Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
January 2016
© 2016 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
Ọ̀SẸ̀ FEBRUARY 29, 2016–MARCH 6, 2016
3 “Ẹ Jẹ́ Kí Ìfẹ́ Ará Tí Ẹ Ní Máa Bá A Lọ”!
Kí ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wa ti ọdún 2016? Kí ló yẹ kó máa wá sí wa lọ́kàn ní gbogbo ìgbà tá a bá ń rí i jálẹ̀ ọdún yìí? Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká rí bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wa ti ọdún 2016 ṣe máa ṣe wá láǹfààní.
Ọ̀SẸ̀ MARCH 7-13, 2016
9 Jẹ́ Kí ‘Ẹ̀bùn Ọ̀fẹ́ Aláìṣeé-Ṣàpèjúwe’ Ti Ọlọ́run Mú Ẹ Lọ́ranyàn
Jèhófà ti fún wa ní ‘ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ aláìṣeé-ṣàpèjúwe.’ (2 Kọ́ríńtì 9:15) Kí ni ẹ̀bùn náà? Báwo lẹ̀bùn náà ṣe ń mú ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi Jésù, báwo ló ṣe ń mú ká máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa ká sì máa dárí jì wọ́n látọkàn wá? A máa rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí, a tún má a ṣàgbéyẹ̀wò àwọn nǹkan tá a lè ṣe nígbà Ìrántí Ikú Kristi.
Ọ̀SẸ̀ MARCH 14-20, 2016
14 Ẹ̀mí Ń Jẹ́rìí Pẹ̀lú Ẹ̀mí Wa
Ọ̀SẸ̀ MARCH 21-27, 2016
Nínú àpilẹ̀kọ méjèèjì yìí, a máa ṣàlàyé bí ẹnì kan á ṣe mọ̀ bí Jèhófà bá ti fẹ̀mí yàn án láti lọ sọ́run àti ohun tó túmọ̀ sí fún ẹnì kan láti di ẹni àmì òróró. Yàtọ̀ síyẹn, a máa mọ irú ojú tó yẹ kí àwọn ẹni àmì òróró máa fi wo ara wọn, a sì tún máa mọ ìdí tí kò fi yẹ ká máa da ara wa láàmú bí iye àwọn tó ń jẹ búrẹ́dì tí wọ́n sì ń mu wáìnì níbi Ìrántí Ikú Kristi bá ń pọ̀ sí i.
Ọ̀SẸ̀ MARCH 28, 2016–APRIL 3, 2016
27 À Ń Láyọ̀ Bá A Ṣe Ń Bá Ọlọ́run Ṣiṣẹ́
Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jèhófà ti fún àwọn míì láǹfààní láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú rẹ̀ kí ìfẹ́ rẹ̀ lè ṣẹ. Ó fẹ́ kí ìhìn rere dé ibi gbogbo láyé, ó sì ti fún wa láǹfààní láti ṣe iṣẹ́ náà. Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká rí ìdí tá a fi ń láyọ̀ bá a ṣe ń bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́.
ÀWÒRÁN IWÁJÚ ÌWÉ:
MADAGÁSÍKÀ
Aṣáájú-ọ̀nà kan ń fi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan han ẹnì kan tó ń wa kẹ̀kẹ́ tí wọ́n ń fi màlúù fà lójú ọ̀nà kan tí igi oṣè wà lọ́tùn-ún lósì nílùú Morondava, lórílẹ̀-èdè Madagásíkà
IYE AKÉDE
29,963
IYE ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ
77,984
IYE ÀWỌN TÓ WÁ SÍBI ÌRÁNTÍ IKÚ KRISTI