KÓKÓ Ọ̀RỌ̀ | ÀWỌN IRỌ́ TÍ KÒ JẸ́ KÁWỌN ÈÈYÀN NÍFẸ̀Ẹ́ ỌLỌ́RUN
Kí Nìdí Táwọn Kan Ò Fi Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run?
“‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.’ Èyí ni àṣẹ títóbi jù lọ àti èkíní.”—Jésù Kristi ló sọ ọ̀rọ̀ yìí ní 33 Sànmánì Kristẹni.a
Kò rọrùn fún àwọn kan láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run torí pé lójú tiwọn àdììtú ni Ọlọ́run jẹ́. Wọ́n gbà pé ó jìnnà sí àwa ẹ̀dá àti pé ìkà ni. Ohun tí àwọn míì sọ rèé:
“Mo gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn mí lọ́wọ́, àmọ́ ó dà bíi pé ó jìnnà sí mi, ó ń ṣe mí bíi pé kò lè gbọ́ àdúrà mi. Lójú tèmi, Ọlọ́run ò mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára wa rárá.”—Marco ọmọ ilẹ̀ Ítálì.
“Ó wù mí gan-an kí n sin Ọlọ́run, àmọ́ ó dà bíi pé ó jìnnà sí mi. Mo rò pé ìkà kan tó kàn ń fojú wa gbolẹ̀ lásán ni. Mi ò gbà pé ó láàánú rárá.”—Rosa ọmọ ilẹ̀ Guatemala.
“Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, mo rò pé àṣìṣe wa nìkan ni Ọlọ́run máa ń wá, á sì máa ṣọ́ wa títí tá a máa fi ṣẹ̀ kó lè fìyà jẹ wá. Nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í wo Ọlọ́run bíi ẹni tó kàn ta kété sí wa. Lójú mi, ó jọ pé Ọlọ́run dà bí olórí ìjọba tó kàn ń ṣàkóso àwọn èèyàn tó wà lábẹ́ rẹ̀, àmọ́ tí kò bìkítà rárá nípa wọn.”—Raymonde ọmọ ilẹ̀ Kánádà.
Kí ni èrò rẹ? Ṣé ó yẹ ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run? Láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn ni àwọn Kristẹni ti ń béèrè ìbéèrè yìí. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn Oníṣọ́ọ̀ṣì kì í gbàdúrà sí Ọlọ́run Olódùmarè. Ìdí ni pé wọ́n kà á sí ẹni tó ń dẹ́rù bani tí kò ṣeé sún mọ́. Òpìtàn kan tó ń jẹ́ Will Durant tiẹ̀ sọ pé: “Báwo ni ẹlẹ́ṣẹ̀ lásánlàsàn ṣe lè gbójú gbóyà gbàdúrà sí Ọlọ́run tó ń dẹ́rù bani tí ó sì jìnnà réré sí àwa èèyàn?”
Kí ló fà á tí àwọn kan fi ka Ọlọ́run sí “ẹni tó ń dẹ́rù bani tó sì jìnnà réré sí wa”? Kí ni Bíbélì fi kọ́ni gan-an nípa Ọlọ́run? Tó o bá mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run, báwo ni ìyẹn ṣe lè mú kó o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀?