BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ
Tara Mi Nìkan Ni Mo Mọ̀
ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1951
ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: JÁMÁNÌ
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: AGBÉRAGA ÀTI AṢETINÚ ẸNI
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ:
Ìlú Leipzig tó wà ní Ìlà Oòrùn Jámánì ni wọ́n bí mi sí. Ìlú yìí ò jìnnà sí ibodè orílẹ̀-èdè Czech àti Poland. Ìgbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́fà, a kó lọ sí òkè òkun nítorí iṣẹ́ bàbá mi. Orílẹ̀-èdè Brazil la kọ́kọ́ lọ, lẹ́yìn náà a kọjá sí orílẹ̀-èdè Ecuador.
Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlá, àwọn òbí mi mú mi pa dà sí orílẹ̀-èdè Jámánì, wọ́n sì fi mí sí ilé ìwé kan níbẹ̀. Èmi nìkan ni mò ń bójú tó ara mi torí pé apá Gúúsù ilẹ̀ Amẹ́ríkà làwọn òbí mi wà, ọ̀nà wọn sì jìn sí mi. Torí náà, ohun tó bá ti wù mí ni mò ń ṣe láì bìkítà nípa bó ṣe rí lára ẹlòmíì.
Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17], àwọn òbí mi kó pa dà sí orílẹ̀-èdè Jámánì. Àmọ́ a kàn jọ ń gbélé lásán ni, nǹkan ò lọ déédéé láàárín wa. Ńṣe ni kálukú ń ṣe tiẹ̀. Lẹ́yìn ọdún kan tí mo rí i pé ọ̀rọ̀ wa ò wọ̀, mo kó jáde nilé. Ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] ni mí nígbà yẹn.
Gbogbo nǹkan tojú sú mi, mi ò sì mọ ohun tí màá fi ayé mi ṣe. Nígbà tí mo wo onírúurú nǹkan táwọn èèyàn ń ṣe, mo pinnu pé ohun tó dáa jù ni kí n máa ṣèwádìí kiri, kí n sì mọ nǹkan tó pọ̀ nípa ilẹ̀ ayé wa tó rí rèǹtè-rente yìí, kó tó di pé àwọn èèyàn ba gbogbo rẹ̀ jẹ́.
Mo ra alùpùpù kan, mo gbéra kúrò lórílẹ̀-èdè Jámánì, mo sì kọrí sí ilẹ̀ Áfíríkà. Àmọ́ kò pẹ́ tí mo tún fi pa dà sí ilẹ̀ Yúróòpù kí n lè tún alùpùpù mi ṣe. Lọ́jọ́ kan, mo lọ sí etíkun kan lórílẹ̀-èdè Potogí, ohun tí mo rí níbẹ̀ mú kí n fẹ́ràn ọkọ̀ ojú omi. Torí náà, mo pa alùpùpù tì, mo sì kò mọ́ ìrìn àjò ojú omi.
Nígbà tó ṣe, mo rí àwọn ọ̀dọ́ kan tó fẹ́ wọ ọkọ̀ ojú omi la òkun Àtìláńtíìkì já, lèmi náà bá dara pọ̀ mọ́ wọn. Ibẹ̀ ni mo ti pàdé ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Laurie, tí mo pa dà fi ṣaya. A kọ́kọ́ lọ sí àwọn erékùṣù Caribbean bí orílẹ̀-èdè Puerto Rico, àmọ́ a kò pẹ́ níbẹ̀ tá a fi pa dà sí ilẹ̀ Yúróòpù. Èmi àti Laurie wá dábàá pé ká kúkú ra ọkọ̀ ojú omi tiwa, ká sì ṣe ilé kékeré sínú rẹ̀ tá a lè máa gbé. Ìyẹn là ń ṣètò lọ́wọ́ tí ìjọba ilẹ̀ Jámánì fi pè mí wọṣẹ́ ológun, bí a ṣe dáwọ́ iṣẹ́ ọkọ̀ ojú omi náà dúró nìyẹn lẹ́yìn oṣù mẹ́ta.
Ọdún kan àti oṣù mẹ́ta gbáko ni mo lò nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun ojú omi ti ilẹ̀ Jámánì. Láàárín àsìkò yẹn ni èmi àti Laurie ṣègbéyàwó, a sì pinnu pé tí mo bá ti parí iṣẹ́ ológun, àá máa bá ìrìn àjò wa nìṣó. Kí n tó woṣẹ́ ológun la ti ra ọkọ̀ ojú omi kékeré kan. Bí mo ṣe ń bá iṣẹ́ náà lọ, a rọra ń ṣiṣẹ́ lára ọkọ̀ wa títí tá a fi ṣe ilé kékeré kan sínú rẹ̀ tá a lè máa gbé. A pinnu láti fi ọkọ̀ ojú omi náà ṣe ilé wa, òun sì lá fẹ́ máa gbé kiri lọ wo àwọn ohun mèremère tó wà láyé yìí. Nígbà tí mo parí iṣẹ́ ológun, mò ń bá iṣẹ́ lọ lára ọkọ̀ ojú omi náà. Àmọ́ ká tó parí ọkọ̀ yẹn, a pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ:
Nígbà tí mo kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mi ò rí ohun kan tó dà bí alárà tó yẹ kí n yí pa dà nínú ìwà mi. Èmi àti obìnrin tá a jọ ń gbé ti ṣèyàwó, mi ò sì mu sìgá mọ́. (Éfésù 5:5) Mo tún ronú pé ohun tó nítumọ̀ la dáwọ́ lé bá a ṣe ń rìnrìn àjò kiri láti wo àwọn ohun mèremère tí Ọlọ́run dá.
