ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w15 1/1 ojú ìwé 13
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kristi Ṣèdájọ́ Àgùntàn àti Ewúrẹ́
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Ọjọ́ Ọ̀la Wo Ni Ó Wà Fún Àwọn Àgùntàn àti Ewúrẹ́?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Máa Fi Ìdúróṣinṣin Ti Àwọn Arákùnrin Kristi Lẹ́yìn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Bí Ìgbésí Ayé Ṣe Rí Lákòókò Tí Wọ́n Ń Kọ Bíbélì—Olùṣọ́ Àgùntàn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
w15 1/1 ojú ìwé 13

ǸJẸ́ O MỌ̀?

Àwọn wo ni “ìwẹ̀fà” tí Bíbélì mẹ́nu kàn?

Àwòrán ìwẹ̀fà ará Asíríà kan lára ògiri

Àwòrán ìwẹ̀fà ará Asíríà kan lára ògiri

Nígbà míì, wọ́n máa ń fi orúkọ yìí pe àwọn ọkùnrin tí wọ́n tẹ̀ lọ́dàá. Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn ọkùnrin tí wọ́n bá fẹ́ fìyà ẹ̀ṣẹ̀ jẹ tàbí tí wọ́n mú lẹ́rú ni wọ́n sábà máa ń tẹ̀ lọ́dàá. Àwọn ọkùnrin tí wọ́n ti tẹ̀ lọ́dàá tí wọ́n sì fọkàn tán ló máa ń bójú tó ilé àwọn obìnrin nínú ààfin ọba. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìwẹ̀fà náà Hégáì àti Ṣááṣígásì ló ń ṣọ́ àwọn ìyàwó àtàwọn ọmọge Ọba Ahasuwérúsì tó ṣeé ṣe kó jẹ́ Sásítà Kìíní ti ilẹ̀ Páṣíà.—Ẹ́sítérì 2:3, 14.

Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo àwọn tí Bíbélì pè ní ìwẹ̀fà ni wọ́n tẹ̀ lọ́dàá. Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé wọ́n máa ń lo ọ̀rọ̀ yìí fún àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní ààfin ọba. Irú àwọn tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìwẹ̀fà tí wọn kò tẹ̀ lọ́dàá ni Ebedi-mélékì tó jẹ́ ọ̀rẹ́ Jeremáyà àti ọkùnrin ará Etiópíà tí ajíhìnrere náà Fílípì wàásù fún. Ó dájú pé onípò àṣẹ nínú ààfin ni Ebedi-mélékì torí pé ó láǹfààní láti máa bá Ọba Sedekáyà sọ̀rọ̀. (Jeremáyà 38:7, 8) Bákan náà, Bíbélì sọ pé ọkùnrin ará Etiópíà náà jẹ́ akápò ọba tó “lọ jọ́sìn ní Jerúsálẹ́mù.”—Ìṣe 8:27.

Kí nìdí tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn fi máa ń ya àgùntàn sọ́tọ̀ lára àwọn ewúrẹ́ láyé àtijọ́?

Olùṣọ́ àgùntàn kan pẹ̀lú ọ̀wọ́ àwọn àgùntàn rẹ̀

Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa ìdájọ́ tó ń bọ̀, ó ní: ‘Nígbà tí Ọmọ ènìyàn bá dé nínú ògo rẹ̀, yóò ya àwọn ènìyàn sọ́tọ̀ ọ̀kan kúrò lára èkejì, gan-⁠an gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn kan tí ń ya àwọn àgùntàn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ewúrẹ́.’ (Mátíù 25:​31, 32) Kí nìdí táwọn olùṣọ́ àgùntàn fi máa ń ya àwọn ẹran wọ̀nyí sọ́tọ̀ọ̀tọ̀?

Wọ́n sábà máa ń da àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ pọ̀ nígbà tí wọ́n bá ń jẹko láàárọ̀. Bó bá sì di alẹ́, wọ́n á kó wọn sínú gàá kí wọ́n lè dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ òtútù tàbí àwọn ẹranko ẹhànnà àtàwọn olè. (Jẹ́nẹ́sísì 30:​32, 33; 31:​38-​40) Àmọ́, torí pé àwọn àgùntàn kò lágbaja, pàápàá àwọn abo àti ọ̀dọ́ àgùntàn, yàrá ọ̀tọ̀ ni wọ́n máa ń kó wọn sí kí àwọn ewúrẹ́ tó máa ń ṣe gàràgàrà má bàa ṣe wọ́n léṣe. Ìwé náà, All Things in the Bible sọ pé àwọn olùṣọ́ àgùntàn tún máa ń ya àgùntàn àti ewúrẹ́ sọ́tọ̀ nígbà “tí wọ́n bá ń bímọ, tí wọ́n bá ń fún wàrà wọn tàbí tí wọ́n bá ń rẹ́ irun wọn.” Jésù lo àpèjúwe tó máa tètè yé àwọn olùgbọ́ rẹ̀ torí pé àwọn darandaran pọ̀ ní gbogbo agbègbè Ísírẹ́lì nígbà yẹn lọ́hùn-⁠ún.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́