Àwọn Ìfilọ̀
◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní February: Ẹ́fíìkì àti Haúsá—Yálà Alafia ati Ãbò Tõtọ—Lati Orisun Wo? tàbí Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. Gẹ̀ẹ́sì—Yálà Lilaaja Sinu Ilẹ-ayé Titun tàbí The Bible—God’s Word or Man’s? Ìgbò—Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ Julọ, Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, True Peace and Security—How Can You Find It?, tàbí Yiyan Ọna Igbesi Ayé Ti O Dara Julọ. Ísókó—Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. Yorùbá—Ayọ̀—Bi A Ṣe Lè Rí I, Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ Julọ, Igbesi Aye Yii Ha Ni Gbogbo Ohun Ti O Wà Bi?, tàbí Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. (A óò fi gbogbo ìwé olójú ewé 192 tí ó wà lókè yí lọni ní ẹ̀dínwó ₦50 [iye tí aṣáájú ọ̀nà yóò gbà á, ₦40]; ìwé Walaaye Titilae ní Ẹ́fíìkì, Haúsá, Ìgbò, Ísókó, àti Yorùbá jẹ́ ₦80 [iye tí aṣáájú ọ̀nà yóò gbà á, ₦50]. A ti fi lẹ́tà tí ó sọ̀rọ̀ nípa èyí ránṣẹ́ sí gbogbo ẹgbẹ́ àwọn alàgbà ní May.) March: Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. April àti May: Àsansílẹ̀ owó fún Ilé Ìṣọ́. Fún iṣẹ́ ìsìn àárín ọ̀sẹ̀ ní àwọn ìpínlẹ̀ ti a sábà máa ń kárí, a lè lo ìwé pẹlẹbẹ tuntun náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? ÀKÍYÈSÍ: Àwọn ìjọ tí yóò nílò àwọn ìwé ìgbétásì tí a mẹ́nu kàn lókè yí ní láti béèrè fún wọn lórí Literature Order Form (S-14) olóṣooṣù wọn ti oṣù tí ń bọ̀.
◼ Kí akọ̀wé àti alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ṣàyẹ̀wò ìgbòkègbodò gbogbo aṣáájú ọ̀nà déédéé. Bí èyíkéyìí lára wọn bá ní ìṣòro dídójú ìlà wákàtí tí a béèrè fún, àwọn alàgbà ní láti ṣètò, kí a lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún un. Fún ìdámọ̀ràn, ṣàtúnyẹ̀wò àwọn lẹ́tà Society (S-201) ti October 1, 1993, àti October 1, 1992. Tún wo ìpínrọ̀ 12 sí 20 nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti September 1986.
◼ Kí àwọn akéde tí wọ́n fẹ́ láti ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní March, April, àti May ṣe àwọn ìwéwèé wọn nísinsìnyí, kí wọ́n sì tètè fi ìwé ìwọṣẹ́ wọn sílẹ̀. Èyí yóò ran àwọn alàgbà lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ètò tí ó yẹ fún iṣẹ́ ìsìn pápá, kí wọ́n sì ní ìwé ìròyìn àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ mìíràn tí ó pọ̀ tó lọ́wọ́. Kí a kéde orúkọ gbogbo àwọn tí a fọwọ́ sí láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ fún ìjọ.
◼ Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn àpéjọ àyíká àti ọjọ́ àpéjọ àkànṣe ti February 1997, a kì yóò pèsè oúnjẹ sísè mọ́. Ṣùgbọ́n, ọtí ẹlẹ́rìndòdò àti àwọn ohun mìíràn yóò wà. Nítorí náà, olúkúlùkù ni yóò máa gbé oúnjẹ rẹ̀ wá. A óò pèsè ẹ̀kún rẹ́rẹ́ àlàyé nígbà tí ó bá yá.