ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/96 ojú ìwé 3
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
km 11/96 ojú ìwé 3

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní November: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun fún ₦80. A óò ṣe àkànṣe ìsapá láti ṣiṣẹ́ lórí gbogbo ìwé tí a fi síta, pẹ̀lú ète bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. December: Gẹ̀ẹ́sì—New World Translation pẹ̀lú ìwé True Peace and Security—How Can You Find It? Yorùbá—Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun. Bí kò bá sí lárọ̀ọ́wọ́tó, fi Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí tàbí ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí lọni. Àwọn èdè yòó kù—Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí tàbí Iwe Itan Bibeli Mi. Bí kò bá sí lárọ̀ọ́wọ́tó, fi ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí lọni. January àti February: Ẹ́fíìkì àti Haúsá—Yálà Alafia ati Ãbò Tõtọ—Lati Orisun Wo? tàbí Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. Gẹ̀ẹ́sì—Yálà Lilaaja Sinu Ilẹ-ayé Titun tàbí The Bible—God’s Word or Man’s? Ìgbò—Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ Julọ, Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, True Peace and Security—How Can You Find It?, àti Yiyan Ọna Igbesi Ayé Ti O Dara Julọ. Ísókó—Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. Yorùbá—Ayọ̀—Bi A Ṣe Lè Rí I, Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ Julọ, Igbesi Aye Yii Ha Ni Gbogbo Ohun Ti O Wà Bi?, àti Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. ÀKÍYÈSÍ: Àwọn ìjọ tí yóò nílò àwọn ìwé ìgbétásì tí a mẹ́nu kàn lókè yìí ní láti béèrè fún wọn lórí Literature Order Form (S-14) olóṣooṣù wọn, ti oṣù tí ń bọ̀.

◼ Àwọn ìjọ tí ó ṣì ní ọ̀pọ̀ Ìròyìn Ìjọba No. 34 lọ́wọ́, lè rọ àwọn akéde láti fi ìwọ̀nyí lọni lọ́nà kan náà tí wọ́n gbà ń lo àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú mìíràn, yálà láti ilé dé ilé tàbí níbò míràn. Bí kò bá burú láti ṣe bẹ́ẹ̀ ní ìpínlẹ̀ yín, àwọn akéde lè fi ọ̀kan sílẹ̀ fún kò-sí-nílé kọ̀ọ̀kan, ní rírí i dájú pé, wọn kò fi sí ibi tí àwọn tí ń lọ tí ń bọ̀ yóò ti rí i. Kí a sapá láti pín gbogbo ẹ̀dà ìhìn iṣẹ́ ṣíṣeyebíye yìí, tí ó kù.

◼ Àwọn akéde kan tí béèrè nípa ọ̀nà tí ó yẹ láti gbà kọ orúkọ arábìnrin tí ó ti ṣègbéyàwó, sórí káàdì Ìdánimọ̀ Aṣáájú Ọ̀nà rẹ̀. Kí a kọ “Mrs.” kí gbogbo orúkọ ọkọ rẹ̀ sì tẹ̀ lé e. Tẹ̀ lé èyí, kí a kọ orúkọ arábìnrin náà fúnra rẹ̀ sínú àkámọ́, fún àpẹẹrẹ, Mrs. John A. Akinọlá (Sarah D.).

◼ Nígbà tí wúndíá aṣáájú ọ̀nà kan, bá lọ́kọ, akọ̀wé ìjọ ní láti fún Society ní gbogbo orúkọ ọkọ rẹ̀ àti ọjọ́ ìgbéyàwó wọn. Lẹ́yìn náà, a óò kọ orúkọ arábìnrin náà sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti fi hàn lókè yìí.

◼ Fún ìdí kan, bí ẹnì kan bá rí i pé ó pọn dandan láti fi iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà sílẹ̀, ó ní láti fi tó àwọn alàgbà ìjọ létí. Lẹ́yìn náà, wọn yóò fi tó Society létí, ní lílo fọ́ọ̀mù S-206. Kí wọ́n ṣàlàyé ṣókí nípa ìdí tí ẹni náà fi fi iṣẹ́ àṣáájú ọ̀nà sílẹ̀, kí ìgbìmọ̀ iṣẹ́ ìsìn àdúgbò sì fọwọ́ sí fọ́ọ̀mù náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́