ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w17 October ojú ìwé 31
  • Oore Kan Tó Sèso Rere

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Oore Kan Tó Sèso Rere
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kẹ́kọ̀ọ́ Lára “Ọmọ Ẹ̀yìn Tí Jésù Nífẹ̀ẹ́”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Johanu Ha Ṣàìní Ìgbàgbọ́ Bí?
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Jòhánù Fẹ́ Gbọ́rọ̀ Látẹnu Jésù
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Ta Ni Jòhánù Arinibọmi?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
w17 October ojú ìwé 31
John gba ìwé “Ihinrere Ijọba Yi” lọ́wọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan

Oore Kan Tó Sèso Rere

ÌLÚ kékeré kan ní Gujarat, lórílẹ̀-èdè Íńdíà ni John, àwọn òbí rẹ̀, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ àtàwọn àbúrò rẹ̀ mẹ́rin ń gbé. Ọgọ́ta [60] ọdún sẹ́yìn ni bàbá John ṣèrìbọmi, ó sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́, ìyàwó rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀ ta ko ẹ̀sìn tuntun tí bàbá náà ń ṣe torí pé ẹlẹ́sìn Kátólíìkì paraku ni wọ́n.

Lọ́jọ́ kan, bàbá John ní kí John lọ bá òun fún arákùnrin kan ní lẹ́tà. Àmọ́, láàárọ̀ ọjọ́ yẹn, agolo kan ya John lọ́wọ́, ó sì ṣe é léṣe gan-an. Síbẹ̀, torí pé ó fẹ́ jíṣẹ́ tí bàbá rẹ̀ rán an, ó fi aṣọ so ìka náà, ó sì sáré lọ fi lẹ́tà náà jíṣẹ́.

Nígbà tí John dé ibi tí wọ́n rán an lọ, ìyàwó onítọ̀hún ló bá, Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì ni obìnrin náà. Nígbà tó gba lẹ́tà náà lọ́wọ́ John, ó kíyè sí i pé John ṣèṣe lọ́wọ́, ó wá sọ fún un pé òun máa bá a tọ́jú egbò náà. Ó kó àwọn ohun èlò ìtọ́jú pàjáwìrì tí wọ́n ní jáde, ó wẹ ojú egbò náà, ó bu oògùn sí i, ó sì fi báńdéèjì dì í. Lẹ́yìn náà, ó po tíì tó gbóná fún John. Gbogbo àsìkò tí obìnrin yẹn fi ń tọ́jú John ló ń bá a sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì.

Ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn mú kí ọkàn John bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀, èrò òdì tó ní nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà. Ó wá bi obìnrin náà láwọn ìbéèrè méjì tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn. Ó béèrè ìdí táwa Ẹlẹ́rìí fi sọ pé Jésù kì í ṣe Ọlọ́run àti ìdí tá a fi sọ pé kò yẹ kéèyàn máa gbàdúrà sí Màríà, tó sì jẹ́ pé ohun táwọn gbà gbọ́ nìyẹn. Torí pé arábìnrin yẹn ti kọ́ èdè Gujarati, èdè yẹn lòun àti John jọ sọ. Ó fi Bíbélì dá a lóhùn, ó sì fún un ní ìwé “Ihinrere Ijọba Yi.”

Nígbà tí John bẹ̀rẹ̀ sí í ka ìwé yẹn, ó gbà pé ẹ̀kọ́ òtítọ́ ló wà nínú rẹ̀. Ló bá gba ọ̀dọ̀ àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì wọn lọ, ó sì bi í láwọn ìbéèrè méjì kan náà. Inú bí àlùfáà náà, ló bá ju Bíbélì lu John, ó sì pariwo mọ́ ọn pé: “Sátánì ti kó wọnú ẹ! Ó yá, sọ fún mi, ibo ni Bíbélì ti sọ pé Jésù kì í ṣe Ọlọ́run. Ibo ni Bíbélì ti sọ pé kò yẹ ká jọ́sìn Màríà? Sọ fún mi!” Ohun tí àlùfáà yẹn ṣe ya John lẹ́nu gan-an, ló bá sọ fún àlùfáà náà pé, “Láyé mi, mi ò tún fẹsẹ̀ tẹnú ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì mọ́.” Kò sì débẹ̀ mọ́ lóòótọ́.

Bí John ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìyẹn, ó ya ara rẹ̀ sí mímọ́, ó sì ṣèrìbọmi. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, àwọn míì nínú ìdílé náà di Ẹlẹ́rìí. Ọgọ́ta [60] ọdún sẹ́yìn ni agolo ya John lọ́wọ́, àmọ́ àpá yẹn ṣì wà níbẹ̀ dòní olónìí. Kò jẹ́ gbàgbé oore tí arábìnrin yẹn ṣe fún un, torí pé oore yẹn ló mú kó wá sin Jèhófà.​—2 Kọ́r. 6:​4, 6.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́