Ṣùgbọ́n ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan ló yẹ kí n yí pa dà nínú ìwà àti ìṣe mi. Mo ti máa ń gbéra ga jù, tinú mi ni mo sì máa ń ṣe. Mo máa ń fọ́nnu nípa àwọn àṣeyọrí mi àtàwọn nǹkan míì tí mo ti gbéṣe. Lẹ́nu kan, tara mi nìkan ni mo mọ̀.
Lọ́jọ́ kan, mo kà nípa Ìwàásù Jésù Lórí Òkè. (Mátíù, orí 5 sí 7) Ohun tí Jésù sọ nípa bí èèyàn ṣe lè láyọ̀ kọ́kọ́ rú mi lójú. Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ pé aláyọ̀ ni àwọn tí ebi ń pa, tí òùngbẹ sì ń gbẹ. (Mátíù 5:6) Ọ̀rọ̀ yẹn ò yé mi, báwo ni ẹni tí ebi ń pa, tí òùngbẹ sì ń gbé ṣe lè láyọ̀. Ṣùgbọ́n, bí mo ṣe ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi lọ, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lóye pé gbogbo èèyàn ló wù láti sún mọ́ Ọlọ́run, àmọ́ a gbọ́dọ̀ gbà pé lóòótọ́ la nílò Ọlọ́run ká to lè sún mọ́ ọn. Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.”—Mátíù 5:3.
Orílẹ̀-èdè Jámánì lá ti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, lẹ́yìn àkókò díẹ̀, a lọ sí orílẹ̀-èdè Faransé àti Ítálì. Àmọ́ kò síbi tá a dé, tí a kò rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan tó wà láàárín wọn jọ mí lójú gan-an. Mo wá rí i pé bí ọmọ ìyá ni gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí sí ara wọn ní ibikíbi tí wọ́n bá wà kárí ayé. (Jòhánù 13:34, 35) Nígbà tó yá, èmi àti Laurie ìyàwó mi ṣèrìbọmi, àwa náà sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Lẹ́yìn ti mo ṣe ìrìbọmi, mó tún ìwà mi ṣe gan-an. Nígbà tó yá, èmi àti Laurie wa ọkọ̀ ojú omi wa gba etíkun ilẹ̀ Áfíríkà kọjá, a sì la àárín òkun Àtìláńtíìkì pa dà sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Nígbà tá a wà lórí òkun, èmi àti ìyàwó mi nìkan nínú ọkọ̀ ojú omi kékeré láàárín agbami ńlá tó yí wa ká, mo wá rí i bá a ṣe kéré jọjọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Olódùmarè ọba ńlá tó dá ohun gbogbo. Kò kúkú sí iṣẹ́ tí mò ń ṣe láàárín alagbalúgbú omi òkun náà, torí náà, mo fi gbogbo àkókò yẹn ka Bíbélì. Ìtàn ìgbésí ayé Jésù ló wú mi lórí jù lọ nínú Bíbélì. Jésù kì í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀, òye àti agbára rẹ̀ sì ga fíìfíì ju tàwa èèyàn lọ. Síbẹ̀, kì í gbéra ga tàbí kó máa ṣe fọ́ńté kiri. Kì í ṣe tara ẹ̀ nìkan ló máa ń wá bí kò ṣe ohun tí bàbá rẹ̀ ọ̀run fẹ́.
Mo rí i pé ó yẹ kí èmi náà gbájú mọ́ ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run ju ohunkóhun míì lọ
Bí mo ṣe ń ronú lórí ìgbésí ayé Jésù, mo rí i pé ó yẹ kí èmi náà gbájú mọ́ ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run ju ohunkóhun míì lọ. (Mátíù 6:33) Nígbà tí èmi àti ìyàwó mi dé orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, a pinnu láti sinmi ìrìn àjò káàkiri ká sì gbájú mọ́ ìjọsìn wa.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ:
Tẹ́lẹ̀, tinú mi nìkan ni mo máa ń ṣe, torí náà, ọkàn mi kì í balẹ̀ lórí àwọn ìpinnu tí mo bá ṣe. Àmọ́ ní báyìí, ọgbọ́n Ọlọ́run tó ju gbogbo ọgbọ́n lọ ni mo máa ń gbára lé kí n tó ṣèpinnu. (Aísáyà 48:17, 18) Bákan náà, bí mo ṣe ń sin Ọlọ́run, tí mo sì tún ń kọ́ àwọn míì nípa rẹ̀ ti mú kí n fi ìgbésí ayé mi ṣe ohun tó dára.
Àwọn ìlànà Bíbélì tí èmi àti ìyàwó mi ń fi sílò ti mú kí ìgbéyàwó wa ládùn, kó sì lóyin. Ọlọ́run tún fi àrídunnú ọmọbìnrin kan ta wá lọ́rẹ, inú wa sì dùn pé òun náà ń sin Jèhófà.
Òótọ́ ni pé nǹkan ò rọrùn fún wa, síbẹ̀ a ti pinnu pé bí iná ń jó, bí ìjì ń jà, Jèhófà la máa dúró tì, a ò sì ní fi í sílẹ̀ láé.—Òwe 3:5, 6.