Àwọn Ìfilọ̀
◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní December: Gbogbo èdè—Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí, fún ₦240. Bí kò bá sí lárọ̀ọ́wọ́tó, lo Iwe Itan Bibeli Mi (₦240) tàbí Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye (ńlá, ₦120; kékeré, ₦120). January: Gbogbo èdè—A lè fi ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí, tí a tẹ̀ sórí bébà tí ń di pípọ́n ràkọ̀ràkọ̀ tàbí tí ń pàwọ̀ dà tàbí èyíkéyìí tí a tẹ̀ jáde ṣáájú 1982, lọni ní ẹ̀dínwó. A kò gbọdọ̀ fi àwọn ìtẹ̀jáde tí a tẹ̀ sórí bébà tí kì í ṣá tàbí pàwọ̀ dà kún àwọn ìfilọni ẹlẹ́dìn-ínwó yìí. February àti March: Efik, Gẹ̀ẹ́sì, àti Igbo—Revelation—Its Grand Climax At Hand! Àwọn èdè yòókù—Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. ÀKÍYÈSÍ: Àwọn ìjọ tí yóò nílò àwọn ìwé ìgbétásì tí a mẹ́nu kàn lókè yìí, ní láti béèrè fún wọn lórí Literature Order Form (S-14) olóṣooṣù wọn, ti oṣù tí ń bọ̀.
◼ Alábòójútó olùṣalága tàbí ẹnì kan tí òun yàn, gbọ́dọ̀ ṣàkọsílẹ̀ àkáǹtì ìjọ ní December 1 tàbí bí ó bá ti lè ṣeé ṣe kí ó yá tó lẹ́yìn náà. Ẹ ṣe ìfilọ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tí ẹ bá ti ṣe èyí.
◼ Ìṣe Ìrántí fún 1997 yóò jẹ́ ní Sunday, March 23, lẹ́yìn tí oòrùn bá ti wọ̀. A pèsè Ìsọfúnni ṣáájú nípa déètì ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí 1997 yìí, kí àwọn ará lè ṣètò tàbí ṣe àdéhùn tí ó pọn dandan fún àwọn gbọ̀ngàn tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó, bí ìjọ tí ó pọ̀ bá ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba, tí wọ́n sì ní láti wá àwọn ilé mìíràn.
◼“Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun fún 1996” ni àkìbọnú tí ó wà nínú ìtẹ̀jáde Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí, a sì gbọdọ̀ tọ́jú rẹ̀ pa mọ́ fún ìtọ́kasí jálẹ̀ ọdún 1996.