Kí Ló Yẹ Kí Àwọn Kristẹni Ṣe Lónìí?
ÀWỌN Kristẹni tòótọ́ lónìí kì í lọ́wọ́ nínú ìṣèlú. Kí nìdí? Torí pé àpẹẹrẹ Jésù ni wọ́n ń tẹ̀ lé. Jésù sọ nípa ara rẹ̀ pé: ‘Èmi kì í ṣe apá kan ayé.’ Ó sọ nípa àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ kì í ṣe apá kan ayé.” (Jòhánù 15:19; 17:14) Jẹ́ ká wo àwọn ìdí mélòó kan tí kò fi yẹ kí àwọn Kristẹni lọ́wọ́ sí ìṣèlú.
1. Ó ní ibi tí agbára èèyàn mọ. Bíbélì sọ pé àwa èèyàn kò lágbára láti ṣàkóso ara wa, bẹ́ẹ̀ náà ni a kò lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Wòlíì Jeremáyà kọ̀wé pé: “Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—Jeremáyà 10:23.
Bó ṣe jẹ́ pé Ọlọ́run kò dá àwa èèyàn pé ká máa dá fò bí ẹyẹ, bẹ́ẹ̀ náà ni kò dá wa pé ká máa dá ṣàkóso ara wa. Nígbà tí òpìtàn David Fromkin ń sọ̀rọ̀ nípa ibi tí agbára ìjọba èèyàn mọ, ó sọ pé: “Nítorí pé àwọn èèyàn ló ń ṣe ìjọba; wọ́n máa ń ṣe àṣìṣe, wọ́n sì lè jáni kulẹ̀. Agbára ń bẹ lọ́wọ́ wọn lóòótọ́, àmọ́ ó ní ibi tí agbára wọn mọ.” (The Question of Government) Abájọ nígbà náà tí Bíbélì fi kì wá nílọ̀ pé kí á má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé èèyàn!— Sáàmù 146:3.
2. Àwọn ẹ̀mí búburú ló ń darí ayé lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí. Nígbà tí Sátánì fi ìṣàkóso ayé lọ Jésù, Jésù kò bá a jiyàn pé kò láṣẹ láti fún òun ní gbogbo ìjọba ayé. Kódà, nígbà tó yá, Jésù pe Sátánì ní “olùṣàkóso ayé.” Ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pe Sátánì ní “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí.” (Jòhánù 14:30; 2 Kọ́ríńtì 4:4) Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni bíi tiẹ̀ pé: “Àwa ní gídígbò kan . . . lòdì sí àwọn olùṣàkóso ayé òkùnkùn yìí, lòdì sí àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú ní àwọn ibi ọ̀run.” (Éfésù 6:12) Àwọn tí aráyé kò ronú nípa wọn rárá, ìyẹn àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú gangan ni alákòóso ayé yìí. Ní báyìí tó o ti wá mọ̀, ojú wo ló yẹ kó o fi wo ọ̀rọ̀ ìṣèlú?
Ronú nípa ìfiwéra yìí: Bí ìgbì òkun tó lágbára ṣe máa ń gbé àwọn ọkọ̀ ojú omi kéékèèké síbí sọ́hùn-ún lórí omi, bẹ́ẹ̀ ni àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú tó lágbára yìí ṣe ń darí ètò ìṣèlú ayé yìí. Bó ṣe jẹ́ pé àwọn atukọ̀ inú àwọn ọkọ̀ ojú omi kéékèèké náà kò lè ṣe ohunkóhun sí ìgbì tó ń gbé wọn, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn olóṣèlú kò lè ṣe ohunkóhun láti dẹ́kun ipa tí àwọn ẹ̀mí burúkú alágbára náà ń ní lórí ayé. Àwọn ẹ̀mí èṣù yìí ti pinnu pé àwọn máa ba ayé àwọn èèyàn jẹ́ porogodo láìsí àtúnṣe, àwọn sì máa fa ‘ègbé fún ilẹ̀ ayé.’ (Ìṣípayá 12:12) Torí bẹ́ẹ̀, ẹnì kan tó lágbára ju Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ nìkan ló lè mú ojúlówó ìyípadà wá. Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni Ẹnì kan ṣoṣo tó lè ṣe bẹ́ẹ̀.—Sáàmù 83:18; Jeremáyà 10:7, 10.
3. Ìjọba Ọlọ́run nìkan làwọn Kristẹni fara mọ́. Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ mọ̀ pé tó bá tó àkókò tí Ọlọ́run ní lọ́kàn, ó máa gbé ìjọba kan kalẹ̀ ní ọ̀run, èyí tó máa ṣàkóso lé gbogbo ayé lórí. Ìjọba Ọlọ́run ni Bíbélì pe ìjọba yìí, ó sì jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù Kristi ni Ọlọ́run yàn gẹ́gẹ́ bí Ọba ìjọba náà. (Ìṣípayá 11:15) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé gbogbo èèyàn ni Ìjọba náà kàn, “ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run” ni Jésù fi ṣe kókó ẹ̀kọ́ tó kọ́ àwọn èèyàn. (Lúùkù 4:43) Ó tún kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà pé: “Kí ìjọba rẹ dé.” Kí nìdí? Ìdí ni pé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, ó dájú pé gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ní ọ̀run náà ni àwọn èèyàn á máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé.—Mátíù 6:9, 10.
Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn ìjọba èèyàn? Bíbélì dáhùn pé Ọlọ́run máa pa àwọn ìjọba “gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá” run. (Ìṣípayá 16:14; 19:19-21) Bí ẹnì kan bá gbà lóòótọ́ pé Ìjọba Ọlọ́run máa pa gbogbo ètò ìṣèlú tí àwọn èèyàn dá sílẹ̀ run, ó máa bọ́gbọ́n mu kí onítọ̀hún jáwọ́ nínú lílọ́wọ́ sí àwọn ètò ìṣèlú wọ̀nyẹn. Ó ṣe tán, tó bá ń gbìyànjú láti kọ́wọ́ ti ìjọba èèyàn, tó máa tó roko ìgbàgbé, ohun tí onítọ̀hún ń ṣe ní ti gidi ni pé, ó ń tako Ọlọ́run.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í dá sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú, ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé wọn kò nífẹ̀ẹ́ sí ohunkóhun tó lè mú ìdàgbàsókè wá fún àwọn ibi tí wọ́n ń gbé? Jẹ́ ká wo ìdáhùn sí ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 7]
Ìjọba Ọlọ́run ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbé lárugẹ, kì í ṣe àtúnṣe nípasẹ̀ ìṣèlú