ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w12 10/1 ojú ìwé 16-17
  • Ǹjẹ́ O Lè Wà Láàyè Títí Láé?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Lè Wà Láàyè Títí Láé?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwo Lo Ṣe Lè Wà Láàyè Títí Láé?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Jèhófà Fẹ́ Ká Wà Láàyè Títí Láé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Ìyè Àìnípẹ̀kun Ha Ṣeé Ṣe Lóòótọ́ Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ayé Tuntun Ọlọ́run, Ayé Àlàáfíà—Ìwọ Lè Wà Níbẹ̀
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
w12 10/1 ojú ìwé 16-17

Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Ǹjẹ́ O Lè Wà Láàyè Títí Láé?

Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìbéèrè tó o ti lè máa béèrè, a sì tún sọ ibi tó o ti lè rí ìdáhùn wọn kà nínú Bíbélì rẹ. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti bá ẹ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìdáhùn náà.

1. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ẹ̀mí àwa èèyàn kì í gùn tó bó ṣe yẹ?

Àwọn ìjàpá kan máa ń lò tó àádọ́jọ [150] ọdún láyé, àwọn igi kan sì máa ń lò tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] ọdún. Àmọ́ ní ti àwa èèyàn, ẹ̀mí wa kúrú gan-an. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwa la lè ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan alárinrin tí ìjàpá àti igi kò lè ṣe. Jèhófà Ọlọ́run dá àwa èèyàn lọ́nà tí a fi lè gbádùn orin, eré ìdárayá, oúnjẹ, ẹ̀kọ́ kíkọ́, rírin ìrìn àjò àti wíwà pẹ̀lú àwọn èèyàn. Ọlọ́run fi sí wa lọ́kàn pé ká fẹ́ láti wà láàyè títí láé.—Ka Oníwàásù 3:11.

2. Ṣé a lè wà láàyè títí láé lóòótọ́?

Títí láé ni Jèhófà yóò máa wà. Ọlọ́run kì í kú. Òun ni Orísun ìyè, torí náà ó lè mú ká wà láàyè títí láé. (Sáàmù 36:9; Hábákúkù 1:12) Yàtọ̀ síyẹn, Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa mú kí àwọn tó bá ṣègbọràn sí òun wà láàyè títí láé. Yóò mú ohun tí ń sọni di arúgbó kúrò lára wọn.—Ka Jóòbù 33:24, 25; Aísáyà 25:8; 33:24.

Àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe fi hàn pé a lè gbẹ́kẹ̀ lé ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé òun máa jẹ́ ká wà láàyè títí láé, tí a ó sì ní ìlera pípé. Jésù wo oríṣiríṣi àìsàn sàn, ó tún jí àwọn òkú dìde pàápàá.—Ka Lúùkù 7:11-15, 18, 19, 22.

3. Ìgbà wo ni àwa èèyàn yóò máa wà láàyè títí láé?

Kì í ṣe inú ayé tó kún fún ìnira àti ìwà ipá yìí ni Ọlọ́run ti fẹ́ kí a wà láàyè títí láé, inú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé ni. Ó fẹ́ ká wà ní àlàáfíà kí ọkàn wa sì balẹ̀. (Sáàmù 37:9, 29; Aísáyà 65:21, 22) Nígbà tí Ọlọ́run bá sọ ayé yìí di Párádísè, yóò jí ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn tó ti kú dìde. Àwọn tó bá ń sin Ọlọ́run tí wọ́n sì ń ṣègbọràn sí i lára àwọn tó bá jíǹde, yóò wà láàyè títí láé.—Ka Lúùkù 23:42, 43; Jòhánù 5:28, 29.

4. Kí la lè ṣe tí a ó fi ní ìyè àìnípẹ̀kun?

Ọlọ́run nìkan ló lè mú ká wà láàyè títí láé. Nítorí náà, ó máa dára pé ká mọ Ọlọ́run ká sì túbọ̀ sún mọ́ ọn. Bíbélì fi kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run wé oúnjẹ jíjẹ. (Mátíù 4:4) Oúnjẹ jíjẹ máa ń gbádùn mọ́ni, àmọ́ èèyàn ní láti sapá kó tó lè rí oúnjẹ náà kó sì sè é. Lọ́nà kan náà, kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run gba ìsapá. Àmọ́ kí ló tún dára bíi kéèyàn sún mọ́ Ọlọ́run kó sì ní ìyè àìnípẹ̀kun?—Ka Lúùkù 13:23, 24; Jòhánù 6:27; 17:3.

Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka orí 3 nínú ìwé yìí Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Gbogbo ohun tó bá gbà ló yẹ ká ṣe ká lè sún mọ́ Ọlọ́run

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́