Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìròyìn Yìí
3 Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—Ní Madagásíkà
Ọ̀SẸ̀ FEBRUARY 26, 2018–MARCH 4, 2018
7 “Ó Ń Fi Agbára fún Ẹni Tí Ó Ti Rẹ̀”
Tó bá dà bíi pé a ò lè fara da àwọn ìṣòro tá à ń kojú, kí la lè ṣe? Àpilẹ̀kọ yìí jíròrò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wa ti ọdún 2018, ó sì sọ ìdí tó fi yẹ ká jẹ́ kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́ ká lè fara dà á àti bó ṣe máa ṣe bẹ́ẹ̀.
Ọ̀SẸ̀ MARCH 5-11, 2018
12 Ìrántí Ikú Kristi Ń Mú Ká Wà Níṣọ̀kan
Saturday, March 31, 2018 la máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi tọdún yìí. Báwo la ṣe lè múra sílẹ̀ ká sì jàǹfààní nínú Ìrántí Ikú Kristi? Àwọn ọ̀nà wo ni Ìrántí Ikú Kristi ń gbà mú káwa èèyàn Ọlọ́run túbọ̀ wà níṣọ̀kan? Wàá rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ yìí.
Ọ̀SẸ̀ MARCH 12-18, 2018
17 Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Fún Ẹni Tó Ni Ohun Gbogbo Ní Nǹkan?
Jèhófà ló fún wa ní gbogbo ohun tá a ní. Síbẹ̀ ó fẹ́ ká máa fi owó ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ tí ètò rẹ̀ ń ṣe. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ìdí tó fi yẹ ká máa fi àwọn ohun ìní wa tó níye lórí bọlá fún Jèhófà àtàwọn ìbùkún tá a máa rí tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀.
Ọ̀SẸ̀ MARCH 19-25, 2018
22 Ìfẹ́ Wo Ló Ń Mú Kéèyàn Ní Ojúlówó Ayọ̀?
Ọ̀SẸ̀ MARCH 26, 2018–APRIL 1, 2018
27 Ìyàtọ̀ Tó Wà Láàárín Àwọn Tó Ń Sin Ọlọ́run Àtàwọn Tí Kò Sìn Ín
Àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ jẹ́ kó ṣe kedere pé ìfẹ́ fún Ọlọ́run ló ń jẹ́ kéèyàn ní ojúlówó ayọ̀, kì í ṣe ìfẹ́ ìmọtara-ẹni-nìkan táwọn èèyàn ní láwọn “ọjọ́ ìkẹyìn” yìí. (2 Tím. 3:1) Àpilẹ̀kọ kejì sọ bí ìwà àwa èèyàn Ọlọ́run ṣe yàtọ̀ pátápátá sí ìwà abèṣe táwọn èèyàn ayé ń hù láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí.
32 ǸJẸ́ O MỌ̀?