Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìròyìn Yìí
Ọ̀SẸ̀ SEPTEMBER 25, 2017–OCTOBER 1, 2017
3 Ṣé Wàá Lè Fi Sùúrù Dúró De Jèhófà?
Ọ̀SẸ̀ OCTOBER 2-8, 2017
8 ‘Àlàáfíà Ọlọ́run Ta Gbogbo Ìrònú Yọ’
Àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ sọ ìdí tó fi yẹ ká máa fi sùúrù dúró de Jèhófà. A tún máa jíròrò bí àpẹẹrẹ àwọn olóòótọ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin láyé àtijọ́ ṣe lè mú ká lẹ́mìí ìdúródeni. Àpilẹ̀kọ kejì sọ bí Jèhófà ṣe máa ń gbọ̀nà àrà ṣe àwọn nǹkan. Àwọn àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ká sì fi sùúrù dúró de ìgbà tó máa gbé ìgbésẹ̀.
13 Ìtàn Ìgbésí Ayé—A Fara Da Ìpọ́njú, Jèhófà sì Bù Kún Wa
Ọ̀SẸ̀ OCTOBER 9-15, 2017
17 Bá A Ṣe Lè Bọ́ Ìwà Àtijọ́ Sílẹ̀, Ká Má sì Gbé E Wọ̀ Mọ́
Ọ̀SẸ̀ OCTOBER 16-22, 2017
22 Bá A Ṣe Lè Gbé Àkópọ̀ Ìwà Tuntun Wọ̀, Tá Ò sì Ní Bọ́ Ọ Sílẹ̀ Mọ́
Àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ sọ ohun tó túmọ̀ sí láti bọ́ àwọn ìwà àtijọ́ sílẹ̀ àti ìdí tá a fi gbọ́dọ̀ tètè ṣe bẹ́ẹ̀. Ó tún sọ àwọn ohun tá a lè ṣe tá ò fi ní pa dà sídìí àwọn ìwà tá a ti fi sílẹ̀. Àpilẹ̀kọ kejì sọ àwọn ànímọ́ tó wà lára àkópọ̀ ìwà tuntun, ó sì ṣàlàyé bá a ṣe lè fi wọ́n sílò nígbèésí ayé wa àti lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa.