ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w12 12/1 ojú ìwé 21
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Iyọ̀—Ohun Èlò Ṣíṣeyebíye
    Jí!—2002
  • Ẹ Jẹ́ Ká Gbọ́ Ìdáhùn Jésù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
w12 12/1 ojú ìwé 21

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ṣé Jésù tọ̀nà nígbà tó sọ pé iyọ̀ máa ń pàdánù adùn rẹ̀?

Nígbà tí Jésù ń wàásù lórí òkè, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ni iyọ̀ ilẹ̀ ayé; ṣùgbọ́n bí iyọ̀ bá pàdánù okun rẹ̀, báwo ni a ó ṣe mú adùn-iyọ̀ rẹ̀ padà bọ̀ sípò? Kò ṣeé lò fún ohunkóhun mọ́, bí kò ṣe kí a dà á sóde, kí àwọn ènìyàn tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀.” (Mátíù 5:13) Iyọ̀ máa ń dáàbò bo nǹkan ni, kì í jẹ́ kó tètè bà jẹ́. Torí náà, ohun tí àkàwé tí Jésù ṣe yìí túmọ̀ sí ni pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lè ṣe ohun tó máa dáàbò bo àjọṣe àwọn èèyàn àti Ọlọ́run àti ohun tí yóò gbà wọ́n lọ́wọ́ ìwà ìbàjẹ́. Ohun tó sì yẹ kí wọ́n máa ṣe nìyẹn.

Ṣùgbọ́n ní ti ọ̀rọ̀ Jésù pé iyọ̀ lè pàdánù adùn rẹ̀, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan sọ pé: “Àwọn èròjà inú ilẹ̀ míì sábà máa ń wà nínú iyọ̀ tí wọ́n máa ń rí ní àgbègbè Òkun Òkú; tí nǹkan olómi bá wá dà sí iyọ̀ náà, iyọ̀ gidi ibẹ̀ lè yòrò kúrò, kó wá ṣẹ́ ku àwọn èròjà yòókù tí kò ní adùn iyọ̀.” (The International Standard Bible Encyclopedia) Ìyẹn wá jẹ́ ká rí ìdí tí Jésù fi lè sọ pé àwọn èròjà tó ṣẹ́ kù yẹn “kò ṣeé lò fún ohunkóhun mọ́, bí kò ṣe kí a dà á sóde.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ yìí wá sọ pé: “Lóòótọ́, iyọ̀ tí wọ́n máa ń rí ní Òkun Òkú kò dáa tó ọ̀pọ̀ jù lọ iyọ̀ tó wà láyé torí àwọn èròjà inú ilẹ̀ míì tó máa ń wà nínú rẹ̀, síbẹ̀ òun ni iyọ̀ tó wọ́pọ̀ jù ní ilẹ̀ Palẹ́sìnì torí pé ó rọrùn láti rí (nítorí wọ́n kàn lè kó o létí òkun yẹn).”

Báwo ni ẹyọ owó dírákímà tí Jésù sọ pé ó sọ nù nínú àkàwé rẹ̀ ṣe ṣeyebíye tó lójú àwọn olùgbọ́ rẹ̀?

Jésù sọ àkàwé obìnrin kan tí ọ̀kan nínú owó dírákímà mẹ́wàá tó ní sọ nù. Ó ní obìnrin náà tan fìtílà, ó sì gbá ilé rẹ̀ fínnífínní títí tó fi rí owó náà. (Lúùkù 15:8-10) Nígbà ayé Jésù, dírákímà kan tó owó iṣẹ́ odindi ọjọ́ kan. Torí náà owó tí Jésù sọ pé ó sọ nù nínú àkàwé yẹn kì í ṣe owó kékeré o. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ìdí míì wà tí ohun tí Jésù sọ pé obìnrin yẹn ṣe fi lè ṣẹlẹ̀ lóòótọ́.

Àwọn ìwé ìwádìí kan sọ pé àwọn obìnrin sábà máa ń fi ẹyọ owó ṣe ohun ọ̀ṣọ́. Ó lè jẹ́ pé irú ohun ọ̀ṣọ́ iyebíye bẹ́ẹ̀ tí obìnrin kan jogún tàbí kó jẹ́ ara owó ìdána obìnrin náà ni Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Yálà ìyẹn ni o, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ìdí pàtàkì wà tó fi jẹ́ pé bí ọ̀kan lára ẹyọ owó mẹ́wàá obìnrin náà ṣe sọ nù, ó máa ká a lára débi pé yóò sa gbogbo ipá rẹ̀ láti wá a rí.

Bákan náà, nígbà ayé Jésù, ṣe ni àwọn mẹ̀kúnnù sábà máa ń kọ́ ilé wọn lọ́nà tí ìmọ́lẹ̀ ò fi ní máa wọlé púpọ̀, kí ooru má bàa máa mú níbẹ̀. Ìwọ̀nba fèrèsé ni wọ́n máa ń ní, òmíràn sì lè má tiẹ̀ ní rárá. Wọ́n sì sábà máa ń da pòròpórò tàbí koríko gbígbẹ sorí ilẹ̀ inú ilé. Tí ẹyọ owó bá wá já bọ́ sílẹ̀ ní irú ibẹ̀, ó máa ṣòro láti wá a rí. Ìyẹn ni ẹnì kan tó máa ń ṣàlàyé ọ̀rọ̀ inú Bíbélì fi sọ pé: “Torí náà, tí nǹkan kékeré kan, bí ẹyọ owó, bá sọ nù ní irú ibẹ̀, ohun tó jọ pé wọ́n máa ṣe náà ni pé wọ́n á tan fìtílà, wọ́n á sì gbá ilé náà kí wọ́n lè rí i.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́