ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 6/96 ojú ìwé 7
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
km 6/96 ojú ìwé 7

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní June: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun fún ₦80. Bí ìyẹn kò bá sí lárọ̀ọ́wọ́tó, lo ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí fún ₦240 tàbí Mankind’s Search for God fún ₦120, tàbí ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí. July àti August: A lè lo èyíkéyìí nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 tí ó tẹ̀ lè é yìí: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, àti “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.” Níbi tí ó bá ti yẹ, a lè fi àwọn ìwé pẹlẹbẹ bíi, Our Problems—Who Will Help Us Solve Them? àti Will There Ever Be a World Without War? lọni. ÀKÍYÈSÍ: Àwọn ìjọ tí yóò nílò àwọn ìwé ìgbétásì tí a mẹ́nu kàn lókè yìí ní láti béèrè fún wọn lórí Literature Order Form (S-14) olóṣooṣù wọn, ti oṣù tí ń bọ̀.

◼ Bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀sẹ September 9, 1996, títí jálẹ̀ ọ̀sẹ September 29, 1997, A óò kẹ́kọ̀ọ́ ìwé, Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí nínú Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ.

◼ Kí alábòójútó olùṣalága tàbí ẹnì kan tí òún yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní June 1 tàbí bí ó bá ti lè ṣeé ṣe kí ó yá tó lẹ́yìn náà. Ẹ ṣe ìfilọ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tí ẹ bá ti ṣe èyí.

◼ Láti mú kí ó túbọ̀ rọrùn fún Society láti bójú tó àwọn lẹ́tà rẹ, o ní láti kíyè sí àwọn ohun tí ó tẹ̀ lé e yìí: (1) Kọ orúkọ àti àdírẹ́sì rẹ sí òkè lápá ọ̀tún lẹ́tà rẹ. (2) Bọwọ́ lu lẹ́tà rẹ ní òpin rẹ̀, kí o sì kọ orúkọ rẹ sábẹ́ ìbọwọ́lùwé náà, níwọ̀n bí a ti lè ṣàìlóye ìbọwọ́lùwé rẹ tàbí ṣàìlè kà á. A kì í ka àwọn lẹ́tà tí a kò bọwọ́ lù tàbí tí kò lórúkọ sí nítorí wọn kò ṣeé gbára lé. Bí o bá tẹ lẹ́tà rẹ, kò tó láti wulẹ̀ tẹ orúkọ rẹ sí ìsàlẹ̀ rẹ̀, nítorí ẹnikẹ́ni lè tẹ lẹ́tà kí ó sì tẹ orúkọ rẹ sí ìsàlẹ̀ rẹ̀. O gbọ́dọ̀ bu ọwọ́ lu lẹ́tà náà ní òke ibi tí o tẹ orúkọ rẹ sí yìí. Kí o tó fi lẹ́tà èyíkéyìí ránṣẹ́ sí Society, jọ̀wọ́ ṣàtúnyẹ̀wò rẹ̀ láti rí i dájú pé o ti tẹ̀ lé àwọn kókó méjì tí a mẹ́nu kàn lókè yìí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́