbà ayé àwọn àpọ́sítélì Jésù, ọ̀pọ̀ èèyàn kò jáfara rárá láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run àti Jésù. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ọkùnrin kan kẹ́kọ̀ọ́ pé ikú Jésù ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn èèyàn láti rí ìgbàlà, kíá ló di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Lónìí náà, ọ̀pọ̀ èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ ló ń di ọmọlẹ́yìn Jésù.—Ka Ìṣe 8:26-31, 35-38.
2. Kí nìdí tí Jésù fi ṣe ìrìbọmi?
Nǹkan bí ọmọ ọgbọ̀n [30] ọdún ni Jésù jẹ́ nígbà tí Jòhánù Olùbatisí rì í bọ inú omi Odò Jọ́dánì. Ìrìbọmi tí Jésù ṣe yìí jẹ́ ẹ̀rí pé ó ti pinnu láti ṣe bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kí ó ṣe. (Hébérù 10:7) Lára rẹ̀ sì ni pé kó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ aráyé. Àmọ́ ṣá o, kí Jésù tó wá sí ayé rárá ló ti fẹ́ràn Jèhófà Baba rẹ̀ tó sì máa ń ṣe ìgbọràn sí i.—Ka Máàkù 1:9-11; Jòhánù 8:29; 17:5.
3. Kí nìdí tó fi yẹ kí Kristẹni ṣe ìrìbọmi?
Ipò tiwa yàtọ̀ sí ti Jésù torí pé wọ́n bí wa sínú ẹ̀ṣẹ̀ ni. Síbẹ̀, ikú tí Jésù kú mú kó ṣeé ṣe fún wa láti lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. (Róòmù 5:10, 12; 12:1, 2) Kódà, a lè di ọ̀kan lára àwọn tó wà nínú ìdílé Ọlọ́run. (2 Kọ́ríńtì 6:18) Báwo ni àǹfààní yẹn ṣe lè kàn wá? Ṣe ni a máa fúnra wa gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run, láti fi ya ara wa sí mímọ́ fún un, ìyẹn ni pé ká ṣèlérí fún un pé a óò máa fi gbogbo ọjọ́ ayé wa ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Lẹ́yìn tí a bá ti wá ya ara wa sí mímọ́ fún un, a óò wá ṣe ìrìbọmi láti jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ pé a ti ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run.—Ka Mátíù 16:24; 1 Pétérù 4:2.
4. Kí lèèyàn máa ṣe tó fi máa dẹni tó ṣe ìrìbọmi?
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń kọ́ àwọn èèyàn tó bá fẹ́ sún mọ́ Ọlọ́run lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tí o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí o sì ń lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni, wàá túbọ̀ fẹ́ràn Ọlọ́run, ìgbàgbọ́ rẹ yóò sì túbọ̀ lágbára sí i. Á sì tún jẹ́ kí ìwà àti ìṣe rẹ dára. Tó o bá dẹni tó ní ìfẹ́, ìgbàgbọ́ àti àwọn ìwà dáadáa míì, wàá lè mú ìlérí tí o ṣe fún Jèhófà pé wàá máa sìn ín títí ọjọ́ ayé rẹ, ṣẹ.—Ka Jòhánù 17:3; Hébérù 10:24, 25.
Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka orí 18 nínú ìwé yìí, Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣé e.