ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp16 No. 4 ojú ìwé 9
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jésù Sọ̀rọ̀ Nípa Ìkọ̀sílẹ̀, Ó sì Fìfẹ́ Hàn Sáwọn Ọmọdé
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Awọn Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Lórí Ìkọ̀sílẹ̀ ati Lórí Ìfẹ́ fun Awọn Ọmọ
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • “Ohun Tí Ọlọ́rùn Ti So Pọ̀ . . . ”
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
  • Fi Ọwọ́ Pàtàkì Mú “Ohun Tí Ọlọ́run Ti So Pọ̀”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
wp16 No. 4 ojú ìwé 9

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kí ló ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú bí Jésù ṣe hùwà sáwọn adẹ́tẹ̀?

Jésù fọwọ́ kan adẹ́tẹ̀

Àwọn Júù máa ń bẹ̀rù àìsàn ẹ̀tẹ̀ kan tó sábà máa ń ṣe àwọn èèyàn láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Ńṣe ló máa ń mú kí ara ẹni náà kú tipiri, táá sì sọ ẹni náà di aláàbọ̀ ara débi tí kò fi ní látùnṣe mọ́. Àìsàn náà kò gbóògùn nígbà yẹn. Torí náà, ńṣe ni wọ́n máa ń ya àwọn tó ní àìsàn yìí sọ́tọ̀, tí wọ́n á sì pàṣẹ fún wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ẹnikẹ́ni sún mọ́ wọn.—Léfítíkù 13:45, 46.

Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù ṣe òfin tó kọjá ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa àìsàn náà, èyí sì ń mú káyé nira fún ẹni tó bá ní àìsàn yìí. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ṣòfin pé àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ jìnnà sí adẹ́tẹ̀ kan fún ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin (nǹkan bíi 6 ft, tàbí 2 m). Àmọ́ tí afẹ́fẹ́ bá sì ń fẹ́, àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ jìnnà sí wọn tó ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ (nǹkan bíi 150 ft, tàbí 45 m). Àwọn ẹlẹ́sìn Támọ́dì kan gbà pé ọ̀rọ̀ Bíbélì tó ní káwọn adẹ́tẹ̀ máa gbé “ní òde ibùdó” túmọ̀ sí pé wọn ò gbọ́dọ̀ wọ àárín ìlú rárá. Torí náà, nígbà tí rábì kan rí adẹ́tẹ̀ kan láàárín ìlú, ńṣe ló ń sọ ọ́ lókùúta tó sì ń sọ pé: “Kúrò láàárín wa, má wàá sọ wá di aláìmọ́.”

Èyí yàtọ̀ pátápátá sí bí Jésù ṣe máa ń hùwà sí wọn! Dípò táá fi lé àwọn adẹ́tẹ̀ da nù, ó máa ń wù ú láti fọwọ́ kàn wọ́n, kó sì wò wọ́n sàn.—Mátíù 8:3.

Kí làwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù sọ pé èèyàn lè torí ẹ̀ jáwèé ìkọ̀sílẹ̀?

Ìwé ìkọ̀sílẹ̀ tí wọ́n lò ní 71 tàbí 72 Sànmánì Kristẹni

Ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ láti 71/72 Sànmánì Kristẹni

Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn máa ń jiyàn gan-an lórí ọ̀rọ̀ ìkọ̀sílẹ̀. Ó tiẹ̀ nígbà kan táwọn Farisí gbé ìbéèrè yìí ko Jésù lójú pé: “Ó ha bófin mu fún ọkùnrin láti kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ lórí onírúurú ìdí gbogbo?”—Mátíù 19:3.

Òfin Mósè gba ọkùnrin láyè láti kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ tí ọkùnrin náà bá “rí ohun àìbójúmu kan níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.” (Diutarónómì 24:1) Nígbà ayé Jésù, ilé ẹ̀kọ́ rábì méjì ló wà tí èrò wọn yàtọ̀ síra. Ṣámáhì ni ilé ẹ̀kọ́ rábì àkọ́kọ́ tó le jù, wọ́n gbà pé “ìṣekúṣe,” ìyẹn panṣágà, nìkan ló lè mú kí ẹnì kan jáwèé ìkọ̀sílẹ̀. Ilé ẹ̀kọ́ Hílẹ́lì, ní tiwọn gbà pé ọkùnrin lè kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ tí èdèkòyédè bá ń wáyé nínú ìdílé, kódà kó má tó nǹkan. Ilé ẹ̀kọ́ yìí sọ pé ọkùnrin lè kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ tí kò bá se oúnjẹ alẹ́ kó dùn tàbí tó rí obìnrin míì tó rẹwà ju ìyàwó rẹ̀ lọ.

Báwo wá ni Jésù ṣe dáhùn ìbéèrè àwọn Farisí náà? Ó làá mọ́lẹ̀ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, bí kò ṣe lórí ìpìlẹ̀ àgbèrè, tí ó sì gbé òmíràn níyàwó, ṣe panṣágà.”—Mátíù 19:6, 9.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́