ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/98 ojú ìwé 1
  • “Jèhófà Ni Olùrànlọ́wọ́ Mi”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Jèhófà Ni Olùrànlọ́wọ́ Mi”
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
km 10/98 ojú ìwé 1

“Jèhófà Ni Olùrànlọ́wọ́ Mi”

1 Nígbà tí Jésù ń yanṣẹ́ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àkọ́kọ́, ó sọ fún wọn pé: “Wò ó! Mo ń rán yín jáde gẹ́gẹ́ bí àgùntàn sáàárín àwọn ìkookò.” (Mát. 10:16) Ìyẹn ha mú kí wọ́n bẹ̀rù kí wọ́n sì fà sẹ́yìn bí? Ó tì o. Wọ́n lo ẹ̀mí ìrònú tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi hàn lẹ́yìn náà nígbà tí ó sọ fún àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Kí a lè jẹ́ onígboyà gidi gan-an, kí a sì sọ pé: ‘Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; èmi kì yóò fòyà. Kí ni ènìyàn lè fi mí ṣe?’” (Héb. 13:6) Wọ́n láyọ̀ pé a kà wọ́n yẹ fún títàbùkù sí nítorí orúkọ Jésù, wọ́n sì ń bá a lọ láìdábọ̀ ní kíkọ́ni àti pípolongo ìhìn rere náà.—Ìṣe 5:41, 42.

2 Lónìí, iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé ti dé ìpele rẹ̀ tí ó kẹ́yìn. Gan-an gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀, a ti di ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo orílẹ̀-èdè. (Mát. 24:9) A ti tako iṣẹ́ ìwàásù tí a ń ṣe, a sì ti pẹ̀gàn rẹ̀, kódà a ti fòfin dè é ní àwọn apá ibì kan lórí ilẹ̀ ayé. Bí a kò bá ní ìgbàgbọ́, ẹ̀rù lè bà wá. Ṣùgbọ́n, mímọ̀ pé Jèhófà ni Olùrànlọ́wọ́ wa ń tù wá lára, ó sì ń fún wa lókun láti máa forí tì í.

3 Ìgboyà jẹ́ ànímọ́ ti lílágbára, líláyà, jíjẹ́ akíkanjú. Ó jẹ́ òdì-kejì ìbẹ̀rù, ìtìjú àti ìwà ojo. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ti fi ìgbà gbogbo nílò ìgboyà láti fara dà. Ó pọndandan bí a óò bá yẹra fún dídi ẹni tí ẹ̀mí ìrònú àti ìwà ayé tí ó jẹ́ ọ̀tá sí Ọlọ́run mú láyà pami. Ẹ wo bí ó ṣe ń fún wa níṣìírí tó láti ronú nípa àpẹẹrẹ gíga jù lọ ti Jésù, ẹni tí ó ṣẹ́gun ayé! (Jòhánù 16:33) Rántí pẹ̀lú pé, nígbà tí àwọn àpọ́sítélì dojú kọ àdánwò lílekoko, wọ́n fi àìṣojo polongo pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 5:29.

4 Àwa Kì Í Ṣe Irú Àwọn Tí Ń Fà Sẹ́yìn: A gbọ́dọ̀ sakun láti ní ẹ̀mí ìrònú tí ó dára nípa iṣẹ́ wa. (Héb. 10:39) Kí a máa fi sọ́kàn nígbà gbogbo pé Jèhófà ni ó rán wa jáde láti fi ìfẹ́ àti àánú tí ó ní sí gbogbo aráyé hàn. Kò fìgbà kan rí sọ pé kí àwọn ìránṣẹ́ òun ṣe ohunkóhun tí kò ní ète tí ó wúlò. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, gbogbo ohun tí a yàn fún wa láti ṣe yóò yọrí sí ire àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run.—Róòmù 8:28.

5 Níní ojú ìwòye pé nǹkan yóò dára yóò ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá a nìṣó ní wíwá àwọn ẹni bí àgùntàn kiri ní ìpínlẹ̀ wa. A lè wo ẹ̀mí ìdágunlá tí àwọn ènìyàn ń fi hàn bí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà fi ipò ìjákulẹ̀ àti àìnírètí tí wọ́n wà hàn. Ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ tí a ní sún wa láti ní ẹ̀mí ìbánikẹ́dùn kí a sì ní sùúrù. Ní gbogbo ìgbà tí a bá fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ sóde, tàbí kẹ̀, bí a bá rí ọkàn-ìfẹ́ kíún, góńgó wa yẹ kí ó jẹ́ láti ṣe ìpadàbẹ̀wò lọ́gán kí a sì ru ọkàn-ìfẹ́ púpọ̀ sí i sókè. Kò yẹ kí a ṣiyèméjì nípa agbára tí a ní láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí láti darí rẹ̀ lọ́nà gbígbéṣẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ máa fi àdúrà wá ìrànwọ́ àti ìtọ́sọ́nà Jèhófà nígbà gbogbo, kí a ní ìgbọ́kànlé pé òun yóò ràn wá lọ́wọ́.

6 A gbàgbọ́ dáadáa pé Jèhófà yóò rí sí i pé iṣẹ́ náà dé ìparí rẹ̀. (Fi wé Fílípì 1:6.) Ìgbẹ́kẹ̀lé pátápátá tí a ní nínú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Olùrànlọ́wọ́ wa ń fún wa lókun kí a má bàa “juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀.”—Gál. 6:9.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́