Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
Ọ̀SẸ̀ JUNE 4-10, 2018
3 Bá A Ṣe Lè Ní Òmìnira Tòótọ́
Ọ̀SẸ̀ JUNE 11-17, 2018
8 Jọ́sìn Jèhófà, Ọlọ́run Tí Ń Fúnni Ní Òmìnira
Gbogbo èèyàn láyé ló fẹ́ túbọ̀ lómìnira. Èrò wo ló yẹ káwa Kristẹni ní nípa òmìnira? Àwọn àpilẹ̀kọ méjèèjì yìí máa jẹ́ ká mọ ohun tí òmìnira tòótọ́ túmọ̀ sí, bá a ṣe lè ní in àti bá a ṣe lè lo òmìnira wa lọ́nà tó máa ṣe àwa àtàwọn míì láǹfààní. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, a máa rí bá a ṣe lè fi ìyìn àti ògo fún Jèhófà.
13 Ẹ̀yin Arákùnrin Tá A Yàn Sípò —Ẹ Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Tímótì
Ọ̀SẸ̀ JUNE 18-24, 2018
15 Máa Fúnni Níṣìírí Bíi Ti Jèhófà
Ọ̀SẸ̀ JUNE 25, 2018–JULY 1, 2018
20 Ìsinsìnyí Ló Yẹ Ká Máa Fún Ara Wa Níṣìírí Ju ti Ìgbàkigbà Rí Lọ
Àwọn àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká rí i pé ọjọ́ pẹ́ tí Jèhófà ti máa ń fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ níṣìírí, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ náà sì máa ń fún àwọn míì níṣìírí. A tún máa rí ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa fún ara wa níṣìírí nísinsìnyí ju ti ìgbàkígbà rí lọ.
Ọ̀SẸ̀ JULY 2-8, 2018
25 Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ṣé Ìjọsìn Jèhófà Ló Gbawájú ní Ìgbésí Ayé Yín?
Ọ̀pọ̀ àǹfààní làwọn ọ̀dọ́ máa rí tí wọ́n bá pinnu láti fayé wọn ṣiṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ ká ní àfojúsùn tẹ̀mí nígbà tá a ṣì wà lọ́dọ̀ọ́, ká sì gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù.