Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìròyìn Yìí
Ọ̀SẸ̀ OCTOBER 23-29, 2017
Jèhófà ló fi àpẹẹrẹ tó ga jù lọ lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ìkóra-ẹni-níjàánu. Báwo làwa èèyàn ṣe lè fara wé e? Àwọn nǹkan wo la lè ṣe táá jẹ́ ká túbọ̀ máa kó ara wa níjàánu?
Ọ̀SẸ̀ OCTOBER 30, 2017–NOVEMBER 5, 2017
Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn jẹ́ aláàánú? Tó bá di pé ká fàánú hàn, Jèhófà àti Jésù ló fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀. Àmọ́, àwọn ọ̀nà pàtó wo la lè gbà ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ bíi tiwọn? Àǹfààní wo la sì máa rí tá a bá ń fàánú hàn?
13 Ìtàn Ìgbésí Ayé—Inú Mi Dùn Pé Mo Bá Àwọn Tó Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ṣiṣẹ́
Ọ̀SẸ̀ NOVEMBER 6-12, 2017
18 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Yóò Wà Títí Láé
Ọ̀SẸ̀ NOVEMBER 13-19, 2017
23 “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run . . . Ń Sa Agbára”
Kí nìdí tó fi jọni lójú gan-an pé Bíbélì túbọ̀ ń wà ní ọ̀pọ̀ èdè? Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì Bíbélì ní báyìí tó ti wà ní èdè tá a lóye? Àpilẹ̀kọ méjèèjì yìí máa mú ká túbọ̀ mọyì Bíbélì, á sì jẹ́ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó fún wa ní Bíbélì.
Ọ̀SẸ̀ NOVEMBER 20-26, 2017
28 “Jẹ́ Onígboyà . . . Kí O sì Gbé Ìgbésẹ̀”
Ó ṣe pàtàkì pé káwa Kristẹni nígboyà. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ lára àwọn tó lo ìgboyà nínú Bíbélì? Báwo làwọn ọ̀dọ́, àwọn òbí, àwọn àgbà obìnrin àtàwọn arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi ṣe lè lo ìgboyà, kí wọ́n sì gbé ìgbésẹ̀?