Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìròyìn Yìí
Ọ̀SẸ̀ DECEMBER 25-31, 2017
Apá pàtàkì ni orin kíkọ jẹ́ nínú ìjọsìn wa. Síbẹ̀, kì í fi bẹ́ẹ̀ yá àwọn kan lára láti kọrin sókè ní gbangba. Kí la lè ṣe táá fi mọ́ wa lára láti máa kọrin sókè sí Jèhófà? Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé ìdí tó fi yẹ ká máa gbóhùn sókè tá a bá ń kọrin. Ó tún sọ àwọn nǹkan tá a lè ṣe táá jẹ́ kí ohùn wa sunwọ̀n sí i.
Ọ̀SẸ̀ JANUARY 1-7, 2018
Ọ̀SẸ̀ JANUARY 8-14, 2018
13 Máa Fàánú Hàn, Kó O sì Máa Ṣe Ìdájọ́ Òdodo Bíi Ti Jèhófà
A lè rí ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ètò tí Jèhófà ṣe pé káwọn tó ṣèèṣì pààyàn nílẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́ sá lọ sí ìlú ààbò. Nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́, a máa rí bí ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ lóde òní ṣe lè rí ààbò Jèhófà. Nínú àpilẹ̀kọ kejì, àá rí bí àpẹẹrẹ Jèhófà ṣe máa mú káwa náà máa dárí jini, ká máa fojú tí Jèhófà fi ń wo ẹ̀mí èèyàn wò ó, ká sì máa ṣèdájọ́ òdodo.
18 A Ó Bù Kún Ẹni Tí Ó Jẹ́ Ọ̀làwọ́
Ọ̀SẸ̀ JANUARY 15-21, 2018
Ọ̀SẸ̀ JANUARY 22-28, 2018
25 Má Ṣe Jẹ́ Kí Ohunkóhun Mú Kó O Pàdánù Èrè Ọjọ́ Iwájú
Ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni tó wà nílùú Kólósè la gbé àpilẹ̀kọ méjèèjì yìí kà. Àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ sọ àwọn ohun tá a lè ṣe táwọn èèyàn ayé bá fẹ́ fi èrò wọn yí wa lọ́kàn pa dà. Àpilẹ̀kọ kejì sọ àwọn ìwà tó lè mú kéèyàn pàdánù àwọn ìbùkún tí Jèhófà ṣèlérí, ó sì sọ ohun tá a lè ṣe tá ò fi ní pàdánù wọn.