Àwọn Ìfilọ̀
◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní May: Gbogbo èdè—àsansílẹ̀-owó fún Ilé-Ìṣọ́nà. Ìwé ìròyìn ẹlẹ́ẹ̀mejì lóṣù fún ọdún kan, ₦400. Ọdún kan fún olóṣooṣù tàbí oṣù mẹ́fà ẹlẹ́ẹ̀mejì lóṣù, ₦200. Fún ìpínlẹ̀ tí a ń ṣe lemọ́lemọ́, a tún lè lo ìwé pẹlẹbẹ èyíkéyìí (yàtọ̀ sí ìwé pẹlẹbẹ Education àti School). June: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Bí ìyẹn kò bá sí lárọ̀ọ́wọ́tó, lo ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí, Mankind’s Search for God, tàbí ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí. July àti August: A lè lo èyíkéyìí nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 tí ó tẹ̀ lè é yìí: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bi?, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, àti “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.” Níbi tí ó bá ti yẹ, a lè fi àwọn ìwé pẹlẹbẹ bíi, Our Problems—Who Will Help Us Solve Them?, àti Will There Ever Be a World Without War? lọni. ÀKÍYÈSÍ: Àwọn ìjọ tí yóò nílò àwọn ìwé ìgbétásì tí a mẹ́nu kàn lókè yìí ní láti béèrè fún wọn lórí Literature Order Form (S-14) olóṣooṣù wọn, ti oṣù tí ń bọ̀.
◼ Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà June 15 àti Jí! June 22, gbogbo ọ̀rọ̀ Bibeli tí a bá fà yọ, títí kan orúkọ àwọn ènìyàn, ni a óò máa kọ ní ọ̀nà àkọtọ́ ti òde òní. Kí gbogbo rẹ̀ baà lè ṣe déédéé délẹ̀, èyí yóò tún kan ọ̀rọ̀ tí a bá fà yọ láti inú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun ní èdè Yorùbá. Ohun kan náà ni yóò ṣẹlẹ̀ sí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa bẹ̀rẹ̀ láti June 1996.