ÀWỌN OHUN TÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ ÌRÒYÌN YÌÍ
Ọ̀SẸ̀ FEBRUARY 4-10, 2019
Àwa Kristẹni tòótọ́ ń fojú sọ́nà láti gbé nínú Párádísè. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ tó mú ká gbà pé Párádísè máa wà lóòótọ́. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa ìlérí tí Jésù ṣe fún ọ̀daràn tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.
8 Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ọ̀SẸ̀ FEBRUARY 11-17, 2019
10 Fi Ọwọ́ Pàtàkì Mú “Ohun Tí Ọlọ́run Ti So Pọ̀”
Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa ìgbéyàwó. Báwo la ṣe lè fọwọ́ pàtàkì mú ìgbéyàwó? Báwo la sì ṣe lè fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò tó bá dọ̀rọ̀ ìpínyà àti ìkọ̀sílẹ̀?
15 Ìtàn Ìgbésí Ayé—Jèhófà Fi Inú Rere Hàn sí Wa
Ọ̀SẸ̀ FEBRUARY 18-24, 2019
19 Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ẹlẹ́dàá Yín Fẹ́ Kẹ́ Ẹ Láyọ̀
Ọ̀SẸ̀ FEBRUARY 25, 2019–MARCH 3, 2019
24 Bí Ẹ̀yin Ọ̀dọ́ Ṣe Lè Gbádùn Ìgbésí Ayé Yín
Ó máa ń pọn dandan fáwọn ọ̀dọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì kan nígbèésí ayé, irú bí ohun tó yẹ kí wọ́n fayé wọn ṣe. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn olùkọ́ àtàwọn míì lè sọ pé kí wọ́n lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga kí wọ́n sì lé bí wọ́n á ṣe rọ́wọ́ mú nínú ayé. Àmọ́, ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé kí wọ́n fi ìjọsìn rẹ̀ ṣáájú láyé wọn. Àwọn àpilẹ̀kọ méjèèjì yìí máa jẹ́ ká rí i pé ohun tó bọ́gbọ́n mu jù ni pé káwọn ọ̀dọ́ tẹ́tí sí Jèhófà.