Fífi Ìfẹ́ Kristian Yanjú Ìṣòro
1 Lẹ́tà Jakọbu, ní orí 4, ẹsẹ 1, béèrè pé: “Lati orísun wo ni awọn ogun ti wá lati orísun wo sì ni awọn ìjà ti wá láàárín yín?” Ó dáhùn ní kedere pé, ó jẹ́ láti inú ìfàsí ọkàn ẹran ara fún wíwá ipò pàtàkì tàbí ìfẹ́ ọkàn láti borí àwọn ẹlòmíràn. Dájúdájú, bí gbọ́nmisi-omi-ò-tó bá wà, tí a sì jẹ́ kí owú àti ìlara fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìjọ, ó di dandan kí ìfẹ́ àti àlàáfíà nínú agbo ilé ìgbàgbọ́ pòórá.—Gal. 5:15.
2 Ìjà: Àwọn kan kò tilẹ̀ rò pé ìjà, tí ó jẹ́ àfihàn ìrufùfù ìbínú, jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ìyọnilẹ́gbẹ́. Nínú àwọn ìdílé kan nínú ayé, kì í ṣe ohun àjèjì fún ọkọ láti lu ìyàwó rẹ̀ bolẹ̀, nítorí ìdí ti ara ẹni tàbí nítorí tí a mú un bínú. Ojú wo ni ìjọ yóò fi wo irú nǹkan bẹ́ẹ̀, bí ó bá ní í ṣe pẹ̀lú àwọn mẹ́ḿbà ìjọ? Ní sísọ̀rọ̀ lórí irú ìwà ìkà burúkú gbáà bẹ́ẹ̀, Ilé-Ìṣọ́nà ti November 1, 1988, ojú ìwé 22, ìpínrọ̀ 11, sọ lápá kan pé: “Àwọn alàgbà ijọ nilati ṣèwádìí awọn ìfisùn fun ìlùkulù ti ara nigbati ọ̀ràn bá kan awọn Kristian meji tí wọn wà ninu igbeyawo oníwàhálà-ìdààmú, ìgbésẹ̀ṣiṣẹ́ ìyọlẹ́gbẹ́ ni ó lè di dandan lati gbé.” Ìwé mímọ́ sọ pé, “kò sí ènìyàn kankan tí ó jẹ́ kórìíra ẹran-ara oun fúnra rẹ̀.” Ìjọ Kristian kò fàyè gba àwọn ọkùnrin tí ń na ìyàwó wọn.
3 Bí Ó Ṣe Yẹ Kí A Hùwà Nígbà Tí Ìṣòro Bá Dìde: Ní Johannu 13:34, 35, Oluwa wa, Jesu Kristi, sọ pé, ó yẹ kí ìfẹ́ fi àwọn ọmọlẹ́yìn òun hàn yàtọ̀. Ní ṣíṣàlàyé síwájú sí i lórí èyí, aposteli Paulu ṣàlàyé lẹ́sẹẹsẹ bí ó ṣe yẹ kí ìfẹ́ Kristian tòótọ́ hùwà. (Ka 1 Korinti 13:4-7.) A tún sọ ní 1 Peteru 4:8 pé, “ìfẹ́ a máa bo ògìdìgbó ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.” Ìfẹ́ rẹ ha lágbára tó láti bo àṣìṣe tàbí ẹ̀ṣẹ̀ tí onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ tàbí mẹ́ḿbà ìdílé rẹ ṣẹ̀ ọ mọ́lẹ̀ bí? Gbìyànjú láti mú àwọn ànímọ́ tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fi ìfẹ́ bá àwọn ará àti àwọn mẹ́ḿbà ìdílé rẹ lò dàgbà.
4 Àṣírí Fífi Ìfẹ́ Yanjú Ìṣòro: Fífi ìfẹ́ ọmọnìkejì hàn ń mú kí ìṣọ̀kan gbèrú láàárín àwọn ìránṣẹ́ Jehofa. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ìṣòro máa ń yọjú, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Bí ó bá jẹ́ ọ̀ràn tí ó wúwo ni, àwọn Kristian ní láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jesu, tí a kọ sílẹ̀ nínú Matteu 18:15-17. Kíyè sí ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́. Ó jẹ́ láti bá arákùnrin rẹ sọ̀rọ̀ níkọ̀kọ̀. Pẹ̀lú ète wo? ‘Jíjèrè arákùnrin rẹ padà.’ Ìgbésẹ̀ kejì (bí ó bá pọn dandan) jẹ́ láti mú ẹnì kan tàbí méjì pẹ̀lú rẹ lọ bá ẹni náà, “kí a lè fi ìdí ọ̀ràn gbogbo múlẹ̀ ní ẹnu ẹlẹ́rìí méjì tabi mẹ́ta.” Lọ́pọ̀ ìgbà, ìgbésẹ̀ kẹta kì í pọn dandan.
5 Ohun Tí Ó Yẹ Kí O Gbé Yẹ̀ Wò: Ṣáájú kí o tó ṣiṣẹ́ lórí Matteu 18:15-17, gbé ìwúwo rinlẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ tí a ṣẹ̀ ọ́ yẹ̀ wò. Ilé-Ìṣọ́nà ti January 15, 1982, ní ojú ìwé 17 sí 20, sọ pé, wọ́n ní láti jẹ́ “ẹṣẹ ti o wuwo de àyè pe a le titori rẹ̀ yọ ẹnikan lẹgbẹ kuro ninu ijọ,” irú bí ìbanilórúkọjẹ́ tàbí òfófó aláràn-ánkan. A kò gbọdọ̀ gbé ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ kalẹ̀ lórí ọ̀ràn ìbanilórúkọjẹ́, bí àwọn tí ọ̀ràn kàn kò bá tí ì ṣiṣẹ́ lórí Matteu 18:15-17. (Tún wo ìwé Iṣetojọ, ojú ìwé 142 sí 144.) Ó yẹ kí ẹni tí a ṣẹ̀ bí ara rẹ̀ léèrè pé, ‘Mo ha lè dárí jì í kí n sì gbàgbé rẹ̀?’—Kol. 3:13.
6 A rọ àwọn Kristian láti lépa àwọn ohun tí ń yọrí sí àlàáfíà. (Romu 14:19; 1 Pet. 3:10-12) Kò yẹ kí a sọ ìjọ di ojú ogun tí a ti ń bá ara wa jà, bí kò ṣe ibi àìléwu nípa tẹ̀mí. Nítorí náà, bí ìṣòro bá dìde, ǹjẹ́ kí a yára láti fi ìfẹ́ Kristian yanjú rẹ̀.