KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ṢÉ SÁTÁNÌ WÀ LÓÒÓTỌ́?
Ṣé Sátánì Wà Lóòótọ́?
Ère kan ní ìlú Madrid lórílẹ̀-èdè Sípéènì ń ṣàpẹẹrẹ Sátánì gẹ́gẹ́ bí áńgẹ́lì burúkú tó ti tẹ́
“Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, bí mo bá ṣe ìjàngbọ̀n, màmá mi á sọ fún mi pé, ‘Èṣù ń bọ̀ wá mú ẹ o!’ Èmi náà á dáhùn pé, ‘Ẹ jẹ́ kó máa bọ̀!’ Ọlọ́run ni mo mọ̀, mi o mọ Sátánì.”—ROGELIO, EL SALVADOR.
Ṣé ìwọ náà gba ohun tí Rogelio sọ gbọ́? Èwo nínú àwọn ọ̀rọ̀ yìí lo gbà pé ó jóòótọ́?
tó ń ṣàpẹẹrẹ nǹkan búburú ni Sátánì, kì í ṣe ẹni gidi.
Sátánì wà, àmọ́ kò rí tiwa rò.
Ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára ni Sátánì, òun ló ń rúná sí ohun tó ń lọ láyé.
Èrò mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí wọ́pọ̀ láàárín ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn lónìí. Àmọ́, ṣé ó pọn dandan ká mọ òótọ́ nípa Sátánì? Bẹ́ẹ̀ nì, torí pé tí Sátánì kì í bá ṣe ẹni gidi, a jẹ́ pé àwọn tó gbà pé Sátánì wà ti ṣìnà. Bákan náà, tó bá jẹ́ pé Sátánì wà, àmọ́ tí kò rí tiwa rò, a jẹ́ pé ńṣe ni ọ̀pọ̀ kàn ń bẹ̀rù rẹ̀ láìnídìí. Tó bá sì jẹ́ pé lóòótọ́ ni Sátánì máa ń fọgbọ́n àrékérekè tanni jẹ́, a jẹ́ pé ó burú ju ohun tí ọ̀pọ̀ rò lọ.
Ẹ jẹ́ ká wo bí Ìwé Mímọ́ ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè yìí: Ta ni Sátánì? Ṣé ẹni gidi ni àbí àmì tó ń ṣàpẹẹrẹ nǹkan búburú? Tí Sátánì bá jẹ́ ẹni gidi, ṣé ó lè pa wá lára? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, báwo la ṣe lè dáàbò bò ara wa?