ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/96 ojú ìwé 6-7
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
km 9/96 ojú ìwé 6-7

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní September: Ẹ́fíìkì àti Haúsá—Alafia ati Ãbò Tõtọ—Lati Orisun Wo?, Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. Gẹ̀ẹ́sì—Lilaaja Sinu Ilẹ-ayé Titun, The Bible—God’s Word or Man’s? Ìgbò—Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ Julọ, Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, True Peace and Security—How Can You Find It?, Yiyan Ọna Igbesi Ayé Ti O Dara Julọ. Ísókó—Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. Yorùbá—Ayọ̀—Bi A Ṣe Lè Rí I, Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ Julọ, Igbesi Aye Yii Ha Ni Gbogbo Ohun Ti O Wà Bi?, Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. (A óò fi gbogbo ìwé tí ó ṣeé tì bọ àpò, tí a mẹ́nu kàn lókè yìí, lọni ní ẹ̀dínwó ₦50, aṣáájú ọ̀nà, ₦40; ìwe Walaaye Titilae ní Ẹ́fíìkì, Haúsá, Ìgbò, Ísókó, àti Yorùbá jẹ́ ₦80, aṣáájú ọ̀nà, ₦50. A ti fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà nípa èyí.) October: Àsansílẹ̀ owó fún Ilé Ìṣọ́ tàbí Jí! tàbí fún ìwé ìròyìn méjèèjì. November: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. A óò ṣe àkànṣe ìsapá láti ṣiṣẹ́ lórí gbogbo ìwé tí a fi síta, pẹ̀lú ète bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. December: Gẹ̀ẹ́sì—New World Translation pẹ̀lú ìwe True Peace and Security—How Can You Find It? Yorùbá—Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun. Ìfilọni àfirọ́pò: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí tàbí ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí. Àwọn èdè yòó kù—Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí tàbí Iwe Itan Bibeli Mi. Ìfilọni àfirọ́pò: Ìwe olójú ewé 192 èyíkéyìí. ÀKÍYÈSÍ: Àwọn ìjọ tí yóò nílò àwọn ìwé ìgbétásì tí a mẹ́nu kàn lókè yìí ní láti béèrè fún wọn lórí Literature Order Form (S-14) olóṣooṣù wọn, ti oṣù tí ń bọ̀.

◼ Kí alábòójútó olùṣalága tàbí ẹnì kan tí òún yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní September 1 tàbí bí ó bá ti lè ṣeé ṣe kí ó yá tó lẹ́yìn náà. Ẹ ṣe ìfilọ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tí ẹ bá ti ṣe èyí.

◼ Kí àwọn akéde tí ó ń wéwèé láti ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ aṣáájú ọ̀nà ní October tètè fi ìwé ìwọṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà sílẹ̀. Èyí yóò fún àwọn alàgbà láyè láti ṣe àwọn ètò tí ó bá pọn dandan fún ìwé ìròyìn, ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, àti ìpínlẹ̀.

◼ A ń rán àwọn alàgbà létí láti ṣiṣẹ́ lórí àwọn ìtọ́ni tí a pèsè nínú Ilé-Ìṣọ́nà ti April 15, 1991, ní ojú ìwé 21 sí 23, tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn tí a yọ lẹ́gbẹ́ tàbí tí wọ́n yọ ara wọn lẹ́gbẹ́, tí wọ́n lè nítẹ̀sí sí dídi ẹni tí a gbà padà.

◼ Ní ọjọ́ Saturday, October 26, 1996, a óò ti ilé Bẹ́tẹ́lì tí ó wà ní Igieduma pa. Kò ní ṣeé ṣe láti ṣèbẹ̀wò tàbí láti wá ra ìwé tàbí kó ìwé ní ọjọ́ náà.

◼ Ìwọ́ ha gbọ́ èdè àwọn adití bí? O ha lè ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí atúmọ̀ fún àwọn adití ní àwọn ìpàdé Kristẹni bí? Society ń ṣàkójọ orúkọ àwọn tí ó lè ṣètumọ̀ fún àwọn adití ní orílẹ̀-èdè yìí. Bí o bá ti ṣe batisí, tí o sì wà ní ìdúró rere nínú ìjọ, tí o sì fẹ́ láti ṣe ìrànwọ́ ní ọ̀nà yìí, jọ̀wọ́, fi orúkọ rẹ sílẹ̀ lọ́dọ̀ akọ̀wé ìjọ ní kíá mọ́sá. Àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin lè yọ̀ǹda ara wọn. Kí àwọn alàgbà jọ̀wọ́ fi orúkọ àwọn akéde tí ó ti ṣe batisí, tí wọ́n wà ní ìdúró rere nínú ìjọ, tí wọ́n sì lè ṣiṣẹ́ dáradára lábẹ́ ìdarísọ́nà, ránṣẹ́. A óò fẹ́ láti rí ìsọfúnni yìí gbà ní kíá mọ́sá.

◼ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ óò rí àtúnṣe tí a ṣe nínú “Àwọn Ọ̀gangan Ibi Àpéjọpọ̀ Àgbègbè 1996,” tí ó fara hàn nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti May 1996 nísàlẹ̀. Fún àwọn ìjọ tí ọ̀gangan ibi àpéjọpọ̀ wọn tàbí ọjọ́ àpéjọpọ̀ wọn ti yí padà, kí alábòójútó olùṣalága jọ̀wọ́ ṣètò pé kí a ṣèfilọ̀ nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tí ó tẹ̀ lé ìgbà tí ìtẹ̀jáde Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí tẹ̀ yín lọ́wọ́.

November 15-17, 1996

AGBOR 1 (Gẹ̀ẹ́sì) Àwọn ìjọ ME-13 ní ìtòtẹ̀léra a, b, d, láti A sí I; àwọn ìjọ ME-15 ní ìtòtẹ̀léra a, b, d, láti J sí Z

November 22-24, 1996

AGBOR 2 (Gẹ̀ẹ́sì) ME-14: Bank Avenue (Agbor), Efezomor (Agbor), Elu Oke (Agbor), Morka (Agbor), Oriekaose (Agbor), Akumazi Umuocha, Umuokum (Akwukwu Town), Aliagwa, Alifekede, Alisimie, àti Ekpon; àwọn ìjọ ME-15 ní ìtòtẹ̀léra a, b, d, láti A sí I

OYEDE 4 (Gẹ̀ẹ́sì) ME-10, 18

November 29–December 1, 1996

AGBOR 3 (Gẹ̀ẹ́sì) Àwọn ìjọ ME-12 ní ìtòtẹ̀léra a, b, d, láti A sí M; àwọn ìjọ ME-14 YÀTỌ̀ SÍ Bank Avenue (Agbor), Efezomor (Agbor), Elu Oke (Agbor), Morka (Agbor), Oriekaose (Agbor), Akumazi Umuocha, Umuokum (Akwukwu Town), Aliagwa, Alifekede, Alisimie, àti Ekpon

December 6-8, 1996

AGBOR 4 (Gẹ̀ẹ́sì) Àwọn ìjọ ME-13 ní ìtòtẹ̀léra a, b, d, láti J sí Z; àwọn ìjọ ME-12 ní ìtòtẹ̀léra a, b, d, láti N sí Z

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